A ṣẹ̀ṣẹ̀ tí ẹsẹ̀ kan bọ́ odò, ọ̀ni ń fà á, ọjọ́ wo ni agbára dè ọwọ́ ijọba ìbílẹ̀  (ìjọba a fi ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ Yorùbá) tí gb’ódó ń ró’sọ tí wá bẹ̀rẹ̀ ní Council kan, tí a rí fídíò kan ni ori ayélujára níbi tí a ti rí arábìnrin kan, bóyá ó jẹ́ akọ̀wé ni a kò lè sọ, ṣùgbọ́n, a ríi tí ó ń pariwo lé ìgbàkejì alága gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń pé nínú fídíò na, tí ó ń kó àwọn ẹrù fáìlì láti inú ọfìsì sínú ọkọ̀ rẹ̀.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X
The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ẹ béèrè lọ́wọ́ igbákejì alága yìí pé ṣé ó fẹ́ maa yí ìwé ní kíákíá ni?, à ṣẹ̀ṣẹ̀ s’oge àparò, ab’àyà telútelú tí Yorùbá máa ń wí nìyẹn o.

Ṣe ìlú tí ó ní òfin àátẹ̀lé, tí wọ́n sí ń tẹ̀lé e kan a máa rí báyìí?. Ṣùgbọ́n ọpẹ ni fún Ọlọ́run tí ó fún àwa I.Y.P. ní ìpìlẹ̀ tí ó dára láti ọwọ́ màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá tí ó fi rán.

Irú ìwà wọ̀bià bí eléyìí kò lè wá’yé ní orílè-èdè Democratic Republic of the Yorùbá tiwa, níbi tí gbogbo àwa Indegenous Yorùbá People ti máa rí ṣe pẹ̀lú ètò tí olórí Adelé wa àti àwọn Adele yókù tí là sílẹ̀ fún wa, tí kì yóò sí ìwà ọkanjú’wà báyìí.