Ìbá ṣe wípé agbésùnmọ̀mí nàìjíríà kò fi ipá dúró lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), a bá má ti rí ìdojúkọ ìpànìyàn àti ìjínigbé tí àwọn Fulani ń ṣe ní ilẹ̀ Yorùbá.
Ọ̀rọ̀ yí wá nítorí ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́, nípa ìlú Igbó-Ọrà, tí a rí fọ́nrá àwọn obìnrín méjì kan, tí wọn ń fi ìtara sọ̀rọ̀, nípa bí Fulani ṣe jí àwọn ènìyàn wọn bí mẹ́rin gbé, tí wọn sì pa méjì nínu wọn, lẹ́yìn tí wọ́n ti nlọ jẹ́ ìpè ìwọ̀sí láti san owó tí wọ́n béèrè, ṣùgbọ́n tí ìdojúkọ’ra ṣẹlẹ̀ láarín àwọn àmọ̀tẹ́kùn àti ajínigbé, tí ajínigbé tìtorí èyí pa méjì nínú àwọn tí wọ́n jígbé.
Ìjọba-ajẹgàba nàìjíríà, kúrò lórí ilẹ̀ wa. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kìí ṣe ilẹ̀ rẹ. D.R.Y jẹ́ orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ kéde òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún.
Ìjọba wa ti wà lórí aléfà, lábẹ́ àkóso Olórí Ìjọba Adelé, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, aríremáse nàìjíríà, jáde. Ìjẹgàba rẹ ni ó ṣe okùnfà ìdààmú ìjínigbé tí ó ń dojúkọ ọmọ Yorùbá. Ṣèyí Mákindé, Sanwó-Olú, Adéléké, Dàpọ̀ Abíọ́dún, Abdulrahman Abdulrazaq, Ododo, Oyèbánjí, Ayédatiwa: a tún ń sọ fún yín lẹ́ẹ̀kan si: ẹ yé hùwà ọ̀daràn; ẹ kúrò nínú àwọn oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo ní ilẹ̀ Yorùbá