Ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lórí ẹ̀kọ́ọ mọ̀ọ́ kọ, mọ̀ọ́ kà ni wípé tí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí àwọn aláwọ̀ funfun gbé wá fún wa kìí bá ṣe ẹ̀tàn ni, báwo ló ṣe jẹ́ pé, tí àwa aláwọ̀ dúdú bá kà’wé gb’oyè tán, à fi kí á máa fi ìwé ẹ̀rí náà wá ìṣẹ́ oníkọ́là káàkiri dípò kí a fi ọgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí a ti ní ṣe iṣẹ́ àdáni tí a le lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí a ti ní ní’bẹ̀, bí àwọn aláwọ̀ funfun ṣe máa ń ṣe fún àwọn ọmọ tíwọ́n, nítorí pé, láti kékeré ni wọ́n ti máa ń kọ́ wọn ní àtúpa’lẹ̀ àti àtúntò, èyí tí ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tètè di mí mọ̀ ní áti’nú à t’òde lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ gbogbo.

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

Ẹ̀kọ́ jẹ́ ìpìlẹ̀ rere fún gbogbo ènìyàn tí ó bá fẹ́ ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀, ẹni tí kò lọ sì ilé ìwé fún ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n tí ó lọ kọ ìṣẹ́ ọwọ, ẹ̀kọ́ náà ma ni, tí ó bá kọ iṣẹ́ náà tán, tí ó bá sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́ náà, ó máa ṣe rere ju ẹlòmíràn tí ó lọ kà’wé gb’oyè lọ.

The democratic republic of the yoruba is a new sovereign nation from april 12th 2024

Ṣùgbọ́n ohun tí ó léwu jù ni pé kí ènìyàn má le mọ̀ọ́ kọ, mọ̀ọ́ kà rárá. Ní Orílè-èdè Olominira Tiwantiwa Tí Yorùbá, oore ọ̀fẹ́ máa wà fún ẹ̀kọ́ àgbà gẹ́gẹ́ bí màmá wa, Modupeola Onitiri-Abiola ṣe máa ń sọ fún wa.

Ní pàtàkì jù lọ, ọgbọ́n èyí tí a rí kọ nínú fídíò tí a rí lóríi ayélujára yìí ni wípé, ki gbogbo ọdọ D.R.Y bẹ̀rẹ̀ sí í máa ṣe àtúnyẹwò.

 àwọn ìmọ̀ tí wọn ti ní, láti máa wo ọ̀nà wo ni wọ́n fi le ran ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ní lọ́wọ́, láti lè rí ògo wọn lò gẹ́gẹ́bí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiola ṣé máa ń sọ fún wa pé ògo wà lára gbogbo ọdọ D.R.Y, àti pé ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, gégébí àlákalẹ̀ ti ètò ìṣèjọba tí D.R.Y tí mama wa ti ṣe kalẹ̀ fún wa, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa máa rí ògo wọn lò ní agbára Olódùmarè ní kété tí àwọn Adelè wa bá ti wọ ilé iṣẹ́ ìjọba wa láì pẹ́ yìí.