Ọ̀rọ̀ ètò ààbò jẹ́ ohun pàtàkì tí a kò sì gbúdọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú, nítorí wípé, kò sì ohunkóhun tí ènìyàn leè ṣe  nínú ìbẹ̀rù àti àìbalẹ̀ ọkàn. Ìjọba tó bá fẹ́ ìdàgbàsókè fún orílẹ̀ èdè rẹ̀, yóò rí ọ̀rọ̀ ààbò gẹ́gẹ́ bíi ohun àkọ́kọ́ nínú ètò ìsèjọba  rẹ̀ tí ó sì gba àbójútó gidigidi.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.

Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Olódùmarè pè wọ́n sí èyí tí ètò ààbò tó dájú sì jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wá lọ́wọ́, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, èyí tí yóò mú ọkàn gbogbo wa bálẹ̀ lórí ilẹ̀ babańlá wa.

Àwọn àgbẹ̀ wa yóò leè máa lọ sí oko wọ́n pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀, tí kò ní sí ìbẹ̀rù àwọn ajínigbé, àwọn arìnrìn-àjò yóò leè lọ síbi tó bá wù wọ́n ní àkókò tí wọ́n fẹ́,láìsí ìfòyà àwọn alọnilọ́wọ́gbà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìbẹ̀rù lórí àwọn dúkìá wa gbogbo.

Bákan náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí yóò  máa wo ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn yóò wà tọ̀sán-tòru, àti wípé, káàkiri orilẹ́ èdè wa ni yóò ní ohun èlò ìyàwòrán, dé bi pé, abẹ́rẹ́ tó kéré jù kò leè jábọ́ tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò kò ní mọ̀ ní orí ilẹ̀ wa.

Iṣẹ́ ọwọ́ Olódùmarè ni eléyìí jẹ́, nítorí náà àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wa títí láé.