Ìròyìn tí ó tẹ̀wá lọ́wọ́ ní yàjóyàjó sọ pé, gómìnà wọn ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n npè ní “Niger” ní ètò-amúnisìn tí wọ́n npè ní “nàìjíríà”, fi ọ̀rọ̀ léde pé ìpínlẹ̀ “Niger” ọ̀ún ṣe ìlérí láti fún ilé-iṣẹ́ Dangote ní igba saarè ilẹ̀; bákan-náà, wọ́n ṣe ìlérí láti fún ilé-iṣẹ́ BUA ní igba saarè ilẹ̀, láti fi dá ilé-iṣẹ́ sílẹ̀.

Èyí ni láti fi tó ètí gómìnà ìpínlẹ̀ “Niger” ní nàìjíríà, Muhammad Umaru Bago, pé Babangida, nígbàtí ó nṣe ààrẹ ológun ní nàìjíríà, òun ló bu lára ilẹ̀ Yorùbá, tí ó bùú mọ́ ìpínlẹ̀ Niger, bẹ́ẹ̀ náà ní ó bu lára ilẹ̀ Yorùbá mọ́ ìpínlẹ̀ Kebbi yín lọ́hun.

Ṣùgbọ́n, ìwọ gómìnà Bago, a fẹ́ kí o mọ̀ ni o, Yorùbá kìí ṣe ara Nàìjíríà mọ́ o, láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, a sì ti ṣe ìpolongo

ìṣàkóso-ara-ẹni wa, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹ̀gbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, ìṣàkóso wa sì ti wà ní ìkàlẹ̀ láti ìgbà náà.

Nítorí èyí, gómìnà Bago ti ìpínlẹ̀ Niger ní Nàìjíríà, a fẹ́ kí o mọ ibi tí ilẹ̀ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ o! Láti Odò Ọya, sí ìsàlẹ̀, Ilẹ̀ Yorùbá nìyẹn o! kí o gbọ́ dáadáa!

Máṣe rò pé ìṣàkóso rẹ kọjá odò Ọya sí’sàlẹ̀ o, rárá o! Kí o yára mọ ìwọ̀n ara ẹ o! Ibikíbi tí ó wà ní Ìsàlẹ̀ Odò Ọya, o ò ní aṣẹ kankan níbẹ̀ o, ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni ibẹ̀ yẹn – máṣe sọ pé o ò gbọ́ o!

A tun fi àkókò yí sọ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi, ní Nàìjíríà, pé, ibikíbi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ Odò Ọya, máṣe kàá mọ́ Kebbi mọ́ o!

A nfi tó ẹ léti ni, kí o máṣe fi ọwọ́ ara ẹ fa wàhálà. Ilẹ̀ Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ti bẹ̀rẹ̀ láti odò Ọya sí’sàlẹ̀, máṣe ka ibẹ̀ mọ́ ìpínlẹ̀ Kebbi mọ́.

Ìwọ Dangote, ṣọ́ ara ẹ, níbikíbi, máṣe tàgẹ̀rẹ̀ wá sí orí ilẹ̀ D.R.Y o, máṣé jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ pé òun fún ẹ ní ilẹ̀, tàbí ta ilẹ̀ fún ẹ, ní Democratic Republic of the Yoruba, o mọ̀ o! o mọ̀ pe D.R.Y kò sí lára Nàìjíríà mọ́! Ilẹ̀ D.R.Y sì ti bẹ̀rẹ̀ láti Odò-Ọya sí’sàlẹ̀; máṣe sọ pé o ò mọ̀ o!

Láti Odò-Ọya, ẹ ti wọ ìṣàkóso Ọ̀yọ́ ti àtijọ́ (Old Oyo Empire), ẹ má kọjá odò Ọya sí’sàlẹ̀ o.

Tí iná bá ńjó lóko, màjàlá á ṣe òfófó

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal