Ilẹ̀ Yorùbá jẹ̀ orílẹ̀ èdè olómìnira aṣèjọba ara ẹni láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wa. Nígbàtí àwọn òyìnbó amúnisìn wọlé dé, wọ́n bá wa pé ọba àti àwọn ìjòyè ló ńṣe kòkárí ìṣàkóso ìṣèjọba nígbà náà.
Àrékérekè ati ẹ̀tàn ni àwọn aláwọ̀ funfun yìí lò láti sọ ara wọn di amùnisìn lóri ìran Yoruba. Àwọn òyìnbó yí wá gẹ́gẹ́bí oníṣòwò, òwò yí ni wọ́n ńṣe tí wọ́n fi wọlé sí àwọn ọba ìgbà náà lára.
Àwọn ajíhìnrere ni òyìnbó kọ́kọ́ rán ṣíwájú láti wàásù ìhìnrere, ni àkókò náà, àwọn òyìnbó gba pé àwọn ọba ní olórí àti aṣèjọba nílẹ̀ Yorùbá, wọ́n sí máa ńlọ rí àwọn ọba yí fún ilẹ̀ àti ohun míràn tí wọ́n nílò fún ẹ̀sìn wọn.
Lẹhin èyí ni àwọn òyìnbó oníṣòwò náà dé láti máaa ṣòwò ní orílẹ̀ èdè Yorùbá. Oníkálukú nfi ọ̀wọ̀ bá ara wọn lò, bẹ́ẹ̀ni àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá fí ìfẹ́ owó àti ojúkòkúrò wọnú iṣẹ́ òwò ẹrú pẹ̀lú wọn. Kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ imú ẹlẹ́dẹ̀ ńwọ ọgbà. Àwọn òyìnbó yí rí àṣírí àti àṣìṣe àwọn ọba yí nípasẹ̀ àìkíyèsára àti àtẹnujẹ, ni omi bá t’ẹ̀yìn wọ ìgbín wọn lẹ́nu.
Ní àìròtẹ́lẹ̀, ni àwọn òyìnbó ńtú apẹ̀rẹ̀ ìmúnisìn tí wọ́n gbé pamọ́ látí máa ṣe òfin ìjẹgàba nípa lílo àwọn akótilétà ọmọ Yorùbá bíi aṣojú àti ọmọ ogun láti gbàkóso ìṣèjọba ilẹ̀ wa pẹ̀lú ipá.
Bí agbára ìṣèjobà ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba, tí amúnisìn sì bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣàkóso orílẹ̀ èdè Yorùbá, ọba àti ìran Yorùbá sì di ẹrú lábẹ́ àwọn àjèjì òyìnbó tó wá sí orí ilẹ̀ wa láti fi àrékérekè àti ipá gba agbára ìṣèjọba orílẹ̀ èdè wa.