Ohun míràn á sì ṣẹlẹ̀, ní wẹ́rẹ́, á wá ṣeni ní Hàà, nígbàtí a bá wo’lẹ̀, tí a wẹnu ọkọ́!
Ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù ògún, lọ́dọọdún, ni Àyájọ́ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́, tí a máa nránti ipò tí Àwọn Ọ̀dọ́ wà, káàkiri àgbáyé, àti kíni ó yẹ kí àwùjọ ó ṣe, láti gbé ipò, ìjẹ́-ọmọ-ènìyàn, àti iyì àwọn Ọ̀dọ́ sí ipele tí ó yẹ kí ó wà.
Ṣé èyí ti ẹ̀ kọ́ ni a nrò, nígbàti Màmá wa, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ngbé gbogbo Ìgbésẹ̀, nígbà náà lọ́hun, pé kí Ìjọba-Adelé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá wa yí, kí ó wọlé sórí àlééfà, ní ilẹ̀ wa; Màmá sì sọ, nígbà náà, pé, ọ̀tọ̀ ni ọjọ́ tí àwọn tí ẹ̀ nrò, àfi ìgbà tí Èdùmàrè fún’Ra rẹ̀ tọ́ka sí Ọjọ́ Kéjìlá, oṣù Igbe, ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí, ẹgbàá ọdún, ó lé mẹ́rin-lé-lógún, tí Màmá sì gbé ìgbésẹ̀ náà, èyí tí ó mi ayé tìtì, pé Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni wa, tí a sì gbé Ìjọba-Adelé wa wọlé, Ọ̀dọ̀ rèé lórí àléfà, tí a rí Ogo, Ẹwà, Iyì, Agbára, Ọ̀wọ̀, àti Ọ̀rọ̀ Akíkanjú, lẹ́nu Ọ̀dọ́, Olóri Ìjọba Adelé wa! Ni ó bá di Àmúṣẹ Ọ̀rọ̀ tí Màmá ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀dọ́ ló máa ṣé!
A sì tẹ̀ síwájú, láti ìgbà náà, bí àwọn Ìjọba Adelé wa ṣe nbá Iṣẹ́ náà lọ, àti Màmá tí wọ́n tún tẹ̀síwájú láti ri pé, pẹ̀lú àṣẹ Èdùmarè, kí iṣẹ́ Ìjọba wa yí, àti ti ọjọ́ iwájú, kí ó ṣe gbogbo ànfààní fún Ìran Yorùbá.
Ìwọ̀nyí ni a mbá lọ, tí a ò mọ̀ pé Olódùmarè, Ọba tí ó ní Ohun Gbogbo ní Ìkáwọ́ Rẹ̀, tí ṣe ìṣirò tiRẹ̀ sílẹ̀! Àwa kàn sọ pé kí á ṣe Àjọ̀dún Àyájọ́ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ káàkiri Àgbáyé; àfi ìgbà tí á wòye, pé, ẹ wá ná, ọjọ́ kéjìlá oṣù ògún mà ni àyájọ́ ọjọ́ ọ̀dọ́-ọ̀! Hà! Ó mà pé oṣù mẹ́rin GÉÉRÉ gé, tí Ọ̀dọ́ gun orí Àléfà Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá à!?
À ṣé, Ẹlẹ́da ti tòó sílẹ̀, pé, ní ọjọ́ gan-an gan tí Ìjọba Yorùbá, Ìjọba Ọ̀dọ́, pé oṣù mẹ́rin géérégé, tí wọ́n dé orí aléfà, ní oṣù kẹ́rin, oṣù igbe, oṣù kẹ́rin lẹ́hìn rẹ̀, géérégé, tí Ìjọba Ọ̀dọ́ ti bẹ̀rẹ̀, ní Ilẹ̀ Yorùbá, ijọ́ ọ̀ún, géérégé, ni Àjájọ́ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́.
A ò ka èyí sí ọ̀rọ̀ kékeré, rárá; Àmì ni ó jẹ́, kí gbogbo ọ̀dọ̀ I.Y.P ti Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y, ó gbéra fún Ìdàgbàsókè Orílẹ̀-Èdè wa, kí wọ́n mọ̀ pé, gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa nsọ, Olódùmarè ni Ó nrin ìrìn-àjò ìran Yorùbá, tí àwa ntẹ̀le!
Àyípadà rere ti dé fún Àwọn Ọ̀dọ́, ẹni ti Màmá ti máa nsọ pé àwọn ló máa ṣé; kí gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, lápapọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí yin Olódùmarè fún àyípadà sí Rere, èyí tí àmì rẹ̀ nhàn yí, pé, nípasẹ̀ àwọn Ọ̀dọ́ ni Ọlọ́run ti yàn, pé Orí-Ire gbogbo Ìran Yorùbá, yíò farahàn!
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, ẹ dìdé fún Ìdàgbàsókè Ìran Yorùbá. Gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ máa yin Èdùmàrè lógo, títí láí, pé Ó ti mú àyípadà rere bá Orílẹ̀-Èdè wa.
Ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe – ìjọba Yorùbá, ìjọba Ọ̀dọ́, gun orí Àléfa.
Ọjọ́ kéjìlá, oṣù ògún – Àyájọ́ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́!