Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Alààyè sí Àwa Ìran Yorùbá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ gbẹgudu ọ̀rọ̀ fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ti Oríl-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ní ọjọ́ ‘rú, ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́fà, odún 2024, tí ó jẹ́ àyájọ́ ọjọ́ tí Olóògbé MKO Abíọ́lá tí wọ́n já’wé olúborí nínú ìdíje fún ipò ààrẹ ní ìlú Nigeria nígbànáà, ṣùgbọ́n tí Ààrẹ Ológun, Ibrahim Badamọsi Babangida tí ó wà l’orí àléfà Nigeria nígbànáà tí ó da ìbò náà sọ nù.

June 12 remember MKO Abiola | Chief Mrs. Modupeola Onitiri-Abiola

Olóyè Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá kò ti’lẹ̀ fi ọ̀rọ̀ s’abẹ́ ahọ́n sọ nígbàtí wọ́n sọ fún gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, wípé, ní òtítọ́ àti ní òdodo, ìlú Nigeria l’ó ni ọjọ́ “June 12,” ó kàn jẹ́ wípé, ẹni tí orúkọ rẹ̀ sọ mọ́ ohun tí ó ṣẹ’lẹ̀ ní ọjọ́ náà l’ọhún, èyíinì, MKO Abíọ́lá, Yorùbá ni. Nítorí náà, a ní l’ati rántí ẹ, nít’orí wípé ògo Yorùbá ni.

Ka Ìròyìn: Àwọn Òyìnbó, Aláyébàjẹ́ Ni Wọ́n

Ṣùgbọ́n, ìdí tí ó fi jẹ́ wípé “ọjọ” Nigeria ni June 12 jẹ́, òun ni wípé, ojọ yẹn, ọjọ́ ìbí ọmọ Fúlàní t’ó sọ wípé kí wọ́n kó ìran Yorùbá àtí àwọn ìran t’ó kù ní Nigeria ní’gbà yẹn, sí oko ẹrú, èyíinì, Ahmadu Bello, ọjọ́ ìbí ẹ̀ ni June 12 yẹn, àti wípé, ní ọkàn àwọn Fúlàní, nígbàtí wọ́n mú ọjọ́ yẹn fún ìdìbò 1993 yẹn, wọ́n fẹ́ fi yẹ́ bàbá wọn Ahmadu Bello sí ni – ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ sí’lẹ̀ fún wọn wípé kí wọ́n kó Yorùbá àti àwọn t’o kù l’ẹrú.

L’otítọ́ àti l’ododo, Babangidá fún’ra ẹ̀ l’ó wá bá MKO wípé kí ó wá du ipò ààrẹ, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé ọ̀nà l’ati mú MKO ba’lẹ̀ ni, nítorí Babangida fún’ra rẹ̀ kò fẹ́ kúrò l’orí oyè, ṣùgbọ́n ó wò’ye wípé àwọn ọmọ Yorùbá nìkan ni wọ́n le dí òun l’ọwọ́ àti wípé MKO nìkan l’ó kù ní ọmọ Yorùbá tí òun kòì tíì mú ba’lẹ̀ tàbí mú s’abẹ́.

Èrò wọn ní wípé wọ́n á gba ọ̀nà èbùrú l’ati ri wípé kò já’wé olúborí, kí wọ́n lè sọ wípé Yorùbá kò l’ẹnu ọ̀rọ̀ mọ́ ní ìlú Nigeria, ṣùgbọ́n Olódùmarè ṣe ìyanù nígbànáà, nípasẹ̀ Mama, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí MKO sì já’wé olúborí.

Bí MKO ṣe di ẹni tí orúkọ rẹ̀ rọ̀ mọ́ June 12 nìyẹn, tí èyí kò sì dùn mọ́ inú àwọn Fúlàní rárá nítorí wípé bàbá wọn Ahmadu Bello ni wọ́n fẹ́ fi June 12 yẹn yẹ́ sí, ní ìrètí wípé MKO kò ní já’wé olúborí, ṣùgbọn kí ọmọ Fúlàní k’ó já’wé olúborí, tí kò sì wá rí bẹ́ẹ̀. Òun ni ó fi wá di wípé Babangida fa’gi lé ètò ìdìbò náà.

Nígbàtí wọ́n wá pa Abíọ́lá, wọ́n rò wípé àwọn ti ṣẹ́’gun ni; ṣùgbọ́n pí pa tí wọ́n paá ni nkan tí ó gba agbára l’ọwọ́ wọn, nítorí ọmọ Yorùbá ní àwọn ò ní gbà.

Ka Ìròyìn: Ọmọ Yorùbá, Ẹ Ṣọ́’ra! àwọn ọmọ Igbo ti ntú ní ọ̀pọ̀ yanturu wọ ìlú Èkó

Olóyè Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá tún wá sọ wípé, l’oótọ́, àwọn ológun yẹn ní ó fí ọwọ́ wọn pa Abíọ́lá, ṣùgbọ́n òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé àwọn ènìyàn t’ó da’lẹ̀ Abíọ́lá, àwọn gan-an gan ni wọ́n pa Abíọ́lá!

Àwọn ọ̀dàlẹ̀ wọ̀nyí, nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà ni wọ́n wà pẹ̀lú Abíọ́lá o!

Nígbàti ohùn awọn ará ìlú ti lé Babangida kúrò l’orí oyè, ni ó wá fi Ṣónẹ́kàn sí’bẹ̀, ṣùgbọ́n tí Abacha lé Ṣónẹ́kàn kúrò l’orí oyè! Àfì ‘gbàtí Abacha bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú MKO sí’nú ipò o! Toò, ojú ọ̀dàlẹ̀ ré!

JUNE 12 NÍ ÌTUMỌ̀ NÍNÚ Ẹ̀MÍ – MOA

Olóyè Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, nínú ọ̀rọ̀ wọn ní àyájọ́ June 12, sọ wípé ọ̀rọ̀ June 12 jẹ́ ohun tí ó ní’tumọ̀ nínú ẹ̀mí àti wípé gbogbo ohun tí ọ̀tá ṣe yẹn, Olódùmarè fi ṣẹ́’gun fún àwa ọmọ Yorùbá ni.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ wípé, gbogbo àwọn ìran tí ó wà ní àkópapọ̀ amúnisìn tí wọ́n npè ní Nigeria, àwọn ni ó ni June 12! Ṣùgbọ́n ẹni tí a wá mọ June12 pẹ̀lú ẹ̀ ni MKO Abíọ́lá, èyí tí ó wá já sí ògo ọmọ Yorùbá! Èyí wá tú’mọ̀ sí wípé ó di dandan kí a máa rántí June 12!