Ní ẹgbàá ọdún ó lé méje, lábẹ́ Àkóso Gbenga Daniel, gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, nígbà náà tí a ṣì wà nínú Nàìjíríà, ni a gbọ́ pé àdéhùn kan wáyé, láarín ìpínlẹ̀ Ògùn àti ilé-iṣẹ́ Sháínà kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Zhongshan, pé kí ilé-iṣẹ́ yí ó kọ́ gbàgede Ìṣòwò àìlówó-orí (Free Trade Zone), èyí tí kárà-kátà yíò ti máà ṣẹlẹ̀ láìsí owó ìgbẹ́rù-wọlé gọbọi láarín ìlú òkèèrè àti Nàìjíríà nígbà náà.
Ṣùgbọ́n, a gbọ́ pé Ìpínlẹ̀ Ògùn kò fi tó ìjọba Nàìjíríà nígbànáà, létí pé òun ní àdéhùn iṣẹ́-ṣíṣe kan pẹ́lú ilé-iṣẹ́ kan lókè òkun, tí ó dẹ̀ yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́bí a ṣe gbọ́.
Nígbàtí ó wá di ẹgbàá ọdún ó lé márun-dín-lógún, lábẹ́ àkóso Ìbíkúnlé Amósùn, Ìpínlẹ̀ Ògùn wá fagilé àdéhùn wọn pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Sháínà ọ̀ún, látàrí pé lẹ́hìn ọdún mẹ́jọ, kòì tíì sí nkan tí wọ́n ṣe yàtọ̀ sí pé wọ́n mọ odi yí ibi gbàgede Ìṣòwò àìlówó-orí náà, èyí tí ilé-iṣẹ́ Sháínà ọ̀ùn sọ pé kò sí òótọ́ níbẹ̀.
Àsẹ̀hìn wá, àsẹ̀hìnbọ̀, ilé-iṣẹ́ Sháínà gbé Nàìjíríà lọ sí ilé ẹjọ́ ní ẹgbàá ọdún ó lé mọ́kanlélógún, nígbàtí Dàpọ̀ Abíọ́dún ti wa lórí àléfà ní ìpínlẹ̀ Ògùn; ilé-ẹjọ́ ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì náà sì ní kí wọ́n san owó tí kò dín ní ọgọ́ta mílíọ̀nù dọ́là fún ilé-iṣẹ́ Sháínà ọ̀ún, ṣùgbọ́n a gbọ́ pé Ìpínlẹ̀ Ògùn kọ̀ láti san owó náà.
Ìdí tí ọ̀rọ̀ fi kan Nàìjíríà ni pé, ní irúfẹ́ ìjọba tí Nàìjíríà ní, ìpínlẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti fò fẹ̀rẹ̀ kí wọ́n máa dá nkan ṣe ní àgbáyé, láìsí pé ìjọba-àpapọ̀ Nàìjíríà ló nṣeé. Nítorí èyí ni ilé-iṣẹ́ Sháínà ọ̀ún ṣe pe Nàìjíríà lẹ́jọ́.
Ìgbà tó yá ni Ilé-Ẹjọ́ ní òkè-òkun sọ pé ibikíbi tí ilé-iṣẹ́ Sháínà náà bá ti rí dúkìá Nàìjíríà, kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ le.
Ní àìpẹ́ yí ni ẹjọ́ tún dé ilẹ̀ Faransé, tí ilé-ẹjọ́ wá gba ilé-iṣẹ́ Sháínà ọ̀ún láyè nìyẹn, kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ọkọ̀ bàlúù mẹ́ta tí ó jẹ́ ti ààrẹ ìlú Nàìjíríà.
A gbọ́ pé nṣe ni àwọn bálúù yí lọ sí orílẹ̀-èdè Faransé láti lọ ṣe àyẹ̀wò-ọkọ̀ nígbàti ilé-iṣẹ́ Sháínà náà gbẹ́sẹ̀ lé wọn.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti wá fi ìkan sílẹ̀ nínú àwọn ọkọ̀ náà báyi, wọ́n ṣì gbẹ́sẹ̀ lé méjì.
Èyí tí ìròhìn yí ṣe jẹ́ pàtàkì fún wa ni pé, Ìpínlẹ̀ wa, Ìpílẹ̀ Ògùn ní Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba, ni ọ̀rọ̀ yí rọ̀ mọ́.
Kíni òkodoro ọ̀rọ̀ gan-gan-gan? Ọmọ Yorùbá, Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa mọ ohun tí orílẹ̀-èdè wa máa ṣe.
Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ti sọ fún wa tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo irúfẹ́ nkan wọ̀nyí ni D.R.Y máa wò fínní-fínní, láti mọ kíni ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè wa máa gbé.