Màmá wa Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá ti jẹ́ kí á mọ̀ pàtàkì Èdè abínibí wa, èyí tí nṣe èdè YORÙBÁ àti wípé, èdè ni ìdánimọ̀ ẹni, Orílẹ̀ èdè tó bá sì ti sọ èdè rẹ̀ nù, Orílẹ̀ èdè bẹ́ẹ̀ ti sọ ìdánimọ̀ rẹ̀ nù. 

Gẹ́gẹ́bí àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fi rán màmá wa MOA sí ìran Yorùbá wípé kí á padà sí orírun wa. MOA ti jẹ́ kó yé wa wípé, èdè Yorùbá nìkan ni a óò máa sọ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.

Láìpẹ́ yìí tí màmá tún wá bá wa sọ̀rọ̀, wọ́n sọ fún wa wípé a máa bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá lórí amóhùnmáwòrán iypdry. A máa ní àǹfààní láti gbọ́ ẹ̀kọ́ kan léra léra fún ọjọ́ mẹ́ta, ẹ̀kọ́ kejì léra léra fún ọjọ́ mẹ́ta míràn, lẹ́yìn èyí ni ìdánwò ráńpẹ́ yóò wà lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí a ti kọ́.

Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa wà ní ìmúrasílẹ̀, nígbàkúùgbà tí ẹ̀kọ́ náà bá bẹ̀rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ wa lórí iypdryTV, àwọn ètò lorísìírísìí ní a óò tún ní àǹfààní láti máa gbọ́ níbẹ̀, nípa ìtẹ̀síwájú orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá D.R.Y.

Kò sí ẹnikẹ́ni tó dàgbà jù láti kọ́ ẹ̀kọ́ o, ẹ jẹ́ kí a tẹ́tí léko. Màmá wa MOA ti sọ wípé, a máa gbọ́ ìfitónilétí nígbà tí àkókò náà bá tó. A kú ojú lọ́nà.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Díẹ̀ díẹ̀ ni’mú ẹlẹ́dẹ̀ fi nw’ọgbà