Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), àrà ọ̀tọ̀ ni ètò ìdìbò yóò jẹ́, àwọn ará ìlú ni yóò yan ẹni tí wọ́n fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí àyè láti fún ẹnikẹ́ni lówó láti ra ẹ̀rí ọkàn àwọn ará ìlú.

Gẹ́gẹ́ bí màmá wa Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, ọ̀rọ̀ òṣèlú ní Orílẹ̀ èdè D.R.Y kò la ti owó lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé igbá ìbò fẹ́ lọ sin àwọn ará ìlú ni kìí ṣe láti lọ kó ọrọ̀ jọ.

Nítorí náà, ètò ìdìbò ni Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) kìí ṣe ìdókòwò rárá, tí ẹnì kan a máa ná owó pẹ̀lú ìrètí wípé òun yóò rí èrè.

Màmá wa MOA tún sọ wípé, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ètò ìdìbò bá ti parí, ní èsì ìdìbò yóò ti jáde. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, ní orí òtítọ́ ni a gbé ìpìlẹ̀ wa lé, kò ní sí ojúṣàájú tàbí ìrẹ́jẹ nínú ohun gbogbo tí a bá ń ṣe ní orílẹ̀ èdè D.R.Y nítorí pé, bákan náà ni gbogbo wa.