Ìròhìn kan tí ó tẹ̀ wá l’ọwọ́ l’orí ẹ̀rọ ayélujá’ra, l’ó sọ wípé, ẹ̀rù ti mba ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ àwọn olórí-orílẹ̀-èdè ní Áfríkà o! àti, ní pàtàkì jùlọ, ìwọ̀-oòrùn Áfríkà! Njẹ́ kíni èrèdí eléyi o?
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XA gbọ́ wípé nṣe ni ìbẹ̀rù-b’ojo ti wá bá wọn, báyi o, l’atàrí bí wọn ò ṣe mọ kíni ààrẹ ìlú Burkina Faso, èyíinì, Ibrahim Traore, wọn ò mọ kíni ó ní l’ọkàn l’ati ṣe o!
L’ọnà kíní, bí Ibrahim Traore ṣe ngbé ìgbésẹ̀ tí kìí ṣe ìgbésẹ̀ irúfẹ́ ti àwọn jẹgúdú-jẹrá ààrẹ-orílẹ̀-èdè míràn, eléyi ti njẹ́ kí ẹ̀rí-ọkàn ó máa bá irú àwọn jẹgúdú-jẹrá bẹ́ẹ̀ jà!
L’ọnà kéjì, ìròyìn tẹ̀ wá l’ọwọ́ wípé àwọn ohun bíi ti ìdáàbò-bo ìlú tí ó nwọ’lé sí Burkina Faso l’ẹnu ìgbà díẹ̀ sí’bi tí a wà yí, fi’hàn wípé, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ kò bá mọ́ nínú àwọn ààrẹ t’ó kù, pàápàá ní Ìwọ̀-Oòrùn Áfríkà, níl’ati sún’ra kì, kí ó so ewé agbéjẹ́ mọ́’wọ́.
A gbọ́ wípé Ibrahim Traore ṣẹ̀ṣẹ̀ ra adákẹ́-jẹ́-wo’lẹ̀ (èyíinì, DRONE) l’ati ìlú Turkey (gẹ́gẹ́bí ìròhìn náà ṣe sọ), tí ó sì jẹ́ eléyi tí ó l’agbára púpọ̀! Kíni ó fi nṣe o?
Àwọn kan ní, bóyá ó ní àṣepọ̀ l’aàrin òun ati Russia, l’atàrí kí wọ́n le máa wo bí nkan ṣe nlọ ní apá ìwọ̀-oòrùn Áfríkà, l’áti lè ran àwọn tí ó bá tako ìjọba jẹgúdú-jẹrá orílẹ̀-èdè wọn, l’ati lè ran irú àwọn alátakò bẹ́ẹ̀ l’ọwọ́ l’ati bo’rí irúfẹ́ àwọn ìjọba jẹgúdú-jẹrá bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ṣé òtítọ́ ni eléyi? A ò tíì mọ o!
- Orílẹ̀-Èdè Yorùbá: Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá Gba Ìkìlọ̀!
- Kíka Ilẹ̀ Yorùbá Mọ́ Nigeria Jẹ́ Ọ̀ràn-Dídá – D.R.Y
- Àwọn Olóríburúkú Ọba Nko’ra’wọn Jọ L’ẹhìn Tí Wọ́n Ti Ta Yorùbá S’oko Ẹrú Tán!
Ohun tí a mọ̀ ni wípé, ọkùnrin Ibrahim Traore yí, ó dàbí ẹni wípé, ẹnití inú àwọn aláyé-bàjẹ́ orílẹ̀-èdè kò lè dùn sí ni, nítorí ó dàbí wípé kìkìdá ohun dáradára nìkan ni òun máa nrò ní ti’rẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
A ti’lẹ̀ gbọ́ wípé, kàkà kí ó máa ra àwọn ọkọ̀ o ní bílíọ̀nù-bílíọ̀nù fún àwọn ol’oṣèlú, nṣe l’ó sọ fún wọn wípé, ẹni bá máa ṣ’iṣẹ́ pẹ̀lú òun o, nṣe ni kí ẹni náà máa fún’ra rẹ̀ lo mọ́tò tí òun fún’ra rẹ̀ rà!
Nṣe ni a gbọ́ wípé, kàkà k’ó ra mọ́tò fún àwọn ol’oṣèlú, nṣe l’ó nra kata-kata tí àwọn àgbẹ̀ máa fi ṣ’oko.