Ètò-amúnisìn tí wọ́n npè ní nàìjíríà, èyí tí kìí ṣe ìlú, tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè, èyí tí ó wà fún fífi ìyà jẹ àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀, kí ìfẹ́ amúnisìn ó lè wá sí ìmúṣẹ, èyí tí ó jẹ́ pé, láti pa àwọn ènìyàn run ni, kí amúnisìn ó lè jogún ilẹ̀ wọn.

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni píparun yí ṣe máa nwá’yé – bí wọ́n ṣe tòó sílẹ̀ ni; ṣé a kúkú mọ̀ pé “ètò” jẹ́ ohun àtọwọ́dá, èyí tí ó wà fún kí nkankan leè ṣẹ̀lẹ̀ gẹ́gẹ́bí wọ́n ti tòó tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.

A tún lè pèé ní “ìlànà” fún bí ohun kan á ṣe lè ṣẹlẹ̀. Gbogbo ìwọ̀nyí ni màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) ti ṣe àlàyé rẹ̀ fún wa dáadáa.

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ngbà láti pa, láti jí, àti láti pa àwọn ènìyàn run. 

Nínú ọdún yí nìkan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn tí wọ́n ti kú, látàrí àìsí ààbò tó péyé. Ẹnu ara wọn ni wọ́n fi sọ́ – iye tí wọ́n sì sọ mọ, nìyẹn! 

Nínú àwọn tí wọ́n kú ìkú olóró tí kò tọ́ sí ọmọ-ènìyàn yí, wọ́n sọ pé, àwọn bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó ni ó jẹ́ ní apá àríwá nàìjíríà wọn lọ́ùn! Ikú wọn sì jẹ́ láti ọwọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí.

Tani ó gba agbésùnmọ̀mí láàyè? Nàìjíríà fún’ra rẹ̀ ni agbésùnmọ̀mí tí ó tún fi àyè gba agbésùmọ̀mì. 

Ètò tí wọ́n ti tò sílẹ̀ nìyẹn, láti ọ̀dọ̀ àwọn amúnisìn, ọ̀gá wọn!

Ètò tí kìí ṣe ìlú, tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè; tí kò ní agbára ìṣàkóso-ara-ẹni kankan ní abẹ́ òfin ní àgbáyé! Ètò tí ó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe tòó sílẹ̀ náà ni ó ṣe nṣẹlẹ̀ yẹn – nítorí náà, ó tẹ́ àwọn tí wọ́n tòó bẹ́ẹ̀ lọ́rùn bí ó ṣe nṣelẹ̀, àwọn ará nàìjíríà kàn nkígbe lásán ni!

Aláìmọ̀kan pátá gbáà ni gbogbo àwọn tí ó pera wọn ní ọ̀kàwé àti ọ̀mọ̀wé, tí wọ́n nṣe agbátẹrù “one nàìjíríà.” Iṣẹ́ tí àwọn amúnisìn náà rán wọn ni wọ́n njẹ́.

Ṣé wọn ò kúkú mọ̀ pẹ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ wọn ní ilé-ìwé amúnisìn, ẹ̀kọ́ kí ènìyàn lè máa ṣe lòdì sí ìṣẹ̀dá ara rẹ̀ ni, kí ó sì máa ṣe ohun tí amúnisìn áá túbọ̀ lè fi kó ìran rẹ̀ lẹ́rú.

Nígbà tí àwọn tọ́ npe ara wọn ní kò-sí-bí-àwọn-ò-ṣe-jẹ́ bá tún nṣe alátìlẹyìn fún “one nàìjíríà”, – kí ètò amúnisìn láti pa, láti jí àti láti parun, léè wá sí ìmúṣẹ.

Ẹ kú ọ̀fọ̀ o, ẹ̀yin ará ètò-amúnisìn tó njẹ́ nàìjíríà, ṣùgbọ́n tiwa ni pé kí ẹ ṣáà kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).

Ẹ̀yin tí ẹ pe ara yín ní Yorùbá ṣùgbọ́n tó jẹ́ ti “one nàìjíríà” ni ẹ nṣe, a ò gbà yín láyè lórí ilẹ̀ wa láti máa hùwà one-nàìjíríà. Ẹ kọjá sí nàìjíríà yín lọ́hun.

Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), àwa ò sí lára nàìjíríà mọ́, a ti kéde òmìnira orílẹ̀ èdè wa láti Ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún. 

Bóyá wọ́n fẹ́ tàbí wọ́n kọ̀, dandan ni kí wọ́n kúrò nínú gbogbo oríkò-ilé-iṣẹ́-ìṣàkóso wa ní Orílẹ̀ èdè Yorùbá (D.R.Y) láìpẹ́. Àwa ni a ní nkan wa; agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀!

Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) ti sọ fún ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ aṣojú agbésùnmọ̀mí àti ajẹgàba, nàìjíríà, ẹ jọ̀wọ́ ọ́fíìsì D.R.Y sílẹ̀, fún adárí-ètò-ìṣúná ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti fún adájọ́-àgbà níbẹ̀. Á dára kí ẹ gba ìkìlọ̀.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal