Gbọ Audio Ìròyìn Òmìnira

Bí ‘ná ò bá tan l’áṣọ, ẹ̀jẹ̀ kìí tán léèkánná, èyí ló jẹ́ kí a máa fi tó wa létí nígbà gbogbo, àwọn ìgbésẹ̀ lọ́kan-ò-jọ̀kan tí ìránṣẹ́ ikú, Bill Gates ń gbé, pàápàá lórí àwa ìran Yorùbá, nítorínáà, ẹ jẹ́ kí a kíyèsára.

Ó pẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ búburú yìí, ṣùgbọ́n àwa ní a ò funra, a tilẹ̀ gbọ́ nínú fọ́nrán kan níbi tí ìránṣẹ́ ikú ọ̀hún fúnra rẹ̀ ti ń sọ wípé, láti ọdún mẹ́rìnlélógún sẹ́yìn ni ilé iṣẹ́ Bill Gates tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ibi yí káàkiri orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú, ó ní tí a bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú lápapọ̀, ìlú apanilẹ́kún jayé Nàìjíríà ni àwọn ti ṣe iṣẹ́ tó pọ̀jù, gbogbo ìgbésẹ̀ náà ló sì lọ dáadáa, iṣẹ́ náà sì tún ń tẹ̀síwájú, nítorí àwọn tún ti ṣètò abẹ́rẹ́ àjẹsára tuntun fún àìsàn ìgbẹ́ gbuuru àti àìsàn àìní ẹ̀jẹ̀ tó ní ara.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa, gbogbo àgbáyé náà ló mọ̀ yín ní apànìyàn, ẹ̀yin ni onígbọ̀wọ́ Bill Gates, ẹ fi àga ìṣèjọba Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) sílẹ̀, a kìí ṣe ara yín mọ́, a ti gba òmìnira wa láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún, a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wa, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, ẹ máa ro ẹjọ́ àwọn ìwà ibi àti ti ìjẹgàba tí ẹ ń ṣe lórí ilẹ̀ D.R.Y ní ilé ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn ti àgbáyé. 

Nítorí náà àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá D.R.Y, ẹ jẹ́ kí  a ṣọ́ra fún abẹ́rẹ́ àjẹsára tàbí oògùn òyìnbó, ẹ máa ṣe ìtọ́jú ara yín ní ìlànà ìbílẹ̀ Yorùbá, kí a sì f’ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa, Olódùmarè ti lo màmá wa, Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ìjọba apànìyàn yí, ìgbà díẹ̀ lókù, ìkan nínú wọn kì yíò lọ láìjìyà.