Ẹ wo wàhálà tí Babajide Sanwolu kó àwa ọmọ Yorùbá sí látàrí jíjẹ gàba tí òun àti àwọn ọmọ-àlè ìyókù rẹ̀ ń jẹ́ gàba lórí ilẹ̀ àwa ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).
Ohun tí a gbọ́ nínú ìròyìn kan ni wípé, ọkọ̀ ak’érò kan tí ó jẹ́ ti ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ni ó dédé ṣubú, èyí tó mú kí ènìyàn mọ́kànlá f’arapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ṣèbí láti dẹ́kun àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ibi bí irú èyí ni ìyá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe dìde, tí àwa ojúlówó ọmọ Yorùbá sì tì wọ́n lẹ́yìn, kí a leè máa ṣe ìjọba ara wa, kí a sì leè dáàbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn wa, pẹ̀lú àṣẹ Èdùmàrè, nígbà tí Màmá ti fi òye bí a ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè yé wa.
Ojú wa ti là, a sì ti ríi kedere wípé ọmọ-àlè lásán-làsàn ni gbogbo ẹ̀yin tí ẹ pe ara yín ní olóṣèlú àti wípé àwọn amúnisìn ọ̀gá yín ni ẹ ń ṣiṣẹ́ fún, erongba gbogbo yín ni láti pa gbogbo wa run kúrò lórí ilẹ̀ àwọn babańlá wa.
Sùgbọ́n Olódùmarè ti dójúti gbogbo yín. Àwa ìran Yorùbá kìí se ara yín mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá ọdún óléméjìlélógún tí a ti ṣe Ìkéde Òmìnira Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, bẹ́ẹ̀ ni a sì ti ṣe ìbúra-wọlé fún olórí ìjọba-adelé wá, bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ólémẹ́rìnlélógún, a sì ti sọ fún yín ṣáájú ìgbà náà wípé à ń bọ̀ láti wá gba ẹ̀tọ́ wa padà lọ́wọ́ yín.
Ṣé o wá rí ìwọ Sanwo-Olu, o nfi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀sẹ̀ rẹ síi lójoojúmọ́. Láìpẹ́ àti láìjìnnà ojú yín máa tó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, nítorí pé Olódùmarè ti jà fún wa. Bí ẹ fẹ́ bí ẹ kọ̀, ìran Yorùbá kò padà sí Nàìjíríà mọ́.