Ọpẹ́ ni fun Ọlórun Ẹlẹ́dàá wa tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìdẹ́kùn àwọn òyìnbo aṣe’kúpani bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kíni à bá máa sọ nírú àkókò báyi?

Dókítà kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ògbóǹtarìgì ninu ṣíṣe àyẹ̀wò oògùn òyìnbó ní orí ayélujára ló ń ṣe àlàyé ewu ńlá tó wà nínú abẹ́rẹ́ àjẹsára covidi. Ó ṣe àlàyé pe wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣeé láti fi ṣe àkóbá fun àwọn nkan ẹlẹgẹ́ nínú ẹ̀yà ara ni, pàápàá fún àwọn obìnrin láti má leè bímọ mọ́. 

Àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó fi iṣẹ́ ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) lé Ìyá wa, Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá lọ́wọ́, láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ ìkà.

Ní kété tí a ṣe ìkéde Orílẹ̀-èdè wa Democratic republic of the Yorùbá (D.R.Y) ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a sì tún ṣe ìbúra wọlé fún olórí ìjọba Adelé wá, bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ ní ọjọ́ kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wá-ọdún-ólémẹ́rìnlélógún, ìjọba wa sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu.

Màmá wa MOA ti sọ fún wa pé nínú àlàkalẹ̀ ìṣèjọba wa, ààbò tó péyé yóò wà fún ẹ̀mí gbogbo àwa ọmọ Yorùbá, nítorínáà, ètò ìlera jẹ́ pàtàkì fún gbogbo ará ìlú. Kí òògùn òyìnbó kan tó wọlé sí orílẹ̀ èdè wa, a ó ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ fínífíní láti ríi dájú pé kò ní ṣe ìpalára fún ara tàbí ẹ̀mí.

Ní àfikún, ewé àti egbò  náà yóò jẹ́ lílò ní àwọn ilé ìwòsàn wa, bẹ́ẹ̀ sì ní kò ní sí ìgbìmọ̀ kankan tí yóò fi agbára mú ọmọ Yorùbá láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára nítorí orílẹ̀ èdè olómìnira aṣèjọba ara ẹni ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.

Democratic republic of the Yoruba is no longer part oƒnigeria. Anyone counting the 7 states of the yoruba nation with nigeria is committing a crime. Indigenous yoruba people should be warned!