Ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ohun gbogbo ni ó wà létò-létò, ohun gbogbo tí a nṣe, àti èyí tí a óò máa ṣe, létò-létò ni. 

Olódùmarè fún’ra Rẹ̀ ti fún àwa Ìran Yorùbá ní Àlàkalẹ̀ tí a óò máa tẹ̀lé títí òpin ayé, èyí tí Ó sì gbé fún wa nípasẹ̀ Màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin). Lórí àlàkalẹ̀ yí sì ni gbogbo ohun tí yóò máa jáde láti ẹnu wa, ní ìwà àti ní ìṣe gbọ́dọ̀ dúró lé.

Ní àìpẹ́ yí, Màmá wa, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí Ìran Yorùbá, MOA, nígbàtí wọ́n ń bá àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) sọ̀rọ̀,wọ́n tún ṣí wa lójú sí ìkan nínú àwọn ohun tó ṣe gbòógì ní D.R.Y wípé, tí a bá sọ pé “I.Y.P,” ó ní ìtumọ̀; tí a bá sì sọ pé “D.R.Y” èyí tí a ò fi ìrònú “I.Y.P” sí, ìyẹn náà ní ìtumọ̀, tí méjèèjì sì jẹ́ ohun rere fún Ọmọ Yorùbá.

Ẹni tí ó jẹ́ pé ìkan ṣoṣo péré nínú àwọn òbí tí ó bíi ni ó jẹ́ ọmọ Yorùbá, tí èkejì kìí ṣe ọmọ Yorùbá, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní ànfààní ti níní òbí kan tí ó jẹ́ Yorùbá, èyí tí ó ga ju ti àjòjì lọ.

Ẹni tí bàbá àti ìyá rẹ̀ jẹ́ I.Y.P, irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀, I.Y.P ni òun fúnra rẹ̀.

Màmá wá fi yé wa, pé, àwọn tí wọ́n jẹ́ I.Y.P yí (tí a sì tún máa npè ní ‘I.Y.P ti D.R.Y,’) àwọn ni ó ní iṣẹ́ láti ṣe, kí wọ́n ríi pé ohun gbogbo tí Olódùmarè fẹ́ fún Ìran Yorùbá, kí wọ́n ri pé ó wá sí ìmúṣẹ.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Àwọn ni ẹrù ìṣerere  ìran Yorùbá wà ní ọrùn wọn, kí wọ́n ríi pé bí ó ṣe yẹ kí Ìran Yorùbá rí, bẹ́ẹ̀ gan-an ló rí, nípasẹ̀ Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Wa.

I.Y.P, èyíinì, ẹni tí ó jẹ́ pé tọ̀tún-tòsì àwọn òbí tí ó bíi wọ́n jẹ́ I.Y.P, àwa I.Y.P yí ni ẹrù ìṣerere ìran Yorùbá àti ìṣerere orílẹ̀-èdè  D.R.Y, àwa ni ẹrù náà wà ní orí rẹ̀! Ìdí nìyí tí Màmá fi sọ, nígbàtí wọ́n ní kí á yọ àwọn ọmọ wa kúrò ní Ilé-Ìwé níbití ètò-amúnisìn tí wọ́n npè ní Nàìjíríà ti ń jẹ gàba, wọ́n ní àwa I.Y.P ni àwọn nbá sọ̀rọ̀ o! Èyíinì, òbí tí ó jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀, I.Y.P ni – bábá rẹ̀, I.Y.P, ìyá rẹ̀ pàápàá, I.Y.P. Ìwọ òbí bẹ́ẹ̀, I.Y.P ni o jẹ́ – lọ yọ àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò ní ilé-ìwé báyìí.

O ní àyè, tí ó bá wù ẹ́, láti ṣe àìgbọràn sí ìkéde yí; ohun tí ó kàn túmọ̀ sí ni pé, nígbàtí àwọn ìṣàkóso adelé wa bá wọ inú Sẹkitéríátì, tí a wá bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ tí ó wà nínú Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún wa, o máa san owo-ilé-ìwé fún ọmọ yẹn, owó náà á sì ju ti àwọn àjòjì lọ.

Ṣùgbọ́n ìwọ òbí tí ó jẹ́ pé, apá kan (bàbá tàbí ìyá) ni ó jẹ́ I.Y.P, tí òbí kéjì jẹ́ àjòjì, irú ẹni bẹ́ẹ̀, ni gbólóhùn “D.R.Y” tọ́ka sí (èyíinì, “D.R.Y” tí kìí ṣe “I.Y.P” torí pé ìkan nínú àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ àjòjì!) A lérò pé ó yé wa? Tí tọ̀tún-tòsì àwọn òbí bá jẹ́ I.Y.P, I.Y.P ni o jẹ́.

Lọ yọ ọmọ rẹ kúrò ní ilé-ìwé tàbí kí o ṣetán láti máa san owó ilé-ìwé ọmọ náà fún orílẹ̀-èdè D.R.Y nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ náà bá ń lọ ìlé-ìwé lọ́fẹ̀ẹ́. 

Fún àwọn  tó jẹ́ pé àjòjì ni ìkan nínú àwọn òbí wọn, tí èkejì jẹ́ I.Y.P, owó ilé-ìwé tí ẹ máa san kò pọ̀ tó èyí tí àwọ̀n àjòjì máa san ní orílẹ̀-èdè D.R.Y. Ìdí tí o fi ní ànfààní yí ni pé ìkan nínú àwọn òbí rẹ jẹ́ I.Y.P. 

Nítorí náà, tí a bá sọ pé, ẹni báyi-báyi, I.Y.P ni, (tàbí tí a pèé lápèjá, tí a sọ pé ‘I.Y.P ti D.R.Y’ ni), ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé, tọ̀tún-tòsì àwọn òbí rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ I.Y.P.

Ṣùgbọ́n ẹni tí a bá sọ pé, ‘D.R.Y’ ni (tí pípè tí a pèé kò lọ́wọ́ I.Y.P nínú, ṣùgbọ́n tí a kàn pèé ní “D.R.Y”), ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé apá kan àwọn òbí rẹ̀, àjòjì ni; apá kan ṣoṣo, péré, ni I.Y.P.

A lérò pé, ó yé wa? Ọkùnrin yẹn, I.Y.P ni, enikèjì yẹn, D.R.Y ni, kí àwọn gbólóhùn wọ̀nyẹn ó bẹ̀rẹ̀ sí yé wa dáadáa.

Nítorí náà, ìwọ tí ó jẹ́ pé ìkan nínú àwọn òbí rẹ, àjòjì ni, tí ó jẹ́ pé òbí rẹ kan péré ni I.Y.P, ànfààní wà fún ẹ. Màmá sọ pé owó ilé-ìwé kò níí pọ̀ tí ẹ máa san, kìí ṣe owó tí ó máa mú ìnira dání. 

Ìrú ẹni, tí ó jẹ́ ‘D.R.Y’ ṣùgbọ́n tí kìí ṣe “I.Y.P,” Màmá ní ẹ̀yin kọ́ ni wọ́n sọ fún láti yọ ọmọ yín kúrò ní ilé-ìwé báyi, ṣùgbọ́n ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀, tí ẹ bá fẹ́ lo ànfààní apá kan yín tí ó jẹ́ I.Y.P. 

Tí o bá fúnra rẹ pinnu láti bu ọ̀wọ̀ fún apá kan ẹ tí ó jẹ́ Yorùbá, tí o tìtorí bẹ́ẹ̀ yọ ọmọ rẹ kúrò ní ilé-ìwé báyi, Màmá wa sọ pé o máa ní ẹ̀dínwó nínú owó tí o máa san nígbàtí a bá bẹ̀rẹ̀ ètò-ẹ̀kọ́ ní àwọn ilé-ìwé wa, tí ẹ̀dínwó bẹ́ẹ̀ sì máa wà fún ọmọ tí o yọ kúrò ní ilé-ìwé, ẹ̀dínwó máa wà títí tí ọmọ yẹn á fi ka’wé tan, títí dé àkọ́gboyè kíní ní fásitì pàápàá.

Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí a gbọ́ran sí ìkìlọ̀ yí, kí gbogbo wa lè jẹ àǹfààní lọ́kan-ò-jọ̀kan tó ti wà nílẹ̀ fún wa ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal