Èèmọ̀ Wọ’lú O! Tàbí Ká Sọ Wípé Ó Ti Fẹ́ẹ́ Wọ’lú Ni, Tàbí Ó Ti Nwọ’lú Bọ̀?
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XṢé l’aìpẹ́ yí ni a gbọ́ l’orí ẹ̀rọ ayélujá’ra bí ètò ìdìbò ṣe lọ ni ìlú South Africa, tí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé wọ́n ni òyìnbo aláwọ̀ funfun pàápàá r’ọwọ́ mú l’ara ètò ìdìbò náà.
Ṣé ohun tí ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àwọn ènìyàn wa kò mọ̀ ní Afríkà, àti ní ilẹ̀ Yorùbá, pàápàá, ni wípé, ènìyàn dúdú àti ènìyàn funfun, wọ́n yàtọ̀ sí’ra pátápátá.
Ẹ má ṣe jẹ́ kí eléyi kí ó rú wa l’ojú, rárárárá. Olódùmarè ti ṣe oore fún wa ní orílẹ̀-èdè Yorùbá – àwa náà dẹ̀ tún ni ìmọ́lẹ̀ gbogbo adúláwọ̀ – kìí ṣe ìgbé’raga o, òtítọ́ ọ̀rọ̀ ni.
Ní àkókò yí, àwọn ohun tí a nrí, pẹ̀lú ìròhìn tí ó ntẹ̀ ‘wa l’ọwọ́, bákannáà, nfi yé wa wípé àwọn aláwọ̀ funfun, l’ojú méjèèjì báyi, ni wọ́n ngbé ìgbésẹ̀, o, wípé, ohun tí ó bá máa gbà ni àwọn á fun o, àwọn níláti padà s’orí ilẹ̀ Afríkà, kí àwọn tún kó wa l’ẹrú, l’ẹẹ̀kan si!
Eléyi kìí ṣe àhesọ ọ̀rọ̀ o! L’ọwọ́l’ọwọ́ báyi, ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àwọn aláwọ̀funfun ni wọ́n ti npadà, tàbí tí wọ́n nṣí kúrò ní ilẹ̀ ti’wọn, tí wọ́n sì nṣí wá sí ilẹ̀ aláwọ̀dúdú báyi!
Tí ó bá wá di ọjọ́ iwájú, àwọn ọmọ ọmọ-ọmọ wọn á sọ wípé ọmọ oní’lẹ̀ ni àwọn o!
Ẹ má ṣe jẹ́ kí eléyi kí ó yà yín l’ẹnu o! Bí wọ́n ṣe ṣe ní South Africa ní ọjọ́ kíní àná nìyẹn o, tí ó fi wá di wípé, àti ènìyàn dúdú, l’oní, àti ènìyàn funfun, papọ̀, ni wọ́n npe’ra wọn ní ọmọ ìbílẹ̀ ní South Africa o!
Ẹ jẹ́ kí á mọ̀, l’oní o, ọmọ Yorùbá, wípé Olódùmarè kò fún aláwọ̀fufun kankan ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ ní Afríkà o! Ẹ má ṣe jẹ́ kí á ṣe àṣìṣe tí àwọn South Africa ṣe o!
Wọ́n ní ojú l’alákàn fi nṣọ́’rí o! Ẹ jọ̀wọ́, ọmọ Yorùbá, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀, ọmọ ònilẹ̀, l’orí ilẹ̀ àwọn babanlá wa, ẹ má ṣe gba òyìnbó aláwọ̀ funfun kankan kí ó máa f’ọwọ́ l’alẹ̀ fún wa l’orí ilẹ̀ Baba wa o! Ọpọlọ t’ó wà l’orí òyìnbó kò dára ju tiwa lọ o!
Ẹ má ṣe rò wípé Olódùmarè fi òyìnbó ṣe ọ̀gá ará’yé o! Rárá, rárá, kò rí bẹ́ẹ̀ o! Bí ẹ ṣe máa k’igbe mọ́ Fúlàní tí ó bá fẹ́ máa fi ọwọ́ l’alẹ̀ fún yín l’orí ilẹ̀ Yorùbá, tí ẹ máa pa’riwo lé orí ọmọ Íbò t’ó ngbé’raga sí ọmọ Yorùbá, l’orí ilẹ̀ Yorùbá, tí ẹ dẹ̀ máa fa irúfẹ́ wọn lé ojúlówó ẹlẹ́ṣọ-ààbò orílẹ̀-èdè Yorùbá, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ ṣe ṣe àwọn òyìnbó o!
Èyí kìí ṣe Nàìjíríà o, t’ó jẹ́ wípé, òyìnbó ni ọlọ́run wọn!
- Ọmọ Íbò Njí Ọmọ Gbé Ní Ìjọrá!
- Ẹ̀rù Mba Àwọn Olórí Orílẹ̀-Èdè Ní Áfríkà
- Àwọn Olóríburúkú Ọba Nko’ra’wọn Jọ L’ẹhìn Tí Wọ́n Ti Ta Yorùbá S’oko Ẹrú Tán!
- Kíka Ilẹ̀ Yorùbá Mọ́ Nigeria Jẹ́ Ọ̀ràn-Dídá – D.R.Y
Tí o bá rí òyìnbó aláwọ̀funfun tí ó fẹ́ yan ọmọ Yorùbá jẹ, ní ilẹ̀ Yorùbá, bí o ṣe máa pa’riwo mọ́ ọmọ Háúsá tàbí ọmọ Íbò tí ó bá ṣe irúfẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o pa’riwo mọ́ òyìnbó ọ̀ún o!
Má ṣe gba ìgbàkú’gbà l’ọwọ́ aláwọ̀ funfun kankan o! Má dẹ̀ ṣe bá wọn sọ èdè òyìnbó!
Àfi tí ó bá gbé iṣẹ́ fún ẹ gẹ́gẹ́bí ÒGBÙFỌ̀ (kìí ṣe gẹ́gẹ́bí ọmọ-ọ̀dọ̀ o!), ṣùgbọ́n kí á gbé iṣẹ́ fún ni, bí a ṣe le gbé iṣẹ́ fún agb’ẹjọ́rò ẹni, tí a dẹ̀ máa san owó fún agb’ẹjọ́rò ọ̀ún, gẹ́gẹ́ bí iye t’ó bá pe owó iṣẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni o!
Má ṣe ṣe iṣẹ́ ẹrú kankan, láí, fún òyìnbó kankan, l’orí ilẹ̀ Yorùbá o! Má dẹ̀ ṣe jẹ́ kí òyìnbó kankan ó sọ fún ẹ wípé, ibi bái ni k’ó dé dúró l’orí ilẹ̀ Yorùbá o! ní’wọ̀n ìgbà tí o kò bá ti kọjá s’orí ibi tí òfin ilẹ̀ Yorùbá bá sọ wípé ó jẹ́ ẹ̀tọ́-ọmọ’nì’yan fún onítọ̀hún, ìbáà ṣe òyìnbó tàbí kò ṣe òyìnbó!
Má ṣe gba òyìnbó, kankan, láyé, kí ó jẹ gàba lé ọ l’orí ní ilẹ̀ Yorùba!
Tí o bá jẹ́ ọbìnrin, má ṣe jẹ́ kí òyìnbó kankan ó fi ìwọ̀sí lọ̀ ẹ́, kí ó máa ṣe bí ẹni wípé tí òun bá ti pè ẹ́, l’ati máa kọjá àyè rẹ̀ l’ara rẹ t’orí wípé òun jẹ́ òyìnbó, kí ìwọ náà wá máa gbà’gbàku’gbà t’orí wípé o rò wípé ẹni bá ti ní àwọ̀ fúnfún ní ẹ̀tọ́ l’ati ṣe ohun tí ó bá wùú pẹ̀lú aláwọ̀ dúdú, Rárá o!
Láì ṣe wípé ol’ólùfẹ́ ẹ ni! tàbí ẹni tí o ní’fẹ́ sí l’ati sún mọ́; ṣùgbọ́n k’ó kàn máa ṣe rádaràda l’ọdọ̀ ẹ ‘t’orí wípé òun jẹ́ aláwọ̀ funfun, kí’wọ náa wá máa wòó; rárá o!
Tí ó bá dẹ̀ jẹ́ wípé ní ti ìfẹ́ ni, má ṣe ṣàì ròó dáradára kí ìfẹ́ náà ó tó di ìgbé’yàwó o!
Tìt’orí wípé kò sí ẹni t’ó lè dá ẹ dúró k’óo má ṣe ìyàwó fún ẹnik’ẹni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ìyàwó fún, ṣùgbọ́n kí o bèèrè, l’ọwọ́ ara rẹ, kíni òfin orílẹ̀-èdè Yorùbá sọ nípa ẹ̀tọ́ tí ọmọ tí mo bá bí máa ní, tàbí tí kò lè ní, tí ó bá jẹ́ wípé bàbá ọmọ náa kìí ṣe ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.
Ó ti d’ojú ẹ̀ o! Òyìnbó kankan, layé, kò gbọdọ̀ jẹ gàba l’orí ọmọ Yorùbá, l’orí ilẹ̀ Yorùbá.
Tí o bá wà ní ibik’ibi, tí ó jẹ́ wípé ẹ tò s’orí ìlà l’ati ṣe ohunk’ohun, tí òyìnbó kan wá wà l’ẹhìn ẹ, má ṣe ti’t’orí wípé ó jẹ́ òyínbó wá sọ fun wípé k’ó ré kọjá síwájú, rárá o!
Tí ó bá sì jẹ́ wípé nṣe ni o nta’jà, má ṣe na’wọ́ pe òyínbó t’ó wà l’ẹhìn wípé k’ó máa bọ̀ ní’wájú, kí o le tètè da l’ohùn, tìt’orí wípé ó jẹ́ òyìnbó rárá o!
A kò gbọ́dọ̀ fi àyè kankan gba òyìnbó aláwọ̀ funfun l’ati jẹ ayé “fà-mí-l’etè-‘ntu’tọ́” l’orí ilẹ̀ Yorùbá.
Ìbáà ṣe òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì, òyìnbó Europe, òyìnbó Amẹ́ríkà, òyìnbó china, kò sí òyínbó kankan t’ó ga ju ọmọ Yorùbá l’orí ilẹ̀ Yorùbá, gẹ́gẹ́ bí kò ti sí Fúlàní, Íbò tàbí háúsá kankan t’ó lè fi ọmọ Yorùbá s’abẹ́ l’orí ilẹ̀ Yorùbá.
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ojú-àánú yín kí ó sọ òyìnbó tàbí ẹnik’ẹni míràn di ọ̀gá tàbí alágbára lé ọmọ Yorùbá l’orí, ní orí ilẹ̀ Yorùbá.