Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ìròhìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ́kànlá osù keje ọdún ẹgbàáólémẹ́rìnlélógún, ni ti ikú ọkùnrin a wa kẹ̀kẹ́ akérò ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta tí a mọ̀ sí márúwá tàbí napep, látàrí bí àwọn òsìsẹ́ ìjọba Nàjíríà tí wọ́n fi ipá jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yorùbá, tí wọ́n npè ní Lastma, ṣe gba kẹ̀kẹ́ tí ó nwà ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì jẹ́ pé gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí ó bẹ̀, pàbó ni ó jásí, ni okùnrin náà bá kúkú pa ara rẹ̀ nípa pípokùn so níwájú iléisẹ́ àwọn Lastma, tí  wọ́n nṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba tí ó njẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, èyíinì, ìjọba Nàíjírìà, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé wọ́n ṣì fi ipá dúró lórí ilẹ̀ wa.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ní ìlú Ìkòròdú, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, èyí tí Nàìjíríà ṣì njẹ gàba lé lórí, ni èyí ti ṣẹlẹ̀.

Ní kété tí a bá ti lé àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà wọ̀nyí kúrò lórí ilẹ̀ wa tán, irú èyí kò leè sẹlẹ̀ ní Orílẹ̀èdè Olómìnira Yorùbá mọ́, níbi tí ìgbáyé gbádùn gbogbo ìran Yorùbá ti  jẹ wá lógún nítorí kò ní sí  ìdúnkookò mọ́’ni, tàbí ìfìyàjẹni ní ọ̣̀nà àìṭọ́ bí irú eléyi, àti wípé àlááfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ni àwa ìran Yorùbá yí ó wà, látàrí isẹ́ ribiribí tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lạ́ ti ṣe ̣láti fún wa  ní ọjọ́ ọ̀la tí ó rẹwà, tí ó sì dá wa lójú pé tí ìjọba wa bá bẹ̀rẹ̀ isẹ́ ní pẹrẹu, tí àwọn adelé wa bá ti wà ní ilé-iṣẹ́ ìjọba ti sẹkitéríátì wa káàkiri, kò leè sí irú ìwà burúkú báyi tàbí òmíràn ní orílẹ̀èdè tiwa.