Nínú Ìkédé Òmìnira Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, èyí tí ó wáyé ní ogúnjọ́ oṣù Bélú, Ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, ọ̀kan nínú àwọn gbòógì gbólóhùn tí ó jáde si àgbáyé, nínú ìkéde náà, sọ báyi:
“Àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá ní ìgbàgbọ́ nínú ìbọ̀wọ̀-fa’ra-ẹni, àparò-kan-ò-ga-jùkanlọ, ní ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè.
Nítorí èyí, a níi lọ́kàn láti ní ìbáṣepọ̀ àtinúwá pẹ̀lú gbogbo orílẹ̀-èdè, àti àjọ káàkiri àgbáyé, tí wọ́n bá B’Ọ̀WỌ̀ fún Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Aṣèjọba-Ara-Ẹni Yorùbá, tí wọ́n sì ṣe ìdánimọ̀ fún wa pé a jẹ́ orílẹ̀-èdè olómìnira ní àyè ara wa.”
Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí Ìran Yorùbá; Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa ń sọ fún wa, ní ìgbà-dé-ìgbà pé, orílẹ̀-èdè tí ó bá fún wa ní ìdánimọ̀ tiwa, ni àwa náà máa ṣe ìdánimọ̀ fún: orílẹ̀-èdè tí ó bá bọ̀wọ̀ fún wa, ni àwa náà yóò bọ̀wọ̀ fún: orílẹ̀-èdè tó bá ní òun ò mọ̀ wá, àwa náà ò mọ̀ọ́, bí ó ṣe jẹ́ nìyẹn.
Èyí túmọ̀ sí pé, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kì ń ṣe ẹrú orílẹ̀ èdè kankan; bẹ́ẹ̀ ni a kìí ṣe abẹnugan tàbí ìránṣẹ́ orílẹ̀-èdè míràn, rárá o!
Màmá sì ti sọ fún wa bákannáà, pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá máa ṣe aṣojú D.R.Y ní orílẹ̀-èdè k’orílẹ̀-èdè, gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó mọ orílẹ̀-èdè yẹn dáradára: tí ó gbọ́ èdè wọn, tí ó mọ àṣà àti ìṣe wọn; tí ó mọ kọ́lọ́fín ìlú náà; nípa èyí tí wọn kò ní lè ṣe awúrúju kankan fun: ẹni tí yóò leè bójútó ànfààní ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) tí ó wà ní orílẹ̀-èdè náà, tí á sì jẹ́ aṣojú rere fún D.R.Y níbẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá ti sọ fún wa pé, gbogbo orílẹ̀-èdè ni D.R.Y ti fẹ́ mọ àwọn wo ni I.Y.P tí ọwọ́ òfin ilú náà mú sí ìhámọ́, àti nítorí kíni, nítorí pé D.R.Y máa ṣe gbogbo ohun tí ó bá máa gbà, láti ríi pé ìyà kò jẹ I.Y.P látàri aṣémáṣe orílẹ̀-èdè náà fún’ra rẹ̀.
Màmá sì ti sọ fún wa, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ti wà nínú ìkéde òmìnira wa ní’jọ́ náà, lọ́hùn-ún pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Aṣèjọba-Ara-Ẹni Yorùbá, yíò mọ odi tí ó lágbára káàkiri àwọn ibodè wa, láti tún jẹ́ kí ààbò kí ó péye si, lórí ilẹ̀-Àjogúnbá wa.
Gbogbo ìwọ̀nyí túmọ̀ sí pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) kò fi àyè kankan sílẹ̀ rárá fún ìwọ̀sí tàbí ìrẹ́jẹ láti ọ̀dọ̀ orílẹ̀-èdè míràn sí D.R.Y, tàbí sí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P), bẹ́ẹ̀ ni a ò fi àyè sílẹ̀ fún ìkọlù láti orílẹ̀-èdè kankan.