Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè, Ìyá ààfin) àti gbogbo I.Y.P ti D.R.Y ló fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún Olódùmarè fún ọdún tuntun tó ṣe alátìlẹyìn fún wa àti fún àṣepé iṣẹ́ òmìnira ilẹ̀ Yorùbá.
Gbogbo àdúrà tí àwọn ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, (I.Y.P) ńgbà pátápátá ló ń gbà.
Àdúrà ni à ń gbà ṣùgbọ́n èpè àti ìnira ló jẹ́ fún àwọn ọ̀tá ìran Yorùbá.
A lè ma lérò pé, àwọn àdúrà wa kò gbà, nítorí pé ìṣẹ̀lẹ̀ kankan kò tíì ṣẹlẹ̀ sí wọn, ṣùgbọ́n Olódùmarè dá wọn sí fún ìyà jẹ ni.
Àwọn àdúrà wa, iwọ ló jẹ́ lára àwọn ọ̀dájú, ìkà, ajẹgàba tí kò ní ìfẹ́ ìran Yorùbá bó tií wù kó kéré mọ.
Gbogbo ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, IYP ti DRY, ẹ jẹ́ kí a máa jó, kíá sì tún máa yọ̀.
Ẹnu ọpẹ́ wa kòní kan láíláí, lágbára Olódùmarè.
A pẹ ko to jẹun, Ki jẹ ibajẹ