Lójoojúmọ́ ni àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí ń sáré tí wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti ríi dájú pé aláwọ̀ dúdú kò bọ́ lọ́wọ́ wọn.
Láìpẹ́ yìí ní a gbọ́ bí orílẹ̀ èdè Niger ṣe f’òpin sí ìwé àdéhùn tí wọ́n ṣe pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n sì wípé àwọn kò fẹ́ ọmọ ológun Amẹ́ríkà kankan mọ́ lórí ilẹ̀ wọn, nígbà tí ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà kò tẹ̀lé àlàkalẹ̀ òfin àdéhùn wọn, bí wọn ò ṣe san owó ibùdó tí wọ́n nlò fún àwọn ọmọ ológun Amẹ́ríkà ọ̀hún ní orí-ìlẹ̀ Niger, tí wọ́n sì tún kọ̀ lati tú àṣírí ibi tí àwọn agbésùnmọ̀mí wà lórí ilẹ̀ wọn, àti pé Amẹ́ríkà fẹ́ máa yan àwọn tí Niger gbúdọ̀ bá d’òwò pọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè.
Èyí ló mú kí orílẹ̀ èdè Niger fárígá wípé kò sí àǹfààní kankan nínú ìbàṣepọ̀ ọ̀hún fún àwọn, ó sàn kí oníkálukú kó ẹ̀kọ rẹ̀ lọ́wọ́.
Èyí ló mú kí Amẹ́ríkà tún gbé ìgbésẹ̀ míràn o. Ìpàdé kan wáyé láìpẹ́ yí ní orílẹ̀ èdè Botswana, láarín ọ̀gá àgbà tí ó ga jùlọ nínú iṣẹ́ ológun ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Q. C. Brown àti àwọn ọ̀gágun orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú káàkiri, láti sọ̀rọ̀ nípa ètò ààbò àti iṣẹ́ ológun, orílẹ̀ èdè tí àwọ́n Amẹ́ríkà yóò bá ní àjọṣepọ̀ àti àwọn àǹfààní tí yóò wà níbẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn ọ̀hún ti ṣeé lálàyé wípé, ìjọba tó wà níbẹ̀ báyìí ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti fi léde pé láìpẹ́ yí ni àwọn yóò ní ibùdó ológun míràn sí Orílẹ̀- èdè Benin, Ivory Coast àti Orílẹ̀-èdè Ghana, tí ọ̀gá ológun kan ní orílẹ̀ èdè Ghana náà sì ti ń báwọn polongo rẹ̀ wípé, ìlú tí wọ́n bá ti gba àwọn agbésùnmọ̀mí láàyè láti máa gbòòrò síi, kò sí bí kò ṣe ní kan orílẹ̀ èdè mìíràn, àti pé ohun tí ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà kò fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ nìyí tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti dẹ́kun rẹ̀. Ọmọ Ghana wá sọ ara rẹ̀ di agbẹnusọ fún Amẹ́ríkà! Ṣé àwọn aláwọ̀dúdú yìí kìí ronú ni?
A lérò pé ẹni tí ó bá ń ṣe àìsàn ló máa ń nílò oníṣègùn ni, àbí nígbà wo ni orílẹ̀ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n dárúkọ wọ̀nyí di agbátẹrù àwọn agbésùnmọ̀mí, tí ó fi wá jẹ́ pé ibẹ̀ ni Amẹ́ríkà fẹ́ lọ dọdẹ sí de agbésùnmọ̀mí?Wọ́n tún sọ wípé, àwọn yóò mú àjọsepọ̀ wọn nípa ètò ààbò pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Ivory Coast kó gbòòrò síi, kí wọ́n sì leè gbógun ti àwọn agbésùnmọ̀mí àti láti pèsè agbègbè tó dára fún ètò ọrọ̀-ajé.
Amẹ́ríkà tún ṣe àlàyé kan wípé àwọn ẹ̀ka wọn tó ń rí sí ètò ààbò faramọ́ ìpèsè ẹ̀ṣọ́ aláàbò sí àwọn ẹnu ‘bodè orílẹ̀ èdè Ivory Coast láti dènà ìgbésùnmọ̀mí àti gbígbé oògùn olóró.
Tani kò sàì mọ̀ wípé, àlùwàlá ológbò wọn, ọgbọ́n àti k’ẹ́ran jẹ ní. Gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ń dá kò ju láti ní ibùdó fún àwọn ọmọ ológun Amẹ́ríkà ní Orílẹ̀ èdè Ivory Coast.
Ìdí nìyí tí wọ́n tún fi ní àwọn máa ṣe ìpàdé àpéjọ kan tó jẹ́ ti àwọn ọmọ ológun ní ọdún tó ń bọ̀ yí níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní orílẹ̀ èdè Ghana.
Ẹ̀bi wọn kúkú kọ́, tí kìí bá ṣe àwọn akótilétà tí wọ́n pe ara wọn ní aṣáájú káàkiri ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, tí wọ́n gbà láti ta ìran wọn torí owó àti ipò. Ẹ sọ gbogbo àṣà yín dànù. Ṣé ẹ lè lọ sí ọ̀dọ̀ wọn láti máa ṣe rádaràda tí àwọn ń ṣe ní Áfríkà ni?
Ṣé a rántí wípé màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ti fi ìgbà kan sọ fún wa pé, èròǹgbà àwọn amúnisìn wọ̀nyí sí wa kò dára rárá, ọ̀nà láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ tọ̀ọ́ lójoojúmọ́.
Nítorí náà, gbogbo wa ẹ jẹ́ ká dìde láti gba ara wa lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìkà wọ̀nyí, bí ọdún ṣe ń gorí ọdún bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára, ṣùgbọ́n Olódùmarè kò ní fún wọn ṣe, ìran Yorùbá kò tún s’ẹrú mọ́.
Òótọ́ tó wà nídi ọ̀rọ̀ yí ni pé, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àti àwọn Faransé, bákannáà, àfojúsùn wọn ni láti kó ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú lẹ́rú pátápátá.
Àwọn aláwọ̀dúdú tí wọ́n dẹ̀ nṣe agbátẹrù fún àwọn funfun wọ̀nyí, èyí tí babanlá baba wọ́n ṣe níjọsí ni àwọn náà tún ń ṣe báyi, láì ro àtunbọ̀tán!
Wọ́n ti gbé ìwà àti àṣà òyìnbó lérí; aṣọ òyìnbó ni wọ́n nwọ̀, èyí tí òyìnbó bá sọ pé àwọn nfẹ́ kó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Afríkà ni àwọn akótilétà ọmọ Áfríkà wọ̀nyí nbá wọn fẹ́! Wọ́n kọ ń kan tó jẹ́ ti aláwọ̀dúdú sílẹ̀! Wọ́n ndalẹ̀ Ìran wọn!
Ṣé aláwọ̀dúdú kankan le lọ sí ìlú àwọn òyìnbó wọ̀nyí láti lọ máa ṣe nkan tí àwọn òyìnbó ọ̀ún wá máa nṣe ní Áfríkà ni?
Ìyá wa, MOA, sọ pé àwọn òyìnbó wọ̀nyí, ìpinu àti ìpalẹ̀mọ́ wọn ni pé kí wọ́n gba gbogbo ilẹ̀ Áfríkà pátápátá. Òun ni wọ́n sì ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ yí!
Àwọn aláwọ̀dúdú tí wọ́n ń gbà wọ́n láàyè kò la ojú wọn láti ri pé àbọ̀dè ni àwọn ń gbà fún Áfríkà; wọn ò lo ọpọlọ wọn láti mọ̀ pé ṣe ni kí àwọn ó tún íran wọn ṣe, kìí ṣe kí wọ́n gbé ìran wọn lé òyìnbó lọ́wọ́! Wọ́n kàn ń gbà sí òyìnbó lẹ́nu, ohunkóhun tí òyìnbó bá ti ń fẹ́! Háà! wọ́n ń ta Ìran wọn nítorí owó.