Lẹ́yìn tí àwọn òyìnbó amúnisìn ti gbàkóso ìṣèjọba ilẹ̀ Yorùbá tán, tí wọ́n sọ ọmọ Yorùbá sí oko ẹrú, àwọn ọba yí ṣì wà ní ipò ọba láìsí agbára tàbí àṣẹ láti ṣe ìjọba mọ́, ṣùgbọ́n àwọn amúnisìn fí wọ́n síbẹ̀ gégébí olórí ẹrú tí wọ́n ńlò láti ṣe àkóso ètò ìmúnisìn àti ìmúnilẹ́rú.

Iṣẹ́ àwọn ọba yí ni láti máa fi agídí gba owó orí lọ́wọ́ ará ìlú fun amúnisìn òyìnbó, wọ́n sì tún ńfi òfin àwọn òyìnbó yí mu ará ìlú láti ṣe ẹrú tipátipá lóri ilẹ̀ babanlá wọn fún aláwọ̀ funfun nítorí kí òyìnbó má dá owó oṣù wọn dúró tàbi kí ó yọ wọ́n lọ́ba gẹ́gẹ́ bí olórí ẹrú. Lábẹ́ àwọn amúnisìn, ìfẹ́ ìlú àti ará ìlú ṣí kúrò lọ́kàn àwọn ọba Yorùbá, ìfẹ́ owó, ipò àti ìbẹ̀rù òyìnbó sì dípò rẹ̀.

Òyìnbó amúnisìn tún ńlo gbogbo àwọn ọba wònyí láti pa àwọn ará ìlú lẹ́nu mọ́, bí àwọn olè òyìnbó náà ṣe nkó ọrọ̀ orílẹ̀ èdè Yorùbá lọ láti tún ìlú àti ayé àwọn ọmọ ìlú wọn ṣe. Àwọn ọba yí wá di ọ̀tá ìran Yorùbá pátápátá.

Bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n ti di ẹrú lábẹ́ amúnisìn òyìnbó, síbẹ̀, wọ́n nfi ipò olórí ẹrú náà jẹgàba lóri àwọn ènìyàn wọn láti ta ìran ọmọ Aládé àti ilẹ̀ àjogún bá wa fún at’ọ̀húnrìnwá, ìkà àti olè òyìnbó amúnisìn. Ìrìn àjò yí tẹ̀síwájú títí di ẹgbàá ọdún ó dín mẹ́rìn dín láàdọ́rùn-ún tí wọ́n so orìlẹ̀ èdè Yorùbá pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tó f’ara tì wá, tí wọ́n sì pèé ní nàìjíríà.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Iṣẹ́ ibi àwọn ọba ẹrú yí kò dáwọ́ dúró títí di òjì dín lẹ́gbàá ọdún nígbàtí àwọn amùnisìn fún arógobògojẹ́ naijiria ní òmìnira òfegè. Ó jẹ̀ òmìnira òfegè nítorí àwọn òyìnbó amúnisìn náà ló ṣì ńdarí gbogbo ìṣèjọba ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá.

Lẹ́yìn òmìnira irọ́ yìí, àwọn Fúlàní ni àwọn òyìnbó amúnisìn sọ di olórí ẹrú tí wọ́n sì ńdarí àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá láti máa ṣe ìfẹ́ àwọn Fúlàní àti aláwọ̀ funfun, ní ìlòdì sí ìran ọmọ Aládé. Ó màṣe ò,  ọba Yorùbá di ẹrú Fulani tí ńṣiṣẹ́ fún amúnisìn. 

A ó ri pé láti ìgbà tí àwọn òyìnbó amúnisìn ti fi àrékérekè àti ipá já ìṣèjọba ilẹ̀ Yorùbá gbà ní ọba ti sọ àṣẹ àti agbára nù, tí àwọn fúnra wọn sí ti di ẹrú tí ńṣe olórí ẹrú.