Èdè Yorùbá ni ó gba’jú gba’jà tí àwọn ènìyàn fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ní ìlú Èkó, bí èyí ṣe fi ara hàn wípé Èkó gba olè, ó gba ọ̀lẹ, nítorí, irú wá, ògìrì wá ni Èkó, Ìpínlẹ̀ tí àìmọye ènìyàn tí ń sọ oríṣirisi èdè, tí wọ́n wá láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XA rí ọ̀rọ̀ rádaràda yí gbọ́ láti ẹnu Gawat Jubril, tí ó jẹ́ agbẹnusọ àgbà nínú ìròyìn fún Babájídé Sanwóolú, gómìnà Nàìjíríà, tí ń jẹ gàba lórí Ìpínlẹ̀ Èkó lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorubá. Òun ló sọ ọ̀rọ̀ yìí lórí abẹ́yẹfò X rẹ̀ ní ọjọ́ kẹ̀sán oṣù keje ẹgbàá ọdún ó-lé-mérìn-lé-lógún.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní ìdánilẹ́kọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà dá lórí: bí gbogbo ará ìlú máa ṣe mọ̀ nípa àgbékalẹ̀ àwọn òfin àti ààbò, ìṣe iṣẹ́ kára kára, àtúnṣe bí àwọn òfin náà ṣe máa tètè di mímú lò àti àǹfààní láti máa ṣe àtúnṣe wọn ní òòrèkóòrè.
Gawat Jubril tún sọ síwájú síi pé yíyí àwọn òfin náà padà sí èdè Yorùbá dúró lórí ìgbìyànjú ìjọba agbésùnmọ̀mí ní Ìpínlẹ̀ Èkó, láti dá ààbò bò àti kí ó pa àṣà Yorùbá mọ́.
Ìjọba agbésùnmọ̀mí ní Èkó ṣ’àlàyé ọ̀rọ̀ náà nínú oṣù kẹfà, nígbà tí wọ́n mú ìkéde ìpalẹ̀mọ́ fún àjọyọ̀ ọ̀sẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ní ó máa wá’yé nínú oṣù kẹsàn-án, wá.
Gẹ́gẹ́ bí ìjọba Èkó ṣe gbé e jáde, àgbékalẹ̀ ètò àjọ̀dún náà ṣe àlàyé ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ lórí àwọn àṣà àjogúnbá Yorùbá, tí yó sì máa wà bẹ́ẹ̀ fún ìran tí ó ń bọ̀, atí bí ọ̀làjú ṣe ń sún síwájú síi.
O tún fi kún àlàyé rẹ̀ pé, àwọn orin ìbílẹ̀, ijó jíjó, ìpolongo àṣà, gbogbo ẹ̀ ló máa wá’yé ní’bi àjọ̀dún náà.
Olúbádá’mọ̀ràn lórí ìrìn àjò afẹ́, Idris Arẹ́gbẹ́ sọ wípé àkòrí ètò náà tí ó máa gba ọ̀sẹ̀ kan gbáko ni: Gbígbé àwọn nǹkan Àjogúnbá Yorùbá lárugẹ, Ìfọwọ́so’wọ́pọ̀ àti Àmúyangàn nípa pípa àwọn àṣà tí a jogún bá wọ̀nyí mọ́ èyí tí yó lè mú ọjọ́ ọ̀la wa dára.
Ẹ bá wa béèrè lọ́wọ́ Sanwoolu pé, ibo ni ó wà láti ọdún yìí wá, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ pé òun fẹ́ gbé àṣà Yorùbá lárugẹ, nígbà tí òkété tí wá bọ́’rù mọ́ọ lọ́wọ́ tán. Ohun tí gbogbo Indigenous Yorùbá People fẹ́ ni pé kí òun àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dì jọ fi Democratic Republic of the Yoruba wa àti àṣà rẹ̀ sílẹ̀ fún wa, kí wọ́n máa lọ sí one Nàìjíríà wọ́n ní apá òkè Ọya.