ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ.

Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ pé ìlú Amẹ́ríkà sọ pé ó tẹ́ òun lọ́rùn kí orílẹ̀-èdè Áfríkà méjì jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́-múléjóko nínú Ìgbìmọ̀ Aláàbò Àjọ Àgbáyé, yàtọ̀ sí bí ó ṣe jẹ́ tẹ́lẹ̀ tí orílẹ̀-èdè aláwọ̀dúdú kankan ò sì nínú ìgbìmọ̀ múléjòkónáà.

Ṣùgbọ́n, ọkùnrin aláwọ̀dúdú ọmọ Áfríkà tí ó gbé ìròyìn náà sí’nú fọ́nrán tí a rí sọ pé, ẹ̀tàn ni!

Ó ní nṣe ni àwọn aláwọ̀ funfun wọ̀nyí fẹ́ kí aláwọ̀ dúdú máa rò pé àṣeyọrí pàtàkì ni àga mùlèjóòkó nínú ìgbìmọ̀ náà.

Aláwọ̀ dúdú ò nílò ìpò tàbí àga nínú Ìgbìmọ̀ Aláàbò Àjọ Àgbáyé; dípò bẹ́ẹ̀, òmìnira pátápátá kúrò lábẹ́ ìmúnisìn òyìnbó ni ó jẹ aláwọ̀-dúdú lógún!

Ní pàtó, ó wá sọ pé nṣe ni kí aláwọ̀dúdú ó kọ̀ jálẹ̀ láti ní àjọṣe pẹ̀lú ilé-ìfowó-pamọ́ Àgbáyé àti Àjọ Ayánilówó Àgbáyé, nítorí àwọn ilé iṣẹ́ wọ̀nyí ni ó ń ṣe ìrànwọ́ àti fi Áfríkà sínú ìgbèkùn síwájú si.

Ó wá sọ pé àwọn aláwọ̀dúdú Amẹ́ríkà pàápàá, kí aláwọ̀dúdú Áfríkà ó ṣọ́ra fún wọn, to rí wọ́n ti pàdánù ìdánimọ̀ wọn: àwọn ni òyìnbó sì nlò láti fa ojú Áfríkà mọ́’ra: nípa bẹ́ẹ̀, Áfríkà á kó sí’nú pàkúté òyìnbó amúnisìn, nígbàtí wọ́n bá ti ti aláwọ̀-dúdú ti Amẹ́ríkà síwájú láti lọ sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn aláwọ̀-funfun fún aláwọ̀-dúdú Áfríkà:èyí túmọ̀ sí pé, aláwọ̀-funfun amúnisìn ní Amẹ́ríkà fi aláwọ̀-dúdú Amẹ́ríkà dẹ pàkúté láti mú aláwọ̀-dúdú Áfríkà nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí aláwọ̀-funfun fi rán wọn sí aláwọ̀-dúdú Áfríkà. Èyí yọrí sí ìkónil’ẹrú sí aláwọ́-dúdú ti Áfríkà!

Democratic Republic of the Yorùbá daily news updates

Fún àpẹrẹ, obìnrin tí a rí nínú fọ́nrán náà, tí ó gbé ọ̀rọ̀ náà jáde gẹ́gẹ́bí abẹnugan Ìlú Amẹ́ríkà, aláwọ̀dúdú Amẹ́ríkà ni!

Aláwọ̀dúdú ti Áfríkà lè wá rí ẹni yẹn, kí ó rò pé, ohunkóhun tí ó bá ti sọ ni òun máa tẹ̀lé torí pé ó jẹ́ aláwọ̀dúdú bíi ti òun!

Ìwọ̀nyí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó jẹyọ nínú àwọn nkan tí ọkùnrin aláwọ̀dúdú Áfríkà tí ó gbé fídíò náà sí’ta sọ!

Ní ti àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), a ti ní ìjọba D.R.Y a dẹ̀ mọ̀ pé wọ́n kún’ jú òṣùwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ tí Olódùmarè pè wọ́n sí: àwọn ni wọ́n máa sọ ipò tí D.R.Y máa dúró sí l’orí ọ̀rọ̀ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè míràn; ẹ má ṣe jẹ́ kí a kánjú: ohun kan tí a mọ̀ ni pé, Orílẹ̀-èdè Yorùbá kò tún ní ṣe ẹrú mọ́!