Ajá Tó Máa Sọnù Kì Í Gbọ́ Fèrè Ọlọ́dẹ

Ṣé àwọn òyìnbó amúnisìn ni ó kúkú so irun iwájú pọ̀ mọ́ ti ìpàkọ́ ní ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú, èyí tí ó fa wípé, ní ibi tí wọ́n wá sọ ní orúkọ “nigeria” ní ọdún 1914, nṣe ni wọ́n so Yorùbá pọ̀ mọ́ Íbò àti Hausa, ẹ̀yà ọ̀tọ̀tọ̀ tí kò jọra rárá.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ìròhìn kan tí ó jẹyọ lórí ayélujára ni ó sọ wípé àwọn ọmọ Íbò kò ní ìjòyè tẹ́lẹ̀, àfi ìgbà tí òyìnbó amúnisìn yan ìjòyè dandan-dan ní ilẹ̀ Íbò, látàrí wípé kí wọ́n le rí wọn lò gẹ́gẹ́bí ‘olórí ẹrú’ tí yíò ran àwọn Gẹ̀ẹ́sì lọ́wọ́ láti máa darí àwọn ẹrú tó kù.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024

Ọmọ Yorùba kan wá ṣe àkíyèsí ọ̀rọ̀ yí, ó ní ìtúmọ̀ rẹ̀ ni wípé Íbò kò ní olórí tàbí ìṣèjọba gẹ́gẹ́bí Yorùbá, à fi ìgbà tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí yan ìjòyè fún wọn. 

Àwọn Ìgbò náà máa nsọ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì kórira ọba-níní, ṣùgbọ́n wọ́n máa nsọ wípé àwọn ‘alàgbà’ ní ìletò kọ̀ọ̀kan ni àwọn máa nní kí òyìnbó kí ó tó dé.

Ṣùgbọ́n a ò wá mọ̀ bóyá lára àwọn ‘alàgbà’ wọ̀nyí ni àwọn òyìnbó tí wọn ò kìí gbé ilé tiwọn yí, ti yan ìjòyè fún wọn. Ṣebí wọ́n ní eégún ní ó ngb’owó òde ní ibi kan, ṣùgbọ́n akọ́dà ni ní ibi míràn!

Àmọ́, ohun kan tí ó wá ba’ni nínú jẹ́ ni ọkùnrin ọmọ Íbò kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó ti di olóògbé láti ìgbà láilaí, èyí tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ernest Okolie, èyí tí ó sọ nínú fọ́nrán náà nípa ohun tí ó pè ní “orílẹ̀-èdè” nígbàtí ó n nsọ̀rọ̀ ‘nigeria.’ Ọmọ Yorùbá tí ó ṣe àkíyèsí yi wá sọ báyi: ó ní, ṣé orílẹ̀-èdè ni Nàìjíríà ni? Gbogbo wa ni a ti wá mọ̀ báyi o, Nigeria kìí ṣe orílẹ̀-èdè, torí kò sí èdè abínibí, èdè ‘ìran ẹni’ tí ó so àwọn ará ìlú Nàìjíríà pọ̀.

Ṣùgbọ́n, gbogbo eléyi, ọ̀rọ̀ ìròhìn ni o, ṣé àwa Yorùbá kò kúkú nṣe ara Nàìjíríà mọ́!