Ènìyàn kò lè ṣiṣẹ́ ní ìlú Gẹ̀ẹ́sì mọ́ láti di olówó. Ọrọ̀ kò sì ṣeé kójọ mọ́ ní Orílè-èdè náà. Ọkùnrin kan ló sọ ọ̀rọ̀ yí lórí Ayélujára X.
Ó ní, iṣẹ́ tí àwọn ń ṣe, àwọn kàn fi ń san owó àwọn ohun kòṣeémáni àti amáyédẹrùn ní, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kàn ń ṣe bí ẹni pé gbogbo ǹkan sì ń lọ déédéé. Èyí ni ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu ọkùnrin náà nínú fọ́nrán ọ̀hún tó sì ń fi àìdùnnú rẹ̀ hàn.
Èyí tún wá jẹ́ àsìkò láti rán ara wa létí pé, Indigenous Yorùbá People (I.Y.P.) tí a bá wà ní òkè òkun, a pè yín pé kí ẹ máa padà bọ̀ wá sí ilẹ̀ bàbá yín, Orílè-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti dúró. Ọlọ́run ti lo Màmá wa, Olóyè Ìyáàfin Modúpẹ́ọ̀lá Onítìrí-Abíọ́lá,
láti gbà wà kúrò nínú oko-ẹrú láti ogúnjọ oṣù Belú ẹgbàá ọdún ó-lé-méjìlélógún, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni pẹ̀lú ìbúra-wọlé fún olórí Ìjọba-Adelé wa bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe, ẹgbàá ọdún ó-lé-mẹ́rinlélógún.
Àwa ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa tí Yorùbá ti jáde kúrò lára agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, kí àwọn ọ̀dọ́ wa le bẹ̀rẹ̀ sí máa lo ògo wọn fún ìgbélékè ogo Ọlọ́run ní Orílè-èdè Democratic Republic of the Yorùbá, (D.R.Y)
Ọlọ́run wá gbé Àlàkalẹ̀ tí ó dára lé màmá wa, MOA lọ́wọ́ kí a lè máa jẹ’gbádùn lọ loríṣiríṣi. Iṣẹ́ sì ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Adelé Ìpínlẹ̀ méjèèje ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Kí Olódùmarè bá wa ti àwọn ajẹgàba tí wọ́n dúró sí àwọn oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa, kí àwọn adarí wa lè tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti là kalẹ̀ láì fi àkókò ṣ’òfò.