TAJUDEEN ABBAS ni orúkọ ọkùnrin náà o; òun ni Abẹnugan Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin àgbà-kéjì, ní ìlú tó fẹ̀gbẹ́ tì wá, Nàìjíríà.
A rí ìròhìn tí ó sọ pé Tajudeen Abass yí ti gbé Àbá kan sílẹ̀ o, síwájú àwọn Ìgbìmọ̀ aṣòfin ọ̀ún ní Nàìjíríà.
Àbá náà sọ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀, tàbí tí ó gbé ìgbésẹ̀, èyí tí ó mú kí ẹnikẹ́ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pè fún kíkúrò ní ìlú wọn Nàìjíríà, tàbí tí ó fa ìjà láarín apá kan Nàìjíríà àti apá míràn, òun ni kí wọ́n jù sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹdọ́gbọ̀n, tàbí kí ó san’wó ìtán’ràn mílíọ̀nù mẹ́wa owó wọn, naira, tàbí méjèèjì.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigería àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. pín sórí àgbàgbé ti X (Twitter)Àjẹ́ ké l’aná, ọmọ kú l’oní, tani kò ṣàì mọ̀ pé àjẹ́ àná ló p’ọmọ jẹ. Òwe ni o, ṣùgbọ́n ó ní bí a ṣe ntúmọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí a bá ngbé yẹ̀wò ṣe rí.
Ṣé ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ láìpẹ́ yí ló nyà wọ́n ní wèrè ni, tàbí wọ́n ti ni lọ́kàn tẹ́lẹ̀, tí wọ́n wá yáa gbe jáde ní àkókò yí?
Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ìlú wọn, Nàìjíríà, ni wọ́n ndá àbá yẹn fún!
Ìpọ̀nrípọngbá wọn, tani wọ́n rò pé àwọn máa ṣẹ̀rùbà? Ṣé wọ́n rò pé a fẹ́ kúrò nínú Nàìjíríà ni? A ò fẹ́ kúròo; a ti KÚRÒ níì! Ṣebí aṣòfin ni wọ́n pera wọn? Ogúnjọ́, oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, ni a ti kúrò nínú Nàìjíríà yín-ì; ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Àjọ Àgbáyé ti pè wá, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè, láti wá kópa nínú ìpàdé ọdọọdún àjọ náà, èyí tí ó wáyé ní oṣù ọ̀wẹ́wẹ̀, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́talélógún, tí a sì lọ; ṣé ẹ̀ẹ́ sọ pé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá kò sí nínú ìpàdé yẹn ní?
Tàbí ẹ ò rántí pé a ti fún àwọn gómìnà yín, Nàìjíríà, tí wọ́n wà káàkiri Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, ní Ìwé Ìtanijí, tí ó tí di bí ọdún kan-àbọ̀, báyi, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbàá, pé a mbọ̀ láti wá máa lo àwọn nkan wa ní ilẹ̀ Yorùbá? – àwọn bíi ilé-iṣẹ́ ìjọba, bárékè, èbuté, pápákọ̀ òfúrufú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣebí a fi ẹ̀dà ìwé náà rán’ṣẹ́ sí àrẹ yín nígbà náà l’ọhun? Àbí ó gbàgbé láti fi sílẹ̀ fún àrẹ yín ìsiìí ní? Ẹ mà npàyàn lẹ́rin o!
Àbí ẹ́ẹ̀ béèrè lọ́wọ́ àjọ àgbáyé ní? Ṣé wọn ò ti sọ fún yín ni, pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ti ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni wa, tí a sì ti gbé ìjọba wa wọlé, ní Ọjọ́ Kéjìlá, Oṣù Igbe, Ẹgbàá Ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nìnú rẹ̀ yí?
Àà, nàìjíríà, ẹ ti wá tẹ́ báyi! Ṣé ẹ̀yín kọ́ ni ẹ fi ọwọ́ yín buwọ́ lùwé ní ọdún náa lọ́hun nígbàtí Àjọ Àgbáyé gbé Ìkéde Ẹ̀tọ́ àwọn Ọmọ-Ìbílẹ̀, sí’ta, ní àgbáyé ni? O dáa, ẹ fẹ́ ṣorí kunkun, àbí? Ẹ ti ṣetán láti wá dàá sí rúgúdù, àbí? Kò ní dáa fún yín!
Ṣé àwọn ọmọ-ogun wa tí ẹ jí gbé ní Oríkò Ilé-Iṣẹ́ Ìjọba wa ní Olú-Ìlú wa ní Ìbàdàn ni ẹ nwá nkan tí ẹ máa kà sí wọn lẹ́sẹ̀, ẹ ò rí, ni ẹ ṣe nsọ̀rọ̀ ẹni tí ó bá wọ aṣọ ológun tàbí ti ọlọpá, pé ẹ máa jùú sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì, tàbí kí ó san mílíọ̀nù méjì náírà?
Agidí yín yẹn ló máa kó bá yín! Ẹẹ̀ tíì mọ nkankan o! Ṣé ìran Yorùbá lẹ npakuru mọ́? À, tiyín ti bá yín! Ẹ ti ṣìí ní gidi.
Àbí àwọn ọmọ Íbò ti kàn sí yín? Wọ́n ti kọjá àyè wọn, a dẹ̀ ti sọ fún wọn pé wọ́n ti tẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùba. Ṣé ìyẹn lẹ ṣe ndába òfin yín, pé ẹni tí ó bá ṣe nkan tí ó bá lòdì sí ìbágbépọ̀ yíò lọ ẹ̀wọ̀n ọdún márun, tàbí kí ó san mílíọ̀nù mẹ́ta owó naira rírùn yín? Orílẹ̀-Èdè yín nìyẹn-ẹ̀. Orílẹ̀-Èdè tiwa làwá wà-a. Ẹ jọ’ra yín lójú gan o! Olódùmarè kọ ẹ̀yìn sí yín; ta lẹ mbá tayò kíni?
Ẹ̀yin ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùba tí Democratic Republic of the Yoruba, ẹ má bẹ̀rù wọn o! A ò kìí ṣe Nàìjíríà, àwọn èèyàn wọn ní Nàìjíríà ni wọ́n mbá wí.