Ọbẹ̀ dùn tán, adímú fẹ́ bù lá, àwọn ọlọ̀tẹ̀ òní’pàdé àbòsí tí wọ́n pe ara wọn ní ọmọ Yorùbá, tó ńkó ara wọn jọ nínú ìpàdé òfo ní ìrètí láti fi ẹ̀tàn àti ipá gba ohun tí wọn kò ní ẹ̀tọ́ si, tí wọ́n ò sì ṣiṣẹ́ fún. Wọ́n ò ṣá igi l’ọ́gbẹ́, bẹ́ẹ̀ni wọn kò ta ògùrọ̀ l’ọ́fà, wọ́n wá gbẹ́nu sókè sí ìdí ọ̀pẹ, ṣe ọ̀fẹ́ ló ń ro ni?

Kí a tó gba òmìnira wa, gbogbo ìgbésẹ àti àṣeyọrí wa ni àwọn aṣèbàjẹ́ yí ńṣe àtakò fún, tí wọ́n nsọ ìsọkúsọ pé agbésùnmọ̀mí nàíjíria ní àwọn faramọ́ pẹ̀lú ìyà, ebi àti pípa tí wọ́n ńpa ọmọ Yorùbá láti gba ilẹ̀ wa. Ó tẹ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yí lọ́rùn kí ìran ọmọ Aládé parun nítorí àtẹnujẹ ti wọn.

Ìyá wa MOA, òrìṣà òmìnira Yorùbá tí Olódùmarè lò fún àwa ọmọ Aládé wá rán àwọn onímọtaraẹni nìkan yìí létí bí wọ́n ṣe ń tan àwọn ọmọ Yorùbá nípa ìjàǹgbara tí àwọn ọ̀daran yí kò ṣe ètò fún, bíkòṣe ọgbọ́n láti fí gba owó àti ipò lọ́wọ́ olóṣèlú àti láti fí ja àwọn ọmọ Aládé ní ólè. Bẹ́ẹ̀ni àwọn kannáà ló ńpè fún ètò ìjọba agbègbè lábẹ́ àkójọpọ̀ òyìnbó amúnisìn nàìjíríà.

Màmá wa tún rán wọn létí bí wọ́n ti ṣe àtakò ìkéde òmìnira wa pẹ̀lú ìgbàpadà ohun ìní wa, tí wọ́n kó àwọn sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀ èké jáde láti sọ̀rọ̀ òdì sí màmá wa pẹ̀lú ìbanilórúkọ jẹ́, ẹ̀rí sì wà nilẹ̀ fún gbogbo ẹ̀sùn náà, bí màmá wa ṣe sọ.

Gbogbo àwọn aṣèpàdé ọ̀tẹ̀ yí kò ní ẹ̀tọ́ kankan ní orílẹ̀-èdè D.R.Y nítorí wọn ò fẹ́ rere fún wa, àfi iṣẹ́ ibi àti olè jíjà. Gbogbo wọn ni MOA sọ pé yóò ro ẹjọ́ fún ìwà ọ̀dájú àti ìṣelòdì sí òmìnira Yorùbá. Àwọn ọ̀dọ́ ààrin wọn ti ba ọjọ́ ọ̀la wọn jẹ́ pẹ̀lú ìdílé wọn. 

Ẹ̀kọ́ ńlá ni èyí jẹ́ fún ìran ọmọ Aládé pé ní àkókò kúkúrú tó kù fún wa láti wọ’nú ògo wa, ká ṣọ́ra gidigidi, kí a má ṣe kọsẹ̀.

Kí gbogbo wa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Alákòóso wa, ká má ṣàìgbọràn sí ìtọ́ni àti àṣẹ olórí Alákòóso wa, bàbá wa Ọlọ́lá jùlọ, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ àti màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla (Olóyè Ìyá – Ààfin).

Láìpẹ́, láì jìnà àwọn ọ̀tá ìran Yorùbá máa gé ìka àbámọ̀ jẹ nígbàtí àwọn Alákòóso wa bá wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa tí ayọ̀ wa yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal