Orílẹ̀-Èdè jẹ́ àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ìran kan-náà; èyí tí ó túmọ̀ sí pé, wọ́n ní ORÍSUN kan-náà; èyí sì máa nf’ara hàn nínú pé èdè abínibí kan-náà pa wọ́n pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ìtàn kan-náà pa wọ́n pọ̀, wọ́n sì ní àṣà kan-náà tí ó pà wọ́n pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sábà máa nní ilẹ̀-àjogúnbá wọn tí ó ṣe-é tọ́’ka sí.

Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), pẹ̀lú àṣẹ Olódùmarè, a jẹ́ ORÍLẸ̀-ÈDÈ; ìran kan-náà ni wá: ìran tí gbogbo àgbáyé npè ní YORÙBÁ, tí a sì ti wa ní orí-ilẹ̀ àwọn Baba-nlá baba wa, láti àtètèkọ́ṣe wá: tí Ìtàn kan-náà pa wá pọ̀; ÈDÈ kan-náà pa wá pọ̀ (èyí tí ó jẹ́ èdè-abínibí, tí Olódùmarè nìkan ló mọ bí òun ti fi èdè yẹn sí wa l’ẹnu, ẹ̀dá kankan kò mọ bí èdè náà ti dé ẹnu wa; a ba bẹ́ẹ̀-ni láti ìran-d’iran àwọn baba-nlá wa; Olúwa ló ṣe èyí, kìí ṣe Ènìyàn!

Èyí sì ni Ọlọ́run fi yà wá sọ́tọ̀ bí ÌRAN kan-náà, èyí tí ó yàtọ̀ sí Ìran míràn ní gbogbo Àyé); bẹ́ẹ̀ náà ni ó fún wa ní Àṣà àti Ìṣe tiwa èyí tí a fi yàtọ̀ sí gbogbo Ìran míràn ní Àgbáyé; a sì ngbé ní ilẹ̀-àjogúnbá àwọn baba wa, èyí tí kò sì ní Àbùlà, bẹ́ẹ̀ ni ó yàtọ̀ pátá sí ilẹ̀-àjogúnbá Ìràn míràn gbogbo ní Àgbáyé.

Àwá Ìran Yorùbá, Indigenous Yoruba People, ti Democratic Republic of the Yoruba, sì ti ní ìṣèjọba tiwa láti àtètèkọ́ṣe, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àgbáyé sì mọ̀ wá láti ìgbà láíláí, kí òyìnbó amúnisìn ó tó dé; wọ́n mọ̀ wá gẹ́gẹ́bí ILẸ̀ YORÙBÁ, ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ILẸ̀-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ àti ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ.

Èyí ni àpẹrẹ ohun tí àgbáyé mọ̀, tí wọ́n sì npè ní ORÍLẸ̀-ÈDÈ.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024

Èyí yàtọ̀, pátápátá, gbáà, sí ohun tí ó jẹ́, Ètò, èyí tí ọmọ-ènìyàn tò jọ; tí kìí ṣe Ọlọ́run ni ó dá wọn bí orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ ÀKÓJỌPỌ̀ oríṣiríṣi àwọn orílẹ̀-èdè, tí oníkálùkù wọn ní ilẹ̀-àjogúnbá tirẹ̀, ṣùgbọ́n tí ọmọ-ènìyàn, lòdì sí Ìfẹ́-Ọlọ́run, fi àrékérekè, pẹ̀lú ipa, so wọ́n papọ̀, tí wọ́n sì purọ́ máa pè wọ́n ní Orílẹ̀-Èdè, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí amúnisìn fi ipá so pọ̀, láti máa darí wọn nínú Ètò Oko-Ẹrú, fún Ànfààní àwọn Amúnisìn ọ̀ún. Èyí kìí ṣe ORÍLẸ̀-ÈDÈ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ Ètò ÀTỌWỌ́DÁ àwọn amúnisìn wọ̀nyí fún ànfààní ti ara wọn, tí kò sì jẹ́ fún ànfààní àwọn tí wọ́n kó ní ẹrú bẹ́ẹ̀, ní orí ilẹ̀ wọn.

Nítorí náà, Orílẹ̀-Èdè yàtọ̀ pátápátá gbáà sí Ètò. Ètò jẹ́ ohun tí ènìyàn gbé kalẹ̀ fún’ra rẹ̀ láti mú nkankan jáde, ó sì ti tò-ó, lẹ́sẹẹsẹ, àwọn ohun tí òun máa ṣe, kí ètò náà kí ó le mú àbájáde tí òun fẹ́, kí ó le jáde, gẹ́gẹ́bí òun ti fẹ́ kí ó rí. Eléyi yàtọ̀ sí Ohun tí Olódùmarè dá fún’Ra Rẹ̀, tí kìí ṣe ọmọ-ènìyàn ni ó tò-ó, fún ìmọ̀-tara-ẹni-tirẹ̀.

Àwa Ìran-Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè tí Ọlọ́run dá, gẹ́gẹ́bí Orílẹ̀-Èdè, gẹ́gẹ́bí ìtumọ̀ ohun tí ó njẹ́ Orílẹ̀-Èdè, tí àgbáyé náà sì mọ̀ pé ohun tí ó njẹ́ Orílẹ̀-Èdè nìyẹn. Ṣùgbọ́n ibi tí wọ́n npè ní Nàìjíríà jẹ́ Ètò tí àwọn òyìnbó amúnisìn ìlú Gẹ̀ẹ́sì fi ọgbọ́n àrékérekè tiwọn kójọ, tí ó sì jẹ́ Ètò àtọwọ́dá wọn, gẹ́gẹ́bí amúnisìn; fún ànfààni ara wọn, láti kó àwọn tí ó wà ní nàìjíríà ọ̀ún ní ẹrú, ní orí ilẹ̀ wọn!

Nítorí náà, IRỌ́ pátápátá, gbáà, fún gbogbo àgbáyé, ni pípè Nàìjíríà, ilẹ̀ tí ó jẹ́ pé Ètò àwọn amúnisìn ìlú Gẹ̀ẹ́sì ní, tí kìí ṣe Orílẹ̀-Èdè; irọ́ pátápátá ni kí wọ́n máa pè-é ní Orílẹ̀-Èdè! Irọ́ tí Amúnisìn Gẹ̀ẹ́sì ti pa fún Àgbáyé ni, tí wọ́n sì ti tan Gbogbo Àgbáyé jẹ,

láti Ọdúnm’ọdún, tí wọ́n npe Nàìjíríà ní Orílẹ̀-Èdè ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ Ẹ̀tànjẹ tí ilú Gẹ̀ẹ́sì tan gbogbo-àgbáyé jẹ ni: Nítorí èyí, Ìkéde ti wá jáde sí gbogbo àgbáyé báyi o, Àṣírí nlá yí sì ti tú síta o, pé Nàìjíríà, ibi tí wọ́n ti npè láti iye ijọ́ yí ní “orílẹ̀-èdè” KÌÍ ṢE ORÍLẸ̀-ÈDÈ o, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹ̀tọ́-kankan láti ṣe ohun tí orílẹ̀-èdè nṣe! Òfegè ni Nàìjíríà, Ètò-ìkónilẹ́rú ÀWỌN AMÚNISÌN ÌLÚ GẸ̀Ẹ́SÌ NI, kìí ṣe orílẹ̀-èdè rárá-rárá.

ÀṢÍRÍ yí ni ó tú sí àgbáyé, nígbàtí Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, Màmá wa, bá gbogbo Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) sọ̀rọ̀, lórí ibi tí ọ̀rọ̀ ìlú wa, Orílẹ̀-Èdè D.R.Y, dé, látàrí jíjẹgàba tí Ètò àwọn Amúnisìn Gẹ̀ẹ́sì, èyí tí wọ́n npè ní Nàìjíríà, njẹgàba s’orí Ìlẹ̀ Orílẹ̀-Èdè tí Ọlọ́run dá, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).

Kìí ṣe èyí nìkan o! Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti kọ ìwé Àkọsílẹ̀, gbòógì, tí wọ́n sì ti fi ránṣẹ́ sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó pọ̀, káàkirí Àgbáyé, nínú èyí tí wọ́n ti tú àṣírí yí síta, kí gbogbo àgbáyé mọ̀, pé, kò sí Orílẹ̀-Èdè kankan ní àgbáyé yí t’ó njẹ́ nàìjíríà o, àti pé nṣe ni Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ntan gbogbo ayé yí jẹ, ní pípe Nàìjíríà ní Orílẹ̀-Èdè; bẹ́ẹ̀ ni Màmá wa sì ti fi ohun ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀gá amúnisìn gbogbo ní Àgbáyé, pé, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ajá yín t’ó jẹ́ ti Nàìjíríà ni wọ́n nṣe (òfegè tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè), ṣùgbọ́n tí wọ́n njẹgàba lórí Orílẹ̀-Èdè tí Ọlọ́run dá, Orílẹ̀-Èdè, Democratic Republic of the Yoruba. Ẹ kìlọ̀ fún wọn, kí wọ́n kúrò ní ilé-iṣẹ́-Ìjọba wa, gbogbo, ní Democratic Republic of the Yoruba.

Ojú olè rè-é níta o! Àṣé nàìjíríà kìí ṣe orílẹ̀-èdè, àṣírí yí ti wá tú sí ìgboro-ayé o, ọ̀rọ̀ sì ti lọ bá àwọn olórí-àmúnisìn tí ó jẹ́ pé Ìran wọn ni ó ṣe àkójọpọ̀ Ètò Àtọwọ́dá tí wọ́n npè ní Nàìjíríà, pé, Ó YÁ, Ẹ SỌ FÚN ÀWỌN AJÁ NÀÌJÍRÍÀ YÍN, TÍ WỌ́N NJẸGÀBA SÓRÍ ILẸ̀ D.R.Y, KÍ WỌ́N KÚRÒ NÍBẸ̀ NÍ KÍÁ!

Democratic Republic of the Yoruba