Ìròyìn kan tí a rí lórí ayélujára instagram, tí ó wá tọ́ka sí ibi tí ọ̀rọ̀ náà ti jẹyọ lórí X, ìkànnì @winexviv , ni a ti ríi o, pé àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ girama ní ìlú aríremáṣe nàìjírà, èyí tí ìjọba agbésùnmọ̀mí wọn nfi àìnítìjú fi ipá dúró lórí ilẹ̀ wa ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), àwọn ọmọ wọ̀nyí, tí wọ́n wà ní ipele kìíní tí nàìjíríà npè ní JS1 ní ìlú wọn l’ọhún, ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣẹ́ oyún, tí wọ́n sì nṣe ìdánwò le lórí.
Bí wọ́n ṣe nbéèrè ìbéèrè lórí ìfètò-sọ́mọ-bíbí àti oyún-ṣíṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n nṣè’dánwò lórí kíni ànfààní ìgbàni-nímọ̀ràn nípa oyún ní ikùn ọmọ tí kòì tíì pé ogún ọdún.
Lóotọ́ àti lódodo, irú ẹ̀kọ́ báyi gbé ojú síta gẹ́gẹ́bí ẹ̀kọ́ sáyẹ́nsì, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wo bí wọ́n ṣe béèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn dáadáa, á mọ̀ pé ẹ̀kọ́ tó fara pamọ́ sábẹ́ sáyẹ́nsì ni, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ èyí tí ó fẹ́ kí àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí ẹlómíì nínú wọn kò tìí pé ọdún mẹ́wa pàápàá, kí wọ́n máṣe mọ ẹ̀kọ́-ilé nípa ìbálopọ̀, ìṣẹ́yún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀nà tí wọ́n fi gbé ẹ̀kọ́ àti àwọn ìbéèrè náà kalẹ̀, jẹ́ èyí tí ó kàn jẹ́ “sáyẹ́nsì” ṣùgbọ́n tí ó fi ọmọ kékeré sílẹ̀ láti máa rò pé òun lè ní ìbálòpọ̀ nígbàkúgbà tí ara òun bá dìde, àti pé tí oyún bá dé, òun lè ṣẹ, tí òun kò bá fẹ́ bí ọmọ náà! Kìkìdá kí òun kàn ṣáà ti gba àmọ̀ràn kí ìṣẹ́yún náà máṣe mú ewu dání ni!
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ni ohun tí àwọn akẹ́kọ fásitì tí wọ́n nkọ́ṣẹ́ ìṣègùn lè mọ̀ ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé wọ́n ti ní ẹ̀kọ́ ilé tẹ́lẹ̀ láti mọ̀ pé bí sáyẹ́nsì bá gbekalẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé bẹ́ẹ̀ ni ọmọlúàbí ṣe máa ṣe tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwọn ọmọ tí wọ́n ṣì wà ní ipele kékeré tí ọjọ́ orí wọn tì dàbí ọdún mẹ́wa kìí ṣe ẹni tí a nkọ́ ni irú sáyẹ́nsì tí kò mú ọpọlọ ọmọlúàbí dání.
A mọ̀, dájú, pé àwọn alágbayé tí wọ́n fẹ́ dín iye ènìyàn tí ó wà ní ayé yí kù, ni wọ́n wà nídi kí wọ́n máa ṣe irú nkan báwọ̀nyí. Wọ́n fẹ́ kí àwọn ọmọdé ó ti ni nínú ọpọlọ wọn pé oyún-ṣíṣẹ́ nígbàkúgbà kìí ṣe ohun-bàbàra – ọ̀nà pé kí ọmọ-bíbí lè dínkù ni wọ́n fi nkọ́ àwọn ọmọdé ní eléyi; èyí á wá túbọ̀ ran ète àwọn alágbayé wọ̀nyẹn lọ́wọ́ láti ri pé ènìyàn dínkù ní ayé.
Yàtọ̀ sí èyí, àwọn amúnisìn tí wọ́n nsọ fún aríremáṣe nàìjíríà láti má fi làákàyè, ọmọlúàbí àti ìwà ológo sí nkan báwọ̀nyí, nṣe bẹ́ẹ̀ torí kí wọ́n le mú aláwọ̀dúdú kúrò nínú ìgbé-ayé rere èyí tí ó jẹ́ igi-lẹ́yìn-ọgbà adúláwọ̀ – ṣé a rántí bí òyìnbó amúnisìn kan, ni igba-ọdún ó-dín-mọ́kànlá sẹ́yìn, tí ó sọ pé tí òyìnbó bá fẹ́ borí aláwọ̀dúdú, wọ́n ní láti mú aláwọ̀dúdú balẹ̀ kúrò ní jíjẹ́ ẹni-ẹ̀mí tí a jẹ́ ẹni-ẹ̀mí, àti kúrò ní àṣà àti ẹ̀kọ́-àdáyébá wa!
Ṣé a rántí pé ó sọ, ó ní òun ti káàkiri Áfríkà, òun ò sì tíì rí ẹni bẹ́ẹ̀ ní àgbáyé tó ní ìwà rere bí ti aláwọ̀dúdú. Ọ̀nà kí wọ́n lè túbọ̀ gba ìwà rere lọ́wọ́ àwọn aríremáṣe nàìjíríà, ni wọ́n fi nkọ́ ẹ̀kọ́ tí ọmọ kékeré á fi rò pé ṣèbí sáyẹ́nsì ni, kò sí bàbàrà nínú pé òun lóyún lọ́mọdé tàbí pé òun ṣẹ́ oyún náà; yàtọ̀ sí pé àwọn amúnisìn wọ̀nyí tilẹ̀ fẹ́ dín iye ènìyàn kù.
Kò sí èyí tí ó kàn wá níbẹ̀ bí kìí ṣe ti jíjẹgàba tí wọ́n jẹgàba sórí ilẹ̀ wa, èyí tí ó túmọ̀ sí pé irúfẹ́ nkan wọ̀nyí náà ni atẹ́gùn rẹ̀ máa máa fẹ́ sí ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P).
Irú iṣẹ́ tí àwọn amúnisìn nṣe ní ìlú nàìjíríà nìyẹn o! Tí àwọn tí ó pera wọn ní àgbààgbà òfò, àti tí wọ́n pera wọn ní ọba, nṣe gọ̀ṣú-gọ̀ṣú tẹ̀lé, torí owó tí kò tó nkan!
Ara nkan tí Màmá wa nsọ nìyí; Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá; pé a ò gbọ́dọ̀ gbà kí àwọn amúnisìn ó dín wa kù ní iye: tórí ohun tí wọ́n nfẹ́ gan-an nìyẹn! Màmá tilẹ̀ ní a ṣì máa bí’mọ si, kìí ṣe pé a máa ṣẹ́’yún.
A dúpẹ́ pé Olódùmarè ti yọ wá pátápátá kúrò nínú oko ẹrú nàìjíríà àti ti àwọn amúnisìn wọ̀nyí, nipasẹ̀ Màmá wa, MOA – gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa nsọ pé “ní dédé ìgbà yí, ní dédé àsìkò yí” ní kí àwa ọmọ Yorùbá ó padà sí orísun wa.
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn amúnisìn wọ̀nyí tí mú àwọn aríremáṣe àti ìlú ajẹgàba nàìjíríà yí láti fi sí’nú òfin wọn pé ẹ̀yà-ara àwọn ọmọ Nàìjíríà ọ̀ún kìí ṣe tiwọn: ìgbàkúgbà ni dókítà ní ilé-ìwòsàn lè yọ ẹ̀ya-ara ẹnikẹ́ni láìsí àṣẹ ẹni náà, tí ẹni ọ̀ún kò tilẹ̀ ní mọ̀!
Àwọn tí wọ́n pera wọn ní ọba òfò, tí wọ́n fẹ́ kí ìran-ọmọ-Aládé máa tẹ̀lé oríburúkú Nàìjíríà ọ̀ún, sì jóko síbẹ̀, wọ́n káwọ́ gbera, láì sọ pé “kí ló njẹ́ bẹ́ẹ̀?” Ṣùgbọ́n àwa ti lọ ní tiwa o! A ò sí nínú Nàìjíríà mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní ọba ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Àwọn tí wọ́n pera wọn ní olówó nílẹ̀ Yorùbá náà, wọ́n lajú lamú wọn sílẹ̀, kí wọ́n máa yọ ẹ̀yà ara-ọmọ-ènìyàn, kí wọ́n sì máa kọ́ àwọn ọmọdé bí wọ́n ṣe nṣẹyún láì fi ẹ̀kọ́ ọmọlúàbí si, ṣùgbọ́n tí wọ́n kàn kọ́ wọn lónà tí á fi dà bí pé inkan tí wọ́n lè ṣe ni, pé kò sí bàbàrà kankan níbẹ̀, kí wọ́n ṣáà ti gba ìmọ̀ràn bí wọ́n á ṣe ṣé tí kò ní mú ìpalára dání!
Bẹ́ẹ̀ làwọn tó pera wọn ní àgbààgbà, àti àwọn òbí pàápàá ní ilẹ̀ Yorùbá lajú sílẹ̀ kí nkan wọ̀nyí máa wáyé: tó bá jẹ́ pé gbogbo àwọn àgbà òfò tó lájú lamú sílẹ̀ wọ̀nyí faramọ́ dídádúró orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y ni, àá sọ pé D.R.Y ni wọ́n gbárùkù ti, tí wọn ò fi sọ̀rọ̀ nípa kílónlọ ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà; ṣùgbọ́n àwọn tí ó jẹ́ pé Nàìjíríà ni wọ́n tò sí lẹ́yìn ni wọ́n: síbẹ̀, tí irú nkan burúkú báwọ̀nyí nṣẹlẹ̀ tí wọ́n dákẹ́!
Ṣùgbọ́n àwa D.R.Y ti lọ ní tiwa o, kò dá wa dúró, a kàn nsọ àwọn nkan wọ̀nyí láti gbé ojú òtítọ́ síta pé àgbà òfò, ọ̀bàyéjẹ́ tó pera rẹ̀ lọba, olówó àdánù, ẹlẹ́tẹ tó pera rẹ̀ ni “elite” ni gbogbo àwọn rádaràda wọ̀nyí: àwa ti lọ ní tiwa.
Àwọn òbí rádaràda tí wọn kì nwo nkan tí wọ́n nkọ́ àwọn ọmọ wọn ní ilé-ìwé, àwọn náà wà lára àwọn olófo wọ̀nyí. Tí àwọn àgbà-ìyà gbogbo wọ̀nyí bá fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú D.R.Y, lábẹ́ ìtọnà Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá nípasẹ̀ Màmá wa, MOA, kí wọ́n sì gbárùkù ti ijọba-Adelé wa ni, à bá ti ṣíra lé Nàìjíríà tó njẹgàba lé wa lórí yí kúrò ní Ilẹ̀ wa, gbogbo nkan rádaràda tí nàìjíríà nṣe ìbá má ti ta bá wa rárá: nítorí pé, jíjẹgàba wọn yí ni gbogbo nkan burúkú tó nṣẹlẹ̀ ní nàìjíríà wọn ọ̀ún ṣe ntabá ọmọ Yorùbá.
Kò yí ìjọba D.R.Y padà o! Ìjọba orílẹ̀-èdè Yorùbá wa yí dúró gbọin-gbọin, ṣùgbọ́n jíjegàba nàìjíríà njẹ́ kí ìbàjẹ́ wọn ní nàìjíríà ó fi ara yí ọmọ-Yorùbá tó wà lórí ilẹ̀ D.R.Y níbi tí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà jẹgàba si: bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn.
Lójú-ayé ẹ̀yin tí ẹ pera yín ní àgbààgbà àti “elite” wọ̀nyí, Nàìjíríà nfi ipá dúró lórí ilẹ̀ Orílẹ̀-èdè Yorùbá, wọ́n nkọ́ àwọn ọmọ wa ní ìkọ́kúkọ, wọ́n nyọ ẹ̀yà-ara àwọn ènìyàn, ẹ sì jóko síbẹ̀ bí olúndù! Ẹ pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọba Nàíjíríà láti máa ba ilẹ̀ Yorùbá jẹ́!
Èyí tí ẹ̀ bá gbárùkù ti Ijọba-Adelé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, kí wọ́n lè ṣe kía wọ inú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba gbogbo káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, kí ìṣèjọba ìgbáyé-gbádùn ti D.R.Y ó lè ní ipa tààrà ní ilẹ̀ Yorùbá láìsí ìjẹgàba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà. Ẹ̀yin àgbà òfò wọ̀nyí, ẹ ẹ̀ ṣe-é dáadáa o! Ẹ ẹ̀ gbádùn rárá! Ṣé lórí owó tí wọ́n nfún yín yí náà? Èló lowó ọ̀ún o?
Ẹ̀yin ọmọ-ilé-ìwe JS1 ti Nàìjíríà tí wọ́n nkọ́ nípá oyún-ṣíṣẹ́, ṣé ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ṣẹ́ oníṣègùn ni, tí wọ́n ti nfi àwòrán bí wọ́n ṣe nṣẹ́ oyún kọ́ yín? Wọn ò fẹ́ kí ẹ bí’mọ ni o! Wọ́n fẹ́ kí ẹ tètè bẹ̀rẹ̀ sí lóyún, kí ẹ dẹ̀ máa ṣẹ́ oyún náà léra léra, ẹ̀ẹ́ sì rò pé ohun tí wọ́n nkọ́ yín ní’lé ìwé ni ẹ nṣe àmúlò rẹ̀, láì mọ̀ pé wọ́n fi ọgbọ́n mú yín kí ẹ máṣe bímọ, títí tí ẹ ò ní fi ní arọ́mọ-dọ́mọ ti yín nílé ayé!
Ohun tí wọ́n nfi kọ́ yín nìyẹn o! Bí ẹ ṣe máa fi ọwọ́ ara yín sọ ara yín di aláìl’ọmọ nílé ayé. Wọ́n fẹ́ pa ìran yín run ni o, ẹ máṣe báwọn lọ́wọ́ sí.
Àbọ̀ ọ̀rọ̀ là ń sọ fún ọmọlúàbí tó bá dé nú ẹ̀, á di odindi.