Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XAjá Tó Máa Sọnù Kì Í Gbọ́ Fèrè Ọlọ́dẹ
Ìyá Ilẹ̀ Yorùbá ti máa nsọọ́ o, kò sí nínáwó ṣòfò ní ìṣèjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá. Eléyí yàtọ̀ pátápátá gbáà sí ìwà ìlú agbésùnmọ̀mí tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wá, èyí tí ìròhìn fi tó wa létí pé, láarín ọdún kan, ní oṣù kẹ́fà ọdún 2023 sí oṣù kárun ọdún 2024, ó lé ní bílíọ̀nùù mẹ́rin-dínlógún owó náírà tí wọ́n ná láti fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún owó òkèèrè (foreign exchange) látàrí ìnáwó owó ìrìn-àjò lọ sí òkèèrè fún ààrẹ wọn l’ọhún, igbá-kéjì rẹ̀, ìyàwó ààrẹ, olùṣiṣ-àgbà fún ààrẹ (chief of staff) àti àwọn ọkọ̀ bàlúù ààrẹ.
Ìyàwó ààrẹ wọn, pàápàá, tí kìí ṣe ẹni tí wọ́n dìbò yàn, tàbí òṣìṣẹ́ ìjọba nnáwó lábẹ́ oríkò ìnáwó yí. Eléyi sì jẹ́ owó pàṣípààrọ̀ nìkan ni o, kìí ṣe ojú-owó àwọn ìrìnnà gan-gan.
Eléyi kò tilẹ̀ kàn wá, Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá; ṣebí ìlú tiwọn l’ọhún nì yẹn; ṣùgbọ́n a fi rán ara wa létí kí a má ṣe gbàgbé ìdákòrò wa lórí ìnáwó owó ará-ìlú D.R.Y, wípé, KÒ GBỌDỌ̀ SÍ ÒFÒ, KÒ SÍ ÌNÁKÚNA, KÒ SÍ ÀDÁNÙ.