Ẹní m’ojú ògún níí p’abì ní’rè. Láìpẹ́ yìí tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) bá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y)  sọ̀rọ̀, wọ́n sọ nípa àwọn kan tí wọ́n ń lérí, tí wọ́n ń sọ ìsọkúsọ pé àṣẹ wo ni màmá wa MOA ní, pé MOA kò lè là lé wọn lọ́wọ́.

Èyí ló mú kí màmá wa sọ wípé, ẹni tó gba ìlú ló ń ṣe ìlú. Ọlọ́run Olódùmarè ló gba ìlú fún wọn, pé ó yá lọ kó àwọn ìran Yorùbá kúrò nínú oko ẹrú, tó sì fún wọn ní kọ́kọ́rọ́ tí wọ́n máa lò. Òun náà ló sì ń ṣe ìlú fún wọn pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tó fi rán wọn sí ìran Yorùbá.

Màmá ṣe àpẹẹrẹ àwọn orílẹ̀ èdè ní àgbáyé tó jẹ́ pé àwọn tó gba orílẹ̀ èdè náà àwọn náà ló ń ṣe ètò ìlú ọ̀hún. Bí àpẹẹrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, MOA ní àwọn méje ni ògbóhùntarìgì tó dúró tán, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ju méje lọ, ṣùgbọ́n àwọn méje tó dúró tán dáadáa yí, wọ́n sọ wípé àwọn ni wọ́n fi ìdí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà mulẹ̀̀, àwọn náà ló sì ń ṣe ìlànà ètò ìṣàkóso fún orílẹ̀ èdè tuntun náà.

Ètò ìṣàkóso orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lónìí, àwọn wọ̀nyí ló gbée kalẹ̀, tí babańlá ẹnikẹ́ni kò sì lè bi wọ́n pé báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Àwọn ló gba ìlú, àwọn náà ló sì ń ṣe ìlú nítorí pé àwọn ló mọ ìdí tí wọ́n fi gba ìlú náà. Báwo ni ẹni tí kò gba ìlú ṣe lè sọ pé ohun fẹ́ ṣe ìlú? Kíni èrò rẹ̀ àti àníyàn rẹ̀ lórí ìlú náà? Ṣé ẹ̀yin tí ẹ ń tako ìran yín lẹ fẹ́ ṣe ìlú ni?

Màmá wa MOA tún dárúkọ àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ní àgbáyé tó jẹ́ pé àwọn babańlá wọn tó gba ìlú náà ló ń ṣe ìlú ọ̀hún, bíi orílẹ̀ èdè Faransé, orílẹ̀ èdè Russia, orílẹ̀ èdè China, orílẹ̀ èdè Singapore àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo wọn pátápátá tó gba ìlú náà ni wọ́n ṣeé.

Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kan, ẹ ò ṣe, àmọ́ ẹ fẹ́ jẹ, ẹ ní ẹ̀yin náà máa kọ ìwé òfin, kí lẹ mọ̀ tí ó njẹ́ òfin? Ẹ̀yin tí ọpọlọ yín ti dorí kodò. 

Kò ṣeéṣe fún ẹni tí kò mọ̀ nípa nǹkan, kó wá sọ pé òun fẹ́ ṣeé.  Nítorí  náà, ẹni tó gba ìlú ló ń ṣe ìlú o.

Ẹ gbà fún Ọlọ́run, ẹ gbà fún divine blueprints ọwọ́ MOA.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal