Ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní ọba àti baálẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá ti wá kọjá àfẹnusọ, bí a ti ń gé wọn lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń bọ òrùka.
Nínú ọ̀rọ̀ màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) tí wọ́n bá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) sọ láìpẹ́ yí, wọ́n sọ nípa àwọn baálẹ̀ kan ní ìlú Ìmẹ̀kọ, ìpínlẹ̀ Ògùn ní orílẹ̀ èdè D.R.Y tí wọ́n ń fún ní saarè ilẹ̀ mẹ́fà ẹni kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú irúgbìn GMO.
MOA wípé, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni gbíngbin irúgbìn GMO ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Àwọn amúnisìn fúnra wọn gan-an kò gba irúgbìn GMO ní orílẹ̀ èdè wọn,orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà pàápàá takòó, òun ni àwọn baálẹ̀ yí lọ ń gbà.
Irúgbìn GMO tí wọ́n sọ pé ó lè ba ilé ọmọ jẹ́, ó lè ba ilẹ̀ jẹ́, àti pé, ó lè fa oríṣiríṣi àìsàn fún ẹni tó bá jẹẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn amúnisìn náà kúkú ti mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí ò fẹ́ràn àwọn ènìyàn wọn, wọ́n kàn ń ṣe bó ti wù wọ́n ni.
Fúnra àwọn amúnisìn yí ni wọ́n sọ wípé àwọn fẹ́ dín iye eniyan tó wà ní àgbáyé kù, se irú wọn ló fẹ́ gbé nǹkan gidi wá fún yín?
Wọ́n ní àwọn fẹ́ pa gbogbo àwọn àgbẹ̀ tán, àti pé ẹni tó bá fẹ́ dá oko yóò lọ gbé ilé ọmọ ìyàwó tàbí ti ọmọ rẹ̀ wá kó tó lè ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn, èròǹgbà àwọn amúnisìn nìyí.
MOA tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ wọn pé, gbogbo ẹ̀yin baálẹ̀ tí wọ́n ti fún ní irúgbìn GMO yí, ẹ má gbìyànjú làti gbìn-ín sórí ilẹ̀ ò, nítorí tí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Ó sàn kí ẹ lọ gbé e pamọ́ sínú ìgò kí ẹ má jẹ̀ẹ́ kó jáde síta rárá.
Fún ìdí èyí, a rọ gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) pé, kí a jẹ́ ojú lalákàn fi ń s’ọ́rí, tí a bá rí ẹnikẹ́ni tó ń ṣe ohunkóhun tó lè ṣe àkóbá fún ọmọnìkejì ní àyíká wa, ẹ má ṣe dágunlá, ẹ tètè fi tó àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè D.R.Y létí.
Orílẹ̀ èdè D.R.Y tako irúgbìn GMO, àti ẹni tó fún ni, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.