Ọ̀rọ̀ ogun àgbọ́tẹ́lẹ̀ ni o, wọ́n ní kìí pa arọ (tó bá gbọ́n).
A ti sọ fún yín, sọ, sọ, sọ, a tún nsọ-ọ́ lẹ́ẹ̀kan si – gbogbo ìpínlẹ̀ Èkó, Ìbàdàn, Ògùn, Ọ̀ṣun, Ondó, Èkìti àti Ìṣèjọba-Ọ̀yọ́, kìí ṣe ara Nàìjíríà mọ́.
A ti kúrò nínú Nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, bẹ́ẹ̀ ni a ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba tiwa, ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ní ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, nítorí náà, ìwọ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), máṣe ka ara rẹ mọ́ Nàìjíríà mọ́, má sì lọ darapọ̀ pẹ̀lú ọmọ Ológun Nàìjíríà!
A tún nsọ ọ̀rọ̀ yí, torí a tún ti rí ìkéde kan ti Àwọn Ológun Nàìjíríà gbé síta pé kí àwọn ènìyàn wọn ó wá darapọ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn. Ìwọ ọmọ Yorùbá, ó ò kì nṣe ọmọ Nàìjíríà, máṣe lọ darapọ̀ pẹ̀lú ológun Nàìjíríà!
Wọ́n ti lẹ̀ sọ nínú ìkéde wọn pé o níláti jẹ́ ọmọ Nàìjíríà kí wọ́n tó le rí tìẹ rò. Nítorí èyí, ó túmọ̀ sí pé tí ó bá ti sọ fún wọn pé ọmọ Nàìjíríà ni ẹ́, o ti pàdánù jíjẹ́-ọmọ-Yorùbá nìyẹn, torí Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́! Nígbàtí o bá sì ti sọ pé ọmọ Nàìjíríà ni ẹ́, àwọn ọmọ àti àrọ́mọ-d’ọmọ ẹ kò lè wá lẹ́yìn ọ̀la kí wọ́n wá sọ pé ọmọ Yorùbá ni àwọn o! Rárá!
Èkejì, ìkédé àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ọ̀ún sọ pé àwọn tí wọ́n bá yege ìforúkọ-sílẹ̀ wọn ọ̀ún, ni kí wọ́n lọ sí ìpínlẹ̀ wọn nígbàtí àkókò bá tó, fún àṣekágbá ètò dídi ọmọ-Ológun wọn ní Nàìjíríà ọ̀hún.
Ìpínlẹ̀ wo ni ìwọ máa lọ sí o? O ò gbọ́dọ̀ wá sí ìpínlẹ̀ kankan ní orílẹ̀-èdè Yorùbá, (D.R.Y), kí o wá sọ pé ibẹ̀ ni ìpínlẹ̀ rẹ ní Nàìjíríà, kò ṣe-é ṣe! Yàtọ̀ sí pé kò ṣe-é ṣe, ó túmọ̀ sí pé o nka ilẹ̀ D.R.Y mọ́ Nàìjíríà nìyẹn; èyí tí ó sì já sí pé ìwọ náà jẹ̀bi ẹ̀sùn ìkọlù orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni Democratic Republic of the Yoruba, o di Ọ̀DARÀN nìyẹn!
Nítorí náà, wọ́n ní ko-ko-ko ni a nrọ́fá adití! Máṣe jẹ́ kí etí ẹ kó di o! Má ṣe darapọ̀ mọ́ ọmọ-Ológun nàìjíríà!