Olórí àwọn àgbàyà, Olúṣẹgun Àrẹ̀mú Ọbásanjọ́, tí fẹ’nu sí ọ̀rọ̀ èpo rọ̀bi, ó sì sọ ọ̀rọ̀ látàrí bí àwọn tí wọ́n ngbé epo wá sí ìlú wọn Nàìjíríà kò ṣe ní jẹ́ kí ilé-iṣẹ́ ìfọpo Dangote ó rọ́wọ́ mú! Ṣé ó kúkú ti pẹ́ tí a máa ngbọ́ pé Ọbásanjọ́ fún’ra rẹ̀ kàn fi Dangote bo’jú ni, àti pé òun gan-an ni ẹni tí ó wà ní’dí ilé-iṣẹ́ ìfọ’po Dangote.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

Gbogbo ẹkún tí Ọbásanjọ́ nsun yí, kò kan Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá rárá: àti Dangote àti àwọn alátìlẹ́hìn rẹ̀, bíi Ọbásanjọ́, tí wọn ò fara mọ́ òmìnira àti ìṣèjọba-ara-ẹni Orílẹ̀-Èdè D.R.Y, kí wọ́n yàgò lọ́nà fún wa.

Kíni ó kan Ọbásanjọ́ gbọ̀n-gbọ̀n-gbọ̀n nínú ọ̀rọ̀ ìfọ’po Dangote! Ṣé ẹ ri báyi pé Obásanjọ́ jẹ́ gbòógì nínú àwọn tó nta Yorùbá fún Fúlàní. Kàkà kó gbárùkù ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ọ̀rọ̀ ìfọpo Dangote ló nka lára – ṣé wọ́n kúkú ti sọ fún wa pé òun gan-gan ló wà lẹ́hìn ilé-iṣẹ́ ìfọpo Dangote.

Gbogbo Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ jọ́wọ́, ọ̀rọ̀ bí Ìjọba Adelé wa ṣe máa wọlé sí àwọn Oríkò-Ilé-Iṣẹ́ Ìjọba káàkiri Orílẹ̀-Èdè wa ni kí á gbá ojú mọ́ báyí, kí á tì wọ́n lẹ́hìn, kí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ó kúrò lórí ilẹ̀ wa pátápátá! Ọmọ Yorùbá, ẹ gbárùkù tí Ìjọba-Adelé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá!