Gẹ́gẹ́ bí orin tí a má ń kọ nígbà dé ìgbà ni ilẹ̀ Yorùbá, wípé:Ká sá máa dúpẹ́ ló tọ́, Ká sá máa dúpẹ́ ló tọ́,Ọrọ wá ó gbà ẹjọ́ wẹ́wẹ́, A fi ká sá máa dúpẹ́ ló tọ́. Ní ìkòríta tí a dé bá yí, bí màmá wa Ìyá Ààfin Modupẹ́ọla Onitiri-Abiọ́la ṣe bá àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá sọ̀rọ̀ láìpẹ́ yìí.
Wọ́n ní ṣe ni kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ọwọ àánú àti agbára rẹ̀ tó fi kó wá jáde kúrò nínú òkùnkùn àwọn amúnisìn, tí à sí ti bọ̀ sì ímọ́lẹ òmìnira wa. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní padà sí ibẹ̀ mọ̀ titi láéláé, a kò ní kúrò ní oko ẹrú kan, ká tún bọ́ sì òmíràn.
Nítorí a ti jáde kúrò ní ìlú agbesunmọ̀mi Nàìjíríà tí àwọn ẹni ìkà amúnisìn ṣe akòpọ̀ rẹ̀, nítorí ìfẹ́ kú fẹ́ ara wọn, láti lè má jawa ni olè, àti kí wọn máa jẹgaba lórí wa. Màmá MOA jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe irú iṣẹ́ agbára bẹ́ẹ̀. Kò ṣeṣe fún ẹ̀dá èèyàn kankan.
Fún ìdí èyí, àwa ọmọ aládé gbudọ máa dúpẹ́ ní gbogbo ìgbà lọ́wọ́ Olódùmarè fún itusilẹ̀ kúrò ní oko ẹrú atọ́dúnmọ́dún amúnisìn.
Màmá wa tẹ̀sìwájú láti máa ṣe aláyè àwọn pàtàkì ìdí ọpẹ́ wa. Gbígba àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P), tí Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ikú òjijì torí àìríjẹ, àìrímu, ìpayà, àìsàn, ìrònú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Kí ló sì fà á, àgbékalẹ̀ ètò àwọn akónilẹrú amúnisìn ni, láti ìgbà tí wọn tí ṣe àtọwọ́dá arúmọjẹ ìlú agbésùmọ̀mí Nàìjíríà. Níbi tí kò sì iṣẹ́ fún ara ìlù, kò sí ọ̀nà tó da. Àwọn ilé ìwé dẹnu kọlẹ̀. Wọ́n ṣà fẹ́ ba ayé àwọn òbí jẹ́, kò sí ìtọ́jú ìlera pípé fún aláìsàn. llé ìwòsàn di àpatì.
Wọ́n fọwọ́ sí ìkórè kíndìnrìn àwọn ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ ni wọn fọwọ sì aṣe ̣kú pani irúgbìn GMO. Wọn sí sọ àwọn ọ̀dọ́ di ìdàkudà. Wọn kò dẹ́ kun pípa àwọn àgbẹ̀ lóko. Wọ́n sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di aláìrí’lé gbé, orí àtàn ni ẹlòmíràn ń gbé. Ìpinnu àwọn ènìyàn burúkú wọ̀n yí ni kí wọ́n máa pàyàn díẹ̀ díẹ̀.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run Èdùmàrè kò gbà fún ìṣẹ ibi wọn láti tẹ̀síwájú. Òun ló fi gbé màmá wá dídé ni déédéé ìgbà yìí ati ni déédéé àsìkò yìí láti jà àjàṣẹ́gun fún òmìnira àwa ọmọ aládé, Ó sì ti ṣe ìyanu.
Ati kúrò ní àárín àwọn ẹni òkùnkùn ariremáṣe Nàìjíríà, láti ogúnjọ oṣù Bélú, ẹgbàáọdún ó lè méjìlélógún. A sì ti ṣe ìbúra wọlé fún bàbá wá Mobọlaji Ọlawale Akinọlá Ọmọkọrẹ, Olórí Aṣojú Ètò Ìmójútó ara ìlú, láti ọjọ́ kejìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lè mẹ́rìnlélógún. Tí iṣẹ́ ètò àmójútó ará ìlú sì ti bẹ̀rẹ̀.
Àwa ọmọ aládé ti kúrò nínú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀. Ìdí nìyí tí afi gbudọ̀ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Olódùmarè ní ìgbà gbogbo. Ibukun ni fun orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantitwa tí Yorùbá (D.R.Y).