Ìkan nínú ọ̀rọ̀ tó ṣe gbòógì tó pè fún àkíyèsí, tí màmá wa Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá sọ jẹ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì “Lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè Yorùbá ni Àkọ́kọ́“.
Màmá wá MOA tẹnu mọ fún àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (lndigenous Yorùbá People, l.Y.P) tí Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), wípé “ÒKAN” ni wá bí òṣùṣù ọwọ̀ ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantitwa tí Yorùbá.
Kí gbogbo ayé gbọ́, kí ọ̀run kó sì mọ̀ pé, àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti padà sí orírun àwọn babanla wa, Yorùbá Nation, Yorùbá Kingdom, Yorùbá Land, Yorùbá Country, gbogbo rẹ̀ wà ní abẹ́ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y).
Àparò kan kò ní ga jù kan lọ, nítorí náà kò ní sí ìyapa ní orílẹ̀ èdè Democratic Republic of the Yorùbá. Ìfẹ́ Ọlọ́run sí wá ní kí a máa ṣe ìtọ́jú ara wa, kí a sì máa wá ìlọsíwájú ọmọlàkejì wa.
Gbogbo I.Y.P ni ó máa ní ẹ̀tọ́ sí àwọn ohun ìgbá’yé gbádùn orílẹ̀ èdè D.R.Y, ọmọdé, ọ̀dọ́, arúgbó, pàtàkì jù lọ àwọn àkàndá ẹ̀dá. ̀̀
Àwa ọmọ Aládé, èyí jẹ́ ohun tí a óò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run àti màmá wa MOA fún títí láéláé. A ti bọ́ kúrò nínú ìsẹ́, òsì, ikú aitọ́jọ́, àárẹ̀, ìwà búburú, àìsàn lai ni ìtọ́jú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ti àwọn aṣekúpani amúnisìn kó wa sí láti àìmọye ọdún.
Àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà sì tẹ́wọ́ gbàá láti máa tẹ̀sìwájú nínú ìjẹgàba àti ìkóni lẹ́rú náà. Ọwọ́ pálábá wọn ti ségi, wọn kò ní gbérí mọ́ títí láéláé.
Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run Olódùmarè tí Ó ran màmá wa ìyáàfin Modupẹ́ọla Onitiri-Abiọla lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí náà.