Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) gbèdéke yóò wà fún àwọn àjòjì tó bá wù láti gbé ní orílẹ̀ èdè wa.
Bí àpẹẹrẹ, àjòjì kò leè jẹ adarí ní ilé iṣẹ́ kankan ní ilẹ̀ Yorùbá, kò sí ààyè fún àjòjì láti kó ọmọ Yorùbá lẹ́rú mọ́, àjòjì kò ní ẹ̀tọ́ láti gbé igbá ìbò tàbí láti dìbò, bẹ́ẹ̀ sì ni ó lójú àwọn ǹkan tí àjòjì ní ẹ̀tọ́ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Ìdí ni wípé, ìran Yorùbá ti j’ìyà púpọ̀ nípa kíkó àjòjì mọ́ra, nítorí irú ẹ̀dá tí a jẹ́. Gbogbo àgbáyé ni ó mọ̀ pé ọmọlúwàbí ni wá, a sì ní ẹ̀mí ìkónimọra lọ́pọ̀lọpọ̀.
Gbogbo ọjà tí àwọn ọmọ Aládé ń tà tẹ́lẹ̀ ti di ti àwọn àjòjì. Kí àwọn amúnisìn tó dé ni ìran Yorùbá ti ń ṣ’òwò, ṣùgbọ́n bí ààyè ṣe gba àwọn àjòjì tó lónìí, púpọ̀ nínú àwọn ọjà wa ni àwọn àjòjì ti gbà, ọmọ Yorùbá tó bá wà ní agbègbè wọn, wọ́n yóò fi imú rẹ̀ dánrin, àwa ọmọ Yorùbá kò lẹ́nu ọ̀rọ̀ lórí ilẹ̀ babańlá wa mọ́.
Ní ilé iṣẹ́ gbogbo-gbò àti aládàáni pàápàá, àwọn àjòjì ló ń jẹ́ ọ̀gá níbẹ̀.
Àwọn àjòjì ń ra ilẹ̀ sí àwọn àgbègbè kan tí àwa ọmọ ònilẹ̀ gan-an kò tó bẹ́ẹ̀ láti gbé. Àjòjì wá di ẹni tó ń ta’lẹ̀ t’alé ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣé oko ń jẹ́ ti baba àti ọmọ kò má ní ààlà ni?
Nítorí náà, ìpìlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Olódùmarè lo màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gbé kalẹ̀ yí kò fi àyè fún àjòjì láti jẹ gàba tàbí fi ọwọ́ lalẹ̀ fún àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P).
Àjòjì tí kò bá lè faramọ́ àlàkalẹ̀ àti òfin orílẹ̀ èdè D.R.Y kó fi ilẹ̀ wa sílẹ̀ láì fi àkókò ṣòfò, nítorí pé a ti kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ nípa àṣìṣe tí àwọn babańlá wa ti ṣe sẹ́yìn, ojú wa sì ti là nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìtúsílẹ̀ tí màmá wa MOA máa ń sọ fún wa, ìran Yorùbá kò ní kúrò nínú oko ẹrú kan bọ́ sí òmíràn láéláé.