Ìròyìn kan gbé Ipinnu ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà jádè nípa ìgbésẹ wọn láti kọ́ ẹnu ibodè sí àwọn òpópónà márosẹ̀ ni ìlú wọn láti lè ma gba owó ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn tó nwakọ̀ kọjá níbẹ̀.
Bi kò bá ṣe pé wọ́n darukọ àwọn ìlú tó jẹ́ tí Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá – D.R.Y) mọ́ ara àwọn ìlú tí wọ́n nsọ, ọ̀rọ̀ náà kò bá má kan wa, nítorí bí ènìyàn bá ṣe fẹ́ ló nṣe l’ójúde ara rẹ̀, bí ó bá tí wùń wọ́n ní kí wọ́n ṣe ní ìlú agbésùmọ̀mí Nàìjíríà, kò kàn wá.
Kọ́kọ́rọ́ tó ba eyín ajá jẹ̀ ni pé wọn kò dúró nílùú tiwọn. A ò ran wọn ní iṣẹ́ lórí ọna wa, bí a tí ma ṣe ọ̀nà wa àti àwọn ètò ìdàgbàsókè míràn wà nínú àlàkalẹ̀ ìṣèjọba tó wà lọ́wọ́ màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, pàtàkì jùlọ ni pé ẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa.
Àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People – I.Y.P) nlo ànfàní yìí láti rán àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà àti àwọn ọmọ iṣẹ wọn létí pé Olódùmarè ti lo màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gba ilẹ̀ Yorùbá kúrò lára Naijiria, láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-méjìlélógún nígbàtí a kéde òmìnira wa.
A sì ti di orílẹ̀ édè olómìnira aṣèjọba ara ẹni ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ó-lé-mẹ́rìnlélógún nígbàtí a búra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, ìjọba wa sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ìgbesẹ̀ ìjẹgàba àti ìgbésùnmọ̀mí tí apanilẹ́kún jayé Naijiria ngbé lóri ilẹ̀ wa yìí lòdì sí òfin àgbáyé, ẹ ó sì fojú bá ilé ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn àgbáyé láì pẹ́.
Ikilọ̀ wa tún lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n pé ara wọn ní ọba tàbí ọ̀jọ̀gbọ̀n ati ẹnikẹ́ni tí ó le jẹ́ tó npe orílẹ̀ èdè Yorùbá mọ́ agbésùmọ̀mí Naijiria, kí wọ́n má tún kà wá mọ́ wọn mọ́, nítorí a kìí ṣe ará aríremáṣe Nàìjíríà mọ́.
Gbogbo ẹnití ó bá darapọ̀ pẹ̀lù agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà láti fí agídí jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, tàbí tí wọn ka orílẹ̀ èdè wa pọ̀ mọ́ ìlú agbèsùnmọ̀mí yẹn ní yíò f’ojú winá òfin àgbáyé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ní, gbogbo irú ẹni bẹ́ẹ̀ á dé ilé ẹ̀jọ́ ọ̀daràn àgbáyé fún ìjìyà tó tọ́.
Òjò ẹ̀sín wọn tí ṣu, o máa tó rọ̀ lé àwọn ọ̀tá wa lórí, wọn kò ní rí ibì kankan fara pamọ́ sí, nítorí, ọjọ́ ti súnmọ́ tan tí àwọn ìjọba Adelé wá máa gbàkóso gbogbo oríkò ile iṣẹ́ ìjọba wa káàkiri Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá -D.R.Y).