Ọ̀dọ́mọbìnrin kan ti ké gbàjarè lórí ẹ̀rọ ayélujára nípa ìwà búburú ọwọ́ àwọn obìnrin ọ̀dọ́ ní ìlú Warri, ìpínlẹ̀ Delta ní ìlú agbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà tó fi ẹ̀gbẹ́ tì wá.
Lórí fọ́nrán náà, ó wípé ṣe ni wọ́n lọ ńta ẹyin tí ó yẹ kí wọ́n fí bímọ tí wọ́n sì ńfi owó rẹ̀ ra irun òyìnbó nítorí oge síṣe.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. pín sórí àgbàgbé ti X (Twitter)Ó wá ń béèrè pé lásìkò tí wọ́n bá pinnu láti bímọ, kí ní wọ́n fẹ́ lò? Yàtọ sí èyí, ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ pé oríṣiríṣi àìsàn tí yíò jásí ikú ní ó máa ńtẹ̀lè irú ìgbésẹ̀ báyìí
Ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, a ní oríṣiríṣi ọnà láti ṣe irun wa l’óge bíi ṣùkú, pàtẹ́wọ́, àdìmọ́lẹ̀, kọjúsọ́kọ, àgàba, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, irú àwọn èyí kò lè fa ìpalára, kò sí nilo owó tó nira.
Ojúkòkòrò àti gbígbé ńkan aláwọ̀ funfun ga ju tí ara ẹni lọ, tí ó túmọ̀ sí ẹ̀mí àti ìwà ẹrú lásán làsàn ni èyí jẹ́.
Ọmọ Aládé àti ọmọlúàbí ni àwa ọmọ Yorùbá jẹ́, nítorínáà, irú ìwà búburú yìí kò gbọdọ̀ farahàn láàrin àwon ọmọ wa.
Gbogbo ẹ́kọ́ àsà àti ìṣe wa dáradára ní a ó fí kọ́ àwọn ọmọ wá ní ilé ìwé wa, bẹ̀rẹ̀ láti aláọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ilé ìwé gíga gégébí àlàkalẹ ètò ẹ̀kọ́ tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ti ṣètò fún orílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Yorùbá.
Àwa òbí pàápàá níláti ṣe ojúṣe wa láti kọ́ àwọn ọmọ wa láti kékeré nínú ilé kí wọ́n má báà darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rẹ búburú tí yíò kọ́ wọn ní ìwà àti ìṣe ẹrú.