À b’ẹ ò rí nkan! Àwọn olórí burúkú gbogbo tí wọ́n pe’ra wọn ní Ọba ní ilẹ̀ Yorùbá, np’ètep’èrò wípé àwọn fẹ́ kó ara wọn jọ l’ati jà fún ìran Yorùbá, àti l’ati wá nkan tí kò sọnù, l’ẹhìn ìgbà tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti dúró tán (D.R.Y) gẹ́gẹ́bí Orílẹ̀-Èdè aṣè’jọba-ara-ẹni (Sovereign Nation) l’ati ọjọ́ kéjìlá oṣù kẹ́rin, ọdún yí (2024)!
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XẸ nlẹ́ o, ẹ̀yin ọba òfò, ọba àdánù, ìgbà yí l’àárọ̀ yín, t’ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ r’ayè fún ìran yí? BLACK LION l’ó sọ bẹ́ẹ̀!
Ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, BLACK LION, wá béèrè àwọn ìbéèrè kan o, bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
BLACK LION sọ wípé, Èkíni, Tani àwọn Fúlàní ti nlò, l’ati iye ijọ́ wọ̀nyí wá, l’ati fi ìran Yorùbá sí oko ẹrú, l’abẹ́ Fúlàní? oko amúnisín? Ó wá dá’hùn wípé, Àwọn ọba (àwọn tí wọ́n pe’ra wọn l’ọba) wọ̀nyíi náà ni!
Èkéjì, Tani ìjọba Nàìjíríà ti nlò l’ati àt’ẹ̀hìnwá (tí kìí bá nṣe nísiìyí tí Olódùmarè ti gbà wá sí’lẹ̀ kúrò l’ọwọ́ wọn), tani Nàìjíríà nlò l’ati gba ilẹ̀ Yorùbá, kúrò l’ọwọ́ ìran Yorùbá? Ó ní wípé àwọn ofò ẹdá t’ó pe’ra wọn l’ọba yíi náà ni!
Ẹ̀kẹ́ta, BLACK LION tún béèrè wípé, Àwọn wo ni ọ̀tá ìran Yorùbá nlò, l’atí jí owó, l’ati fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí gbé owó já’de kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá o? Àwọn òfò ẹ̀dá tí wọ́n pe’ra wọn ní ọba yíi náà ni o!
Ẹ̀kẹ́rin, ó béèrè wípé, Tani ọ̀tá Yorùbá nlò l’ati mú Yorùbá s’abẹ́, kí Yorùbá má ṣe gbé’rí, l’ati iye ọjọ́ wọ̀nyí wá? Àwọn t’o pe’ra wọn l’ọba yíi ni o!
Ẹ̀kárun, Àwọn wo ní ọ̀tá nlò l’ati dún màhuru-màhuru má ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, l’orí ilẹ̀ babanlá wọn? Àwọn òfò ọba yíi ni o!
Ó wá sọ wípé, l’ẹyìn tí ó ti jẹ́ wípé àwọn ọba al’ayé’bàjẹ́ wọ̀nyí, ni wọ́n sún ọmọ Yorùbá dé ipò ọ̀fọ̀ àti òṣì tí a ba’ra wa l’oní, tí kìí bá nṣe àánú Ọlọ́run t’ó ṣí’jú wò wá ní déédé ìgbà yí, àwọn òfò ọba wọ̀nyí wá ngb’ìyànjú nísiìyí wípé àwọn nkó ẹgbẹ́ kan jọ l’abẹ́ ìṣ’ètò àwọn kan tí wọ́n pe’ra wọn ní “Alliance for Yoruba Demcratic Movements.” Hábà!
BLACK LION wá fi ohùn tí ó l’agbára rán’ṣẹ́ sí gbogbo àwọn ol’ofo wọ̀nyí, wípé, GBOGBO YÍN, PÁTÁ, Ẹ TI DÁ’RÀN l’abẹ́ òfin Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá! – òfin tí ó gbée ró gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè aṣè’jọba-ara-ẹni, l’ati ọjọ́ kéjìlá, oṣù kẹ́rin, ẹgbàá ọdún, ó lé mẹ́rin-lé-l’ogún yí (2024). Wọn ò tíì sọ fún yín ni? Ẹ ti ṣìí, ẹ̀yín àdánù ẹ̀dá tí ẹ npe’ra yín ní ọba, àti àwọn al’agbátẹ̀rù yín gbogbo, àwọn olófò tí wọ́n pe’ra wọn ní oní’ròhìn. Ọba l’ati ‘bo dé ‘bo? Wọn òì tíì sọ fún yín ni?
Ṣé ọ̀rọ̀ yí kúkú wá’yé l’atàrí ọ̀rọ̀ kùbákùngbé kan tí ó já’de l’orí ẹ̀rọ ayélujá’ra, ní ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kárun-dín-l’ọgbọ̀n, oṣù òkúdù (èyíinì, oṣù kẹ́fà, ní ònkà ayé òde òní), ọdún 2024 yí, èyí tí àwọn kan tí wọ́n pe’ra wọn ní “Alliance for Yoruba Democratic Movements” sọ wípé àwọn nkó àwọn ọba jọ, l’ati ní ẹgbẹ́ àwọn ọba! À b’ẹẹ̀ rí? L’aago méló, t’orí Olúwa? L’aago méló?
Wọ́n ní àwọn ṣe ìpàdé ní Èkó nínú ọ̀sẹ̀ yí, àti wípé àwọn ti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tí yíò ṣe àbẹ̀wò sí àwọn tí wọ́n pè ní ọba wọ̀nyí, káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, títí dé Kwara àti Kogí, àti Delta, l’atàrí wípé àwọn fẹ́ dá “O’odua Council of Traditional Rulers” sí’lẹ̀! Ẹ jọ̀wọ́, l’abẹ́ òfin wo, o? Wọ́n l’ayà l’ayà, wọn tún npe èdè “Nàìjíríà” (“South West”) ní’bi tí wọ́n ti ns’ọ̀rọ̀ ìran ọmọ Yorùbá! Ha! Ti’yin ti bá yín “South West” ní’bo, o?
BLACK LION wá béèrè wípé tani ó ta ohun ìní ìran Yorùbá fún àjèjì, tí wọ́n sì nta ilẹ̀ àjogúnbá ìran Yorùbá? Àwọn wèrè t’ó pe’ra wọn l’ọba yíi ni o! Àwọn wo ni wọ́n npa’dí-àpò-pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́tẹ (tí wọ́n pe’ra wọn ní ‘Elite’) l’ati jí ohun ìní Yorùbá? ÀWỌN T’Ó PE’RA WỌN NÍ ỌBA YÍI NÁÀ NI O! Àwọn wo ni wọ́n nṣ’iṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn t’ó pe’ra wọn ní gómìnà ní ilẹ̀ Yorùbá, l’ati ṣ’iṣẹ́ ìparun fún ỌMỌ YORÙBÁ? Àwọn àdàmọ̀dì èèyàn t’ó pe’ra wọn ní ọba yíi náà ni o! Àwọn ni àṣìtáánì ìran Yorùbá!
BLACK LION tún wá béèrè wípé, Àwọn wo ni wọ́n npa’dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn tí kìí ṣe ìran Yorùbá l’ati ṣe aburú fún ìran ọmọ Ol’ogo? Àwọn olóríburúkú tí wọ́n pe ara wọn ní ọba yíi náà ni o! Àwọn ni akót’ilétà!
Ó tún béèrè sí’wájú wípé, àwọn wo ní wọ́n npa’dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn oyìnbó, àt’òyínbó Europe, àt’òyìnbó china àti gbogbo wọn, l’ati mú ìran Yorùbá sí oko amúnisìn? Àwọn ọba (àwọn tí wọ́n pe’ra wọn l’ọba) yíi náà ni!
Àwọn wo ni ó ngba àwọn ajèjì àti àt’ọ̀húnrèwá gbogbo, l’ayè l’ati hùwà agbésùnmọ̀mí, àti l’ati máa dún màhuru-màhuru mọ́ ìran Yorùbá? Àwọn òṣì èyàn t’ó pe’ra wọn ní ọba wọ̀nyíi náà ni o!
Àwọn wo ni ìtàn sọ fún wa wípé ó ta ìran Yorùbá sí Oko Ẹrú káàkiri àgbáyé, tí wọ́n dẹ̀ ṣì nta ọmọ Yorùbá, l’oríṣiríṣi ọ̀nà, sí oko ẹrú títí di àsìkò yí? Àwọn tí wọ́n po’nú, tí wọ́n pe’ra wọn ní ọba yíi náà ni! Tani ó ba ilẹ̀ Yorùbá jẹ́, dé ibi tí ó wà l’oni yí? Àwọn òfò ẹ̀dá tí wọ́n npe’ra wọn l’ọba yíi náà ni o! Wọ́n dẹ̀ sì nṣeé títí di ìsin-ìyí!
Wọ́n wá fẹ́ máa kó ẹgbẹ́ òfò kan jọ, nísiìyí! À! ó ti pẹ́ẹ yín! A ti bọ́ l’ọwọ́ yín! Ẹ ò já mọ́ nkankan ní’lẹ̀ Yorùbá mọ́! Pátápátá ni ẹ ò já mọ́ nkankan mọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá o! K’ẹ́ẹ yáa gbọ́! Orí burúkú t’ẹ ti nṣe l’ati iye ijọ́ yí wá, ẹ rò wípé ẹ lè máa kó wa l’ẹrú lọ!? KÒ JỌỌ́!
Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá l’ọwọ́ sọ wípé àwọn ìgbìmọ̀ tí wọ́n ní àwọn fẹ́ kó àwọn t’ó pe’ra wọn l’ọba wọ̀nyí jọ, tún sọ wípé, àwọn máa ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Togo, Bènin àti Ghana bákannáà. Àb’ẹẹ̀ r’á wọn olóṣì! Kí ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fa èléyí, báyi, tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti wà l’orí ìkàlẹ̀?
BLACK LION wá tún f’ohùn lé’de o! Ó ní wípé, Ẹ dúró náà! Ẹ̀yin òfò ẹ̀dá tí ẹ pe’ra yín l’ọba yíi, ṣé ẹ rò wípé a ò mọ ìtàn ni? Tani kò ṣàì mọ ìtàn àti ìwà aláyé’bàjẹ́ àwọn ọba Yorùbá, káàkiri àgbáyé? Ayé yín ò ní dáa! Tani ò ṣàì mọ̀, káàkiri àgbáyé, wípé, ìdílé àwọn ọba ní ilẹ̀ Yorùbá l’ó fa èyí tí ó pọ̀ jù ní ìyà tí ìran ọmọ Yorùbá njẹ káàkiri àgbáyé?
Ẹlẹ́da àwọn tí babanlá baba yín, tí wọ́n pe’ra wọn l’ọbá, ẹlẹ́da àwọn tí wọ́n tà s’oko ẹrú fún àwọn òyìnbó, ẹlẹ́da wọn mbá yín jà, l’ọwọ́l’ọwọ́ báyí! Ẹẹ̀ tíì mọ̀ niì, ti’yín ti tán ní’lẹ̀ Yorùbá! Ó ti tán pátápátá po! Olódùmarè l’ó rán wa ní’ṣẹ́ t’á nṣe yíi.
Ó ní ẹkún àwọn tí àwọn baba yín tà s’oko ẹrú àwọn òyínbó, ní’rínwó ọdún, o lé, s’ẹhìn, ó ní ẹkún wọn kò jẹ́ kí òun gbá’dùn l’ọrun! Ṣebí àwọn baba yín l’ó bẹ̀rẹ̀ òwò ẹrú?! Òun l’ẹ̀yin náà tún nṣe fún wa l’oní!
Àwọn ìdílé yín; àwọn babanlá yín, l’ó pa ìran Yorùbá l’ẹkún nígbànáà l’ọhún; tí wọ́n di ọwọ́ àwon babanlá ìran ọmọ Yorùbá, tí wọ́n fà wọ́n lé àwọn òyìnbó l’ọwọ́; ẹ rò wípé ati gbàgbé ni? Ẹ̀jẹ̀ àwọn baba wa l’ó wà l’ara waà; ẹ̀jẹ̀ dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí rùn!
A nsàárò àwọn baba wa tí àwọn baba yín tà s’oko ẹrú! Ọrun nṣ’ọ̀fọ̀ tít’orí wọn-ọ̀n; ṣé ẹ rò wípé ọjọ́ ẹ̀san ò ní dé ni? Ọjọ́ ẹsan ti dé; àtubọ̀tán ti dé! Ọwọ́ ti kan ọwọ́ nínú ẹ̀mí; ẹ̀jẹ̀ ti fọ’hùn nínú ẹ̀mí; kò yé yín níì; àwọn babanlá wa tí àwọn baba yín tà s’oko ẹrú ti dìde; wọ́n ní àwọn ò ní gbà mọ́; kò sí nkan t’ó njẹ́ ọba ní’lẹ̀ Yorùbá mọ́; ṣé ẹ rò wípé ọ̀rọ̀ kékeré l’a mbá yín sọ ni?
Olódùmarè l’ó rán wa ní’ṣẹ́ẹ! Àwọn babanlá-baba Michael Jackson, tí àwọn baba yín tà s’oko ẹrú ní’gbà yẹn, wọ́n ti dìdé l’ọrun, wọ́n ti sọ fún Elédùmarè wípé àwọn ò gbà mọ́, Elédùmarè dẹ̀ ti dá wọn l’ohùn, idílé ọba ní ilẹ̀ Yorùbá ti di ohun ìgbàgbé!
Ah! àwọn babanlá-baba àwọn Serena Williams, tí àwọn baba yín tà s’oko ẹrú, l’ati ilẹ̀ Yorùbá, t’ẹ́ẹ ní kí àwọn òyìnbó máa mú wọn lọ, tí òyìnbó fi ẹ̀wọ̀n irin sí wọn l’ọrùn! Ha! ẹ ta ìran ọmọ aladé sí oko ẹrú?! ti’yín ti bá yín; ṣé ẹ rò wípé ẹ̀san ò ní dé ni?
Ẹ̀san tí dé! Olódùmarè l’ó nṣe eléyi, kì nṣe ènìyàn; àwa kàn jẹ́ irin-iṣẹ́ l’ọwọ́ Elédùmarè ni! Òpin ti dé bá ìdílé Ọba ní ilẹ̀ Yorùbá! Gbogbo àwọn ìran ọmọ ol’ogo, àwọn babanlá ìran Yorùbá, tí ẹ tà sí ìlẹ̀ Amẹ́ríkà, ní àríwá Amẹ́ríkà ni, ní Gúùsù Amẹ́ríkà ni; gbogbo àwọn tí ẹ tà lọ sí Brazil; gbogbo àwọn tí àwọn baba yín tà lọ sí Grenada, tí wọ́n tà lọ sí Guyana, tí wọ́n tà bí ẹni nta iṣu àti ọ̀gẹ̀dẹ̀, odindi ọmọ èèyàn, ọmọ aládé (gbogbo ọmọ Yorùbá l’ó l’adé l’orí o!), tí ẹ tà wọ́n tìt’orí aburadà! tí ẹ tà wọ́n tìt’orí dígí! Odidi ọmọ èèyàn! ọmọ aládé, tí Olódùmarè dá ní àwòrán ara ẹ̀!
Òun l’ẹyin àt’àwọn baba yín tí wọ́n pe’ra wọn l’ọba ní ilẹ̀ Yorùbá tà! Háa! ẹ ta ìran ọmọ aládé s’oko ẹrú?! Kò sí nkan t’ó njẹ́ ọba ní’lẹ̀ Yorùbá mọ́ o! K’ẹ ya gbọ́!
Òpin ti dé! Gbogbo àwọn dúdú ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà l’oní, tí ó jẹ́ wípé ìran Yorùbá ni wọ́n, ẹ̀mí wọn àti ẹ̀mí babanlá wọn ti dìde o! Wọ́n ní àwọn fẹ́ mọ’bi t’awọn ti wá o! Wọ́n ní kí Olódùmarè ó pa’lẹ̀mọ́ àwọn t’ó ta babanlá wọn s’oko ẹrú, l’ati ilẹ̀ Yorùbá; wọ́n ní kí Olódùmarè ó pa’lẹ̀ wọn mọ́ o!
Wọ́n ní ẹ̀mí àwọn fẹ́ padà sí orísún wọn o! àwọn ò dẹ̀ gbọdọ̀ bá ẹnik’ẹni tí wọ́n npè ní ọba ní’bẹ̀ o! Àwọn tí ẹ tà s’oko ẹrú, tí wọ́n ti kú tipẹ́tipẹ́ sọ wípé àwọn npadà bọ̀ ní ilẹ̀ orísun àwọn o! àwọn ò gbọdọ̀ bá ẹnik’ẹni tí ó pe’ra rẹ̀ ní ọba ní’bẹ̀ o!
ÌDÁJỌ́ OLÓDÙMARÈ TI DÉ L’ATI ỌRUN! Àkókò àtubọ̀tán ti dé; gbogbo ìran ọmọ aládé tí àwọn baba yín ta babanlá wọn s’oko ẹrú ti bẹ Olódùmarè o, Olódùmarè sì ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn – kò sí nkan t’ó njẹ́ ọba mọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá!