A kì í s’òótọ́ inú, kí ọ̀rọ̀ ẹni má d’ayọ̀, b’áyé ẹni bá dojúrú ìwà èèyàn ló yẹ ká wò

Òwe Yorùbá

Ètò ẹ̀kọ́ ní ìlú tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wá, èyíinì, Nàìjíríà, ti wá kúkú polúkúrúmuṣu báyi o!

Gẹ́gẹ́bí ìròhìn kan tí a gbọ́ ti sọ, ọmọ apá òkè Ọya kan ní ìlú Nàìjíríà, sọ báyi, wípé, “Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ fásitì ní Nàìjíríà ní wọ́n ti fẹ́ tà, báyi o, fún àwọn oníṣòwò onílé-iṣẹ́ àdáni”

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Ètò ẹ̀kọ́ ní ìlú tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wá, èyíinì, Nàìjíríà, ti wá kúkú polúkúrúmuṣu báyi o!

Gẹ́gẹ́bí ìròhìn kan tí a gbọ́ ti sọ, ọmọ apá òkè Ọya kan ní ìlú Nàìjíríà, sọ báyi, wípé, “Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ fásitì ní Nàìjíríà ní wọ́n ti fẹ́ tà, báyi o, fún àwọn oníṣòwò onílé-iṣẹ́ àdáni”

Ọkunrin náà, tí a rí fídíò rẹ̀ lórí ẹrọ ayélujára sọ báyi wípé, “ododo ọ̀rọ̀ ni o, láti ẹnu ìjọba Nàìjíríà fún’ra wọn.”

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ṣé wọ́n ni, ìrínisí ni ìsọnilọ́jọ̀; ọkùnrin yí, èyítí ìsọ̀rọ̀ sí rẹ̀, àti ìrísí rẹ̀ nínú fídíò ọ̀ún, jọ ọmọ Fúlàní àti ẹni tí ó ríjájẹ tí ó sì ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní ìlú Nàìjíríà, sọ báyi, wípé: “Mínístà fún ètò ẹ̀kọ́ ní ìlú Nàìjíríà fún’ra rẹ̀ ni ó sọ ọ̀rọ̀ yí o!”

Ọ̀kunrin yí wá tẹ̀síwájú nínú fídíò ọ̀ún, wípé, mínístà yí, Kòfẹ́sọ̀ Tahir Mamman, sọ báyi  wípé, “Ìjọba Àpapọ̀ Nàìjíríà tí wá dé ibi tí wọn kò rí nkankan ṣe mọ́, báyi o, àfi wípé àwọn ti f’ẹnu kò, tí kò sì tún yípadà mọ́, wípé, látàrí kí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà kí wọ́n le ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, àti tìtorí wípé ìjọba Nàìjíríà kò ní agbára mọ́ o, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn kò ní òye àti owó mọ́; láti máa gbé ètò ẹ̀kọ́ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga-jùlọ bíi ti unifásitì, lé èjìká wọn; wọ́n ti wá pinnu báyi o, wípé àwọn tí ó ní owó fún ok’òwò yíò ní ànfààní, báyi o, láti wá ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba-àpapọ̀ wọ̀nyí ní ìkáwọ́ wọn; èyí tí ó tú’mọ̀ sí wípé ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ni owó rẹ̀ dání, kí ó máa bọ o, ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà fẹ́ ta àwọn ilé-ẹ̀kọ́ fásitì wọn!”

Ọkùnrin yí wá tẹ̀síwájú láti sọ wípé, “Àwọn ol’okòwò kìí ṣe sùgọ́mù o! Wọn ò kì nfi owó wọn sínú òwò kankan láì ṣe wípé kí àwọn jẹ èrè tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ tiwọn o!”

Ó tún wá sọ, síwájú, wípé: “Níbi tí a gbé dé l’oní [èyíinì, nínú ìlú wọn ní Nàìjíríà], ó ti di èèwọ̀ fún èyí tí ó pọ̀jù lọ nínú [àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà] láti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Fásitì. Tí a bá ti wá gbé ètò ilé-ẹ̀kọ́ gíga, báyi, fún àwọn ol’okòwò, ó wá di wípé, pátápátá ni a ti ilẹ̀kùn ilé-ẹ̀kọ́ gíga mọ́ àwọn ọ̀dọ́ wa síta!”

Ọkùnrin yí wá sọ wípé, ìtúmọ̀ eléyí ni wípé, ní Nàìjíríà o, ètò tuntun yí túmọ̀ sí wípé wọn kò fẹ́ kí ọmọ mẹ̀kúnnù kí ó ní ẹ̀kọ́ ilé-ìwé mọ́, láyé! Nítorí wípé ol’okòwò máa máa gba nkan bí milíọ̀nù mẹ́ta sí mílíọ̀nù mẹ́wa lọ́wọ́ àwọn olùkẹ́kọ, gẹ́gẹ́bí owó ilé-ìwé! Ó ní, eléyi wá túmọ̀ sí wípé àádọ́run nínú ọgọ́run, àti jùbẹ́ẹ̀ lọ pàápàá, nínú àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ láti kàwé dé fásitì, ni àwọn ti yọ kúrò nínú rírí ìwé kà, nìyẹn!

Ó ní, ìwà ìkà gbáà ni eléyi jẹ́ o. Ṣùgbọ́n ní ti’wa o, ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, aò róunf’ayọ̀ bí? Nítorí tí Èdùmàrè ti sọ ọ̀rọ̀ tiwa di ayọ̀! Èyí tí Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá fi máa nsọ, láti ìgbà dé ìgbà wípé, gbogbo ohun tí Olódùmarè ti pèsè sílẹ̀ fún wa ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, dá lórí wípé, láíláí, kí á le máa yin Ẹlẹ́da wa títí òpin ayé!

Ọkùnrin ará Nàìjíríà yí wá mú ẹnu ba ààrẹ wọn l’ọhún, èyíinì, Tinubú o! Ohun tí ó dẹ̀ sọ nígbà tó mẹ́nu lé Tinubú nínú fídíò ọ̀ún, ìlù àgídìgbo ni o, ọlọgbọ́n ló lè jóo o, ọ̀màràn ló dẹ̀ le mọ̀ọ́!

Ó sọ wípé lábẹ́ àkóso Tinubú olórí wọn l’ọhún ni gbogbo aburú wọ̀nyí ti nṣẹlẹ̀ o, títí tí ó tilẹ̀ dé orí wípé Nàìjíríà, báyi, ti fi ọwọ́ sí ìbálòpọ̀ ọkùnrin-sọ́kùnrin àti obìnrin-sóbìnrin! Ọmọ Nàìjíríà tí ó nsọ ọ̀rọ̀ yí, tí ó sì tún wá jẹ́ bíi àwọn tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nígbàtí a ṣì wa láarín wọn, gẹ́gẹ́bí àwọn tí ó ní ẹnu ọ̀rọ̀ l’ọhún, wá so gbólóhùn yí jáde, ó wípé, “Àwọn tí wọ́n bá ti kọjá àyè wọn níwájú ọlọ́run, ni a óò parun ní kíákíá!” Kíni ìtumọ̀ eléyi o? Ọmọ Yorùbá ẹ gbe yẹ̀ wò!