Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, máa nsọ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan – wọ́n máa nsọ pé ìpìlẹ̀ kẹ́ta, fún Ìran Yorùbá, ni iṣẹ́ tí a nṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ yí, àti pé, ìpìlẹ̀ eléyi, kò gbọdọ̀ wó láíláí nítorí ìrìn-àjò ẹ̀mí ni Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y).
Nítorí náà, kí a jẹ́ kí ìrìn-àjò náà kí ó yé wa dáadáa. Ẹlẹ́da-Ìran-Yorùbá ni Aṣáájú-wa, Ìpilẹ̀ṣẹ̀-wa àti Aláṣepé wa; Ó sì ti fún wa ní Àlàkalẹ̀ tí a máa máa tẹ̀lé, títí Ayérayé, nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, Ìránṣẹ́ Rẹ̀ sí àwa Ìran Yorùbá.
Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá nípasẹ̀ Màmá wa, MOA, Àlàkalẹ̀ náà ni A fi bá Olódùmarè dá Májẹ̀mú pé, títí Ayé, Àlàkalẹ̀ yí ni A máa máa tẹ̀lé, láì yà sí Ọ̀tún tàbí Òsì, bẹ́ẹ̀ ni a ò níí yọ kúrò nínú rẹ̀, a ò sì níí fi ohunkóhun kun! Èyí ni Májẹ̀mú tí a bá Olódùmarè dá, gẹ́gẹ́bí Ìran Yorùbá.
Nítorí èyí, ìrìn-àjò Ẹ̀mí ni.
Gẹ́gẹ́bí Ìrìn-Àjò Ẹ̀mí, tí Ìran Yorùbá sì jẹ́ Ìran Ẹ̀mí, a níláti máa fi iyè sí gbogbo Ohun tí Olódùmarè bá nbá wa sọ, pàápàá tí Ó ti bá wa sọ Nínú Àlàkalẹ̀ tí Ó gbé fún wa, èyí ti a kò gbọ́dọ̀ yà kúrò nínú rẹ̀!
Ànfààní Nlá-Nlà ni eléyi jẹ́, pé Ìran Yorùbá rí Ojú-Rere Olódùmarè; Ó pè wá, láti bá Òun rìn, Ó sì fún wa ní Ìránṣẹ́ Rẹ̀, nípa ẹni tí ó ṣe Iṣẹ́ Ìgbàlà àti Òmìnira yí fún wa, Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.
Màmá wá ti nfi yé wa, láti ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn báyi, pé Ìpìlẹ̀ Ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ta tí Olódùmarè nyọ̀nda fún Ìran Yorùbá ni èyí! Àti pé kí a máṣe jẹ́ kí ìpìlẹ̀ eléyí kí ó ṣubú!
Kíni ìpìlẹ̀ ti àkọ́kọ́? Màmá fi yé wa pé Ìpìlẹ̀ Àkọ́kọ́ ni èyí tí a ti ní láti ayébáyé, láti ìṣẹ̀dálẹ̀ wá, èyí tí ó jẹ́ pé, àwọn òyìnbó-amúnisìn, pàápàá, jẹ́’rí si pé ó ga ju ohunkóhun tí àwọn rí rí lọ; wọ́n jẹ́’rí pé Inú-Ọrọ̀, Inú-Ògo, Inú-Ìrọ̀rùn ni àwọn bá àwọn babanlá-bàbá wa, tí kò tilẹ̀ sí òtòṣì tàbí olè ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, èyí tí a mọ̀ pé Yorùbá sì jẹ́ Gbòógì; wọ́n ní a jẹ́ ẹni-iyì, ọmọlúàbí, ológo; àti pé a jẹ́ ẹni-Ẹ̀mí, a sì ní Àṣa àti Àdáyébá-Ìgbé-Ayé t’ó fún wa ní Àgbára t’ó ju ti èyí tí amúnisìn léè borí rẹ̀! Ìdí ni’yí tí àwọn amúnisìn náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pète-pèrò, bí àwọn ṣe máa mú ìgbé-ayé-ológo wa balẹ̀! Wọ́n mà ri ṣe-è!! Áà! Bí ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ ṣe wó nìyẹn, tí a wá di ẹdun-arinlẹ̀, ẹni à nkó-lẹ́rú, lábẹ́ òyìnbó tí kò tó wa! tí a wá nsìn wọ́n! Bí àwọn ọba wa ṣe nta Ìràn ọmọ-Yorùbá sí oko-ẹrú ní òkèèrè nígbà náà nìyẹn, èyí tí ó fi jẹ́ pé, lóni, ni a rí ìran Yorùbá káàkiri àgbáyé; ẹlòmíràn kò tilẹ̀ mọ̀ pé Yorùbá ni òun, ó ṣáà mọ̀ pé aláwọ̀-dúdú ni òun àti pé láti ilẹ̀ Áfríkà ni wọ́n ti kó àwọn baba-nlá baba òun ní Ẹrú, tí kò sì mọ ọ̀nà ilé mọ́! Ẹlòmíràn tí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìwádi imọ̀-ìjìnlẹ̀, ìṣẹ̀dá omi-àti-ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ fihàn pé ìran Yorùbá ní ilẹ̀ Áfríkà ni àwọn babanlá rẹ̀ ti wá, gẹ́gẹ́bí ẹrú, sí ilẹ̀ tí òun wà nísiìyí, ṣùgbọ́n kò wá lè sọ pàtó, ibi gan-an, ìdílé Yorùbá wo, gan-an ni òun ti wá, k’a má tilẹ̀ wá sọ pé ìlú tàbí ìletò wo ni nínú ìdílé náà.
Yàtọ̀ sí àwọn tí àwọn ọba nígbà-náà tà sí oko-ẹrú, àwọn tó kù ní ilẹ̀ wa, àwọn òyìnbó-amúnisìn wọ̀nyí tún jẹgàba lé wa lórí, wọ́n fi wá sábẹ́, lórí ilẹ̀ wa, wọ́n nṣe ìjọba-òyìnbó lé’wa lórí, títí tó fi jẹ́ pé, nṣe ni kò tilẹ̀ wá sí nkankan tó farajọ bí a ṣe jẹ́ tẹ́lẹ̀, kí òyìnbó-amúnisìn ó tó kó’wa lẹ́rú!
Ìpìlẹ̀-Àkọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó wó pa’lẹ̀, Yorùbá di ẹrú, a sì pàdánù ògo tí a ti ní tẹ́lẹ̀ kí òyìnbó ó tó dé. Kò sì sí ohun tó fàá náà ju pé, àwa fún’ra wa, l’a gbàbọ̀dè fún ara wa, nígbàtí àwọn ọba tí ó yẹ kí wọ́n dáàbò bò wá, tí ó jẹ́ pé àwọn gan-an ni wọ́n tún ta ìran Yorùbá, s’oko ẹrú. Bí wọ́n ṣe tà’wa s’oko-ẹrú ní òkèèrè, náà ni wọ́n gba àbọ̀dè kí ìràn-Yorùbá tó kù sí orí-ilẹ̀ Yorùbá, ó bọ́ sí ìgbèkùn lábẹ́ amúnisìn, lórí ilẹ̀ wa!
Ìpìlẹ̀ kéjì ni ó wá’yé nígbàtí Ọlọ́run nínú àánú Rẹ̀, tí ó tún fún wa ní Ànfààní, lábẹ́ ìmùnisìn-òyìnbó, pé kí wọ́n gba àwa Yorùbá láàyè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn amúnisìn kò ì tíì lọ pátápátá, ṣùgbọ́n a ní ànfààní láti ṣe ìjọba tiwa, nígbà-náà l’ọhún, èyí tí bàbá wa, Awólọ́wọ̀, fi jẹ́ Olóri-Ìjọba ilẹ̀ Yorùbá, èyí tí ó wáyé kó tó di pé wọ́n sọ pé àwọn fún àpàpọ̀ ibi tí wọ́n pè ní Nàìjíríà ní Òmìnira.
Gudugudu méje, yàà-yàà mẹ́fà ni ilẹ̀ Yorùbá ṣe nígbà náà, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ilẹ̀ Òyínbó bíi Faransé kò tilẹ̀ tíì ní àwọn nkan amáyédẹrùn kan, nígbàtí ilẹ̀ Yorùbá ti ni. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nkan ni ó jẹ́ pé lábẹ́ àkóso ìjọba Bàbá wa Awólọ́wọ̀ ni ó jẹ́ pé ilẹ̀ Yorùbá ni ó kọ́kọ́ ṣe irúfẹ́ ohun bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀. Ohun gbogbo nlọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ, àfi ìgbà tí wọ́n tún ní kí Nàìjíríà lápapọ̀ ó ní ìjọba àṣejọpọ̀ ní òkè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́kùnjẹkùn yíò ṣì máa ṣe ìjọba tiwọn lọ bákan-náà. Àbámọ̀ kí á sọ pé a ò ṣe! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bàbá wa Awólọ́wọ̀ gbìyànjú ní àkókò náà, wọ́n ní kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ pé, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ẹlẹ́kùnjẹkùn tí ó fẹ́ darapọ̀ máa jẹ́ Nàìjíríà, tí ó bá dé’bi tí ọ̀rọ̀ kò wọ̀ mọ́, le ní ànfààní láti jáde kúrò nínú àjọṣepọ̀ ọ̀ún, àmọ́, àwọn tó kù kò gbà! Àbámọ̀ kí á ti sọ pé tí wọn ò bá gbà, a ò ní darapọ̀ pẹ̀lú wọn! Ṣùgbọ́n nṣe ni a mà darapọ̀ pẹ̀lú wọn-ọn! Láti ìgbà náà ni oríṣiríṣi tí bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ ní Ilẹ̀ Yorùbá! Ọ̀tọ̀ ni àwọn ọmọ-Yorùbá kan tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbàbọ̀dè fún Ìran Yorùbá, nípa pípa’dí-àpò pọ̀ mọ́ àwọn Fulani lábẹ́ ìjọba-àpapọ̀ èyí tí Tafawa Balewa àti baba-ìsàlẹ̀ rẹ̀, Ahmadu Bello, ti nṣe àkóso, àwọn ọmọ Yorùbá ọ̀ún pa’dí-àpò pọ̀ mọ́ àwọn Fulani yí láti da iṣẹ́ rere tó nlọ ní Ilẹ̀ Yorùbá rú, títí tí ó fi di pé wọ́n sọ bàbá wa Awólọ́wọ̀ sínú ẹ̀wọn látàrí ẹ̀sùn tí ó sọ pé òun ó mọ ọwọ́ mọ ẹsẹ̀ rẹ̀: tí kò sì sí ohun kan-kan títí di òní-olóni yí tí ó fi ẹsẹ̀ ẹ̀sùn náà mu’lẹ̀, yàtọ̀ sí àfojúsùn pé wọ́n ṣáà fẹ́ da ojú ìran Yorùbá bo’lẹ̀! Bí ìpìlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì ṣe dàwó nìyẹn! Láarín ẹ̀ ni wọ́n tan àwọn ìran wa tó wà ní apá Bìní, pé, àwọn fẹ́ wà lọ́tọ̀: ẹ̀yìn èléyi ni àwọn ológun nàìjíríà kúkú gbà’jọba, tí a sì mọ̀ pé ó lọ́wọ́ Gẹ̀ẹ́sì nínú; ọmọ Íbò, ológun, tí ó bọ́ sórí àlééfà, kúkú wa fagilé ìjọba ẹlẹ́kùn-jẹ-kùn, tí ó wá túmọ̀ sí pé Yorùbá ṣubú pátápátá, a ò ní agbára lórí ohun ìní wa mọ́!
Kẹ̀rẹ̀-kẹ̀rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pín wa yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ, ó wá dí pé oníkálùkù káàkiri ilẹ̀ Yorùbá nmójú-tó agbègbè wọn, Yorùbá ò jẹ́ ẹyọkan mọ́! Bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré, gbogbo agbára wà lọ́wọ́ ìjọba-àpapọ̀ Nàìjíríà, nítorí èyí, kò sí ìkan-kan nínú gbogbo yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ tí wọ́n pín Yorùbá sí, tí ó rọ́wọ́ mú; wọ́n kàn gbé orúkọ lérí ni!
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tú bábá wa Awólọ́wọ̀ kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n ti bábá ṣe ọṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe ní ilẹ̀ Yorùba – ìyẹn àwọn Fulani àti àwọn amúnisìn; títú bàbá wa Awólọ́wọ̀ kúrò nínú túbú kò gbé ògo Yorùbá padà! Àwọn ọ̀tá ti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Ràbọ̀-ràbọ̀ rẹ̀ ni Ilẹ̀ Yorùbá wà títí wọ́n tún fi pa bàbá wa, MKO Abíọ́lá.
Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́da wa, Olódùmarè, Ọlọ́run Ìran ọmọ-Yorùbá, tó sọ pé, ní déédé ìgbà yí àti ní déédé àsìkò yí, kí Ìyá wa, Olùgbalà Ìran-Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, kí wọ́n dìde! Wọ́n sì dìde ní òtítọ́, láti jẹ́ iṣẹ́ tí Olódùmarè fi rán wọn: ní ogúnjọ́, oṣù Bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, ìgbésẹ̀ gbòógì yí ṣẹlẹ̀, pé ìràn-ọmọ-Yorùbá, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè Olómìnira, jáde kúrò lára ìlú amúnisìn, Nàìjíríà! Bẹ́ẹ̀ náà ni, ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, a gba ìṣèjọba-ara-ẹni wa padà, gẹ́gẹ́bí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), a sì ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí-Ìjọba-Adelé wa, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni a ti tún bá Olódùmarè dá májẹ̀mú, báyi, pé Àlàkalẹ̀ tí wọ́n gbé fún Ìran Yorùbá, nípasẹ̀ Màmá wa, MOA, ni a ó máa tẹ̀lé, láí-láí, láì yà sí ọ̀tún tàbí òsì.
Ìpìlẹ̀ KẸ́TA tí Olódùmarè fún wa ní Ànfààní rẹ̀ ni’yí! Màmá wa sì ti sọ fún wa pé, A Ò gbọ́dọ̀ fi àyè kan-kan sílẹ̀ fún ìpìlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ta yí, kí ó wó!