United Arab Emirates (UAE) àti ìlú agbèsùnmọ̀mí Naijiria parí àríyànjiyàn tí ó wa láàrín wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Mohammed Idris tí ó jẹ́ mínísítà wọn fún ìròhìn ati àlàyé ti sọ síta ní ọjọ́ Ajé pé àwọn tí fí ẹnu kò lórí bí àwọn ará Naijiria yíò tí máa rin ìrìnàjò lọ sí UAE.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Pin Sori Agbagbe X (Twitter)
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Sùgbọ́n tí ó wa níbẹ̀ báyìí ni pe, ará Nàìjíríà ti ó bá fẹ́ lọ síbẹ̀ yíò kọ́kọ́ san ọ̀jìlélẹ́gbẹ̀ta ẹgbẹ̀rún naira sí ọ́fíísì aṣojú UAE ní Abuja, tí wọn ó fí ṣètò fọ́ọ̀mù ati awọn ìwé àṣẹ tí UAE béèrè fun, owó eléyìí kò ṣeé gbà padà, bóyá wọn rí físà gbà tàbí wọn kò ri gbà.

Lẹ́hìn náà wọn gbọ́dọ̀ ní ìwé tí ó jẹ́rìí si pé ẹ́gbẹ̀rún mẹwa dọ́là wà nínú bánkì wọn fún oṣù mẹ́fà.

Ní àfikún, ẹnití ó ńbẹ̀bẹ̀ fún físà ní láti fí ìdánilójú han pé òun tí ra tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ òfúrufú fún àlọ ati àbọ̀.

Ọ̀nà miran fún UAE  láti fi ọgbọn sọ pé kí agbèsùnmọ̀mí Naijiria má wọ ìlú àwọn mọ́ nìyẹn, nítorí gbogbo orilẹ̀-èdè ló mọ Naijiria gẹ́gẹ́bí arúfin, olè, agbèsùnmọ̀mí àtí ìkà lágbàyé, fún ìdí èyí, kò sí ẹnití ó fẹ́ irú àwọn ará ìlú búburú yìí lọ́dọ̀ wọn.

Tí àwọn olórí atí gbogbo aṣíwájú agbèsùnmọ̀mí Naijiria bá dára, wọn á tún ilé wọn ṣe, ọrọ̀ ajé wọn tí bàjé, kò sí ààbò, iṣẹ́ ò sì, iná mọ̀nàmọ́ná pàápàá tí dojúrú, àwọn ìjọba wọn kò fẹ́ ti ará ìlú, ìdí rèé tí àwọn ará ìlú fi ńsá kúrò nilu.

Democratic republic of the Yoruba ominira news update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, World 2024

Àwá dúpẹ́ pé Yorùbá tí kúrò lára Naijiria lati ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wáọdúnóléméjìlélógún, tí a sì ti di orílẹ-èdè olómìnira bẹ́ẹ̀ni ìjọba wá tí bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe, ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rinlélógún. Nitorinaa, a kìí ṣe ará àpèjúwe búburú yìí mọ́. 

Ti àwọn Adelé wa bá ti wọ ilé iṣẹ́ ìjọba, Democratic Republic of the Yorùbá yíò pegedé, gbogbo àgbáyé ní yíò máa wá sí ọ̀dọ̀ wa, ko si ìdí fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá láti japa nítorí ǹkan tí a ní lórí ilẹ̀ wa ó tó wà jẹ, ilé yíò dùn púpọ̀ bẹẹni àwọn orílẹ-èdè tó kù yíò máa bẹ̀ wá pẹ̀lú físà wọn ni.

Ọmọ D.R.Y. ẹ jẹ́ ka dìde sínú ògo wa.