Ìròhìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́, tí a rí fídíò rẹ̀ ní’bi tí oníròhìn kan ti nṣe ìfọ̀rọ̀-wá’ni-lẹ́nuwò pẹ̀lú ìkan nínú àwọn àgbà-òṣìṣẹ́ ìjọba-àná ní ìlú tó f’ẹ̀gbẹ́ tì wá, Nàìjíríà, ni a ti gbọ́ pé láarín àwọn tí ó nṣe ìjọba wọn l’ọhún náà ni àtakò ti máa nd’ojúkọ àwọn tí ó bá fẹ́ fi òtítọ́ inú ṣe iṣẹ́; gẹ́gẹ́bí pé kí á rí ìwà ìbàjẹ́ tí ó yẹ kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ lé lórí, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ àwọn ọ̀gá wọn ni á tún gbẹ́sẹ̀ lé ìwádí tí ó bá yẹ kí wọ́n ṣe.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa nsọ, ọ̀rọ̀ Nàìjíríà kò kàn wá; ṣùgbọ́n, títí tí Olódùmarè máa fi bá wa lé wọn lọ kúrò lórí ilẹ̀ wa, ilẹ̀ Yorùbá, ó di dandan kí á máa pe àkíyèsí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá sí ìwà apànìyàn àti olè tí Nàìjíríà nhù, ní bí ó ṣe fa ìpalára fún Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, nínú fídíò ọ̀ún, a gbọ́ bí àwọn kan ṣe fi ọ̀nà èbùrú kó ọgọ́rin ọ̀kọ̀ olówó-iyebíye wọ’lé láì san owó ìgbẹ́rù-wọlé.
Dájúdájú, àwọn ibodè tí ó jẹ́ ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, tàbí èbúté Orílẹ̀-Èdè wa ni wọ́n máa nsábà lò láti kó ẹrù bẹ́ẹ̀yẹn wọ’lé. Èyí l’ó fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà kí ó kàn wa.
A dúpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó ti fún wa ní Ìṣẹ́gun dé’bi tí a dé l’oní; tí a dẹ̀ mọ̀ pé àṣepé ni iṣẹ́ Rẹ̀; a sì dúpẹ́ lọ́dọ̀ Màmá wa, Ìyá Ìran Yorùbá, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, fún fíf’ara jìn tí wọ́n fi ara jìn fún iṣẹ́ yí; nípasẹ̀ èyí, a ní ìdánilójú pé, ní àìpẹ́, àti ní àìjìnà, a máa rí ẹ̀hin àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà wọ̀nyí, kúrò ní orí ilẹ̀ wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Gbogbo ohun nípa ilẹ̀, agbègbè àti gbogbo ibodè pẹ̀lú èbúté wa ni yíò wà ní ìkáwọ́ àwa onínkan, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí irú ìwà ìbàjẹ́ ti Nàìjíríà yẹn tí a máa gbà láàyè.