Ó ti wá d’ojú ẹ̀ báyi, o!
Àwọn ọmọ ènìyàn ndá ọ̀ràn mọ́ ọ̀ràn, ní ilẹ̀ Yorùbá; bóyá àìm’ọ̀kan l’o nṣe wọ́n ni o, tàbí àf’ojúdi ni o, tàbí ìjọba ìlú t’ó f’ẹ̀gbẹ́ tì wá, èyíinì, nàìjíríà, l’ó rán wọn ní’ṣẹ́ ni o, èyík’eyí t’ó wù k’ó jẹ́, kò kàn wá; ṣùgbọ́n a fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀, pàápàá àwọn ọmọ Íbò, tí wọ́n máa mbẹ́ ìbẹ́kú’bẹ́, ìbẹ́ ìgbé’raga tí ó máa pa’wọ́n run l’orí ilẹ̀ Yorùbá, wípé, Yorùbá KÒ SÍ L’ABẸ́ NIGERIA MỌ́!
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XÀìm’òfin á máa pa’yàn – bí kò ti’lẹ̀ kú ní’pa ti ara, ó le kú ní ọ̀nà míràn. Ṣúbọ́n, kí á mọ òfin, k’á tún máa ṣẹ̀ sí òfin náà, ìyẹn burú jáì!
Parí-parì gbogbo rẹ̀ ni wípé, kò sí “mi ò mọ̀ niì” l’abẹ́ òfin.
- Ojú Àwọn Apànìyàn Agbèsùnmọ̀mí Ilẹ̀ Yorùbá Re
- Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Ṣe Òfin Oní’lé-Gbé’lé Ní Èkìti!
- Ọmọ Yorùbá Ṣe Ìkìlọ̀ Tí Ó L’agbára Fún Bill Gates !
- Ajílẹ̀ Aburú Ti Ba Nkan Jẹ́ Ní Ìlú T’ó F’ẹ̀gbẹ́ Tì Wá
- Ọ̀rọ̀ Ti Di Orílẹ̀-Èdè S’orílẹ̀-Èdè
Nítorí eléyi, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa, k’á gb’ìyànjú l’ati fi tó àwọn ènìyàn l’etí, pàápàá àwọn ọmọ Íbò tí ó jẹ́ wípé wọ́n rò wípé àwọn ni àwọn ní ayé yí ní ìkáwọ́, kí wọ́n mọ̀ wípé pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ d’ọwọ́ wọn o! ní’lẹ̀ Yorùbá; Yorùbá ti já’de kúrò nínú Nigeria, gbogbo ẹni tí ó bá ṣì nhu ìwà àìbìkítà, tàbí ìwà àf’ojúdi, l’orí ọ̀rọ̀ yí, kò kàn wá o, ohun tí ojú ẹni náà bá rí!