Ohun tí aláìmọ̀kan fi ń ṣe ara rẹ̀ ló pọ jù̀. Nínú ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) bá wa sọ láìpẹ́ yí, màmá sọ nípa àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní gómìnà ètò àwọn amúnisìn tí wọ́n ń pè ní Nàìjíríà.
Màmá wípé, kílódé tí wọ́n ro ara wọn pin? Ǹjẹ́ ẹ̀yin yìí ti lẹ̀ mọ̀ pé ìwé ìgbàpadà tí a mú wá fún yín pé ẹ̀yin gan-an wà nínú àwọn tó máa jẹ àǹfààní rẹ̀?
Ṣébi ẹ ò kúkú mọ̀ pé ètò àwọn amúnisìn ni ibi tí ẹ wà yẹn àti pé orí òfo ni ẹ jókòó lé. Ẹ máa rí ìtumọ̀ rẹ̀ tó bá yá.
Kí wá lódé tí ẹ ò lè ro àròjinlẹ̀ tí ẹ fẹ́ jẹ àwọn ọmọ yín m’áyé tí ẹ sì tún fẹ́ ba orúkọ ìdílé yín jẹ́, lórí ohun tó jẹ́ àǹfààní ìran yín.
Tó yẹ kí ẹ kúrò pẹ̀lú sùúrù kí ẹ sọ pé ẹ ò mọ̀ pé bí ó ṣe rí rèé,tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ẹ jẹ́ kí a bọ́ sí orílẹ̀ èdè wa.
Ṣùgbọ́n ẹ kọ̀, ẹ ò se bẹ́ẹ̀ nítorí ẹ ń rí jẹ ní’dìi mọ̀dàrú, nítorí àpapín tí wọ́n ń ṣe fún yín, ẹ kọ̀ láti sọ òtítọ́, gbogbo àwọn tó ti kú ikú tí kò yẹ́ kí wọ́n kú, ẹ̀yin àti ìdílé yín lóni ẹrù rẹ̀. Ṣé ẹ rò pé ẹ lè jẹ gàba títí láé ni, kò ṣeéṣe, ẹ ò lè jẹ gàba fún ìgbà pípẹ́ pàápàá.
Ǹjẹ́ ẹ tilẹ̀ mọ̀ pé inú oko ẹrú ni ẹ̀yin gan-an pàápàá wà, àbí ẹ ò mọ gbogbo ohun tí ojú yín rí kí ẹ tó dé ibi tí ẹ dé nínú ètò àwọn amúnisìn tí wọ́n fi yín há sí.
Tí kìí bá ṣe ọ̀nà àlàáfíà tí Ọlọ́run ní kí a tọ̀, tí a rí àánú gbà, èyí tí a ò fi jagun nítorí pé ìbẹ̀rẹ̀ ogun ni èèyàn ń rí ẹnìkan kì í mọ òpin rẹ̀.
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bá wá ń gbèrò wípé ẹ fẹ́ da nkan rú tàbí jagun, ayé ẹni bẹ́ẹ̀ máa dàrú ni.
Kò ní sí ogun ní D.R.Y nítorí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló gbé D.R.Y jókòó. Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bá ń sọ pé ẹ máa bìíwó, Ọlọ́run máa payín run ni.
A tún fẹ́ fi àsìkò yí rán wa létí gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe sọ pé kí a túbọ̀ máa polongo rẹ̀ wípé, Nàìjíríà kìí ṣe ìlú bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe orílẹ̀-èdè, ètò àwọn amúnisìn lásán ni. Àwọn amúnisìn ló kóo papọ̀ fún àǹfààní ara wọn láti wá máa kó wa lẹ́rù.
Òfo lórí òfo ni ibi tí wọ́n ń pè ní Nàìjíríà, nítorí pé orílẹ̀ èdè ni ibi kan tàbí àgbègbè kan tí èdè kan, àṣà kan, ilẹ̀ àjogúnbá kan pa wọ́n pọ̀.
Ṣùgbọ́n kíni a leè tọ́ka sí tí ó júwe Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀-èdè? Kòsí. Nítorí náà, ìtànjẹ ni wọ́n ń pè ní Nàìjíríà.
Àwọn ajẹgàba tí wọ́n fihá síbẹ̀ náà sì mọ̀ ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti sọ òtítọ́ nítorí ìjẹkújẹ àti ìwà ìmọt’ara-ẹni-nìkan wọn.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè pé ó ti kó ìran Yorùbá yọ kúrò nínú ètò amúnisìn.
D.R.Y ti di orílẹ̀-èdè aṣàkóso ara ẹni. A ò sí lábẹ́ amúnisìn mọ́.