Kò sí mi ò mọ̀, lábẹ́ òfin. Àwọn kan ti ṣe àkọlù sí ìṣàkóso-ara-ẹni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ó sì di dandan pé ohun tí òfin tí ìṣàkóso-ara-ẹni D.R.Y dúró lé lórí, máa fi han àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí, pé ọ̀daràn ni wọ́n, ohun tí ojú wọn bá sì rí, látàrí ọ̀ràn-dídá wọn, kí wọ́n f’ara mọ.
Àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí ni:
- Èkíní, AbdulQowiyy Ọlálékan Imam-Oníde, ẹni tí ó ni ìkànnì X tí a mọ̀ sí, @A_QowiyyBadmus .
- Èkejì, High Chief Yusuf Akinadé Ọláyínka 1, tí ó pe ara rẹ̀ ní ‘Baṣọ̀run of Ọ̀yọ́ land’.
- Ẹ̀kẹ́ta, Alhaji Abdul Lateef Abdulazeez Ẹlẹ́yẹlé, tí ó pe ara rẹ̀ ní ‘Mufasiru of Ọ̀yọ́ Land’.
- Ìkẹ́rin, Alhaji Chief Tajudeen Abdul-Hammed Kamorise, èyí tí ó pe ara rẹ̀ ní ‘Ààrẹ Muslumi of Ọ̀yọ́ Land’.
- Ìkárun, Alhaji Yaqub Mainazara, ẹni tí ó pe ara rẹ̀ ní ‘Amir Li-Mumeen of Ọ̀yọ́ Land’.
- Ẹ̀kẹfà, Dr. Rafiu Àdísá Bello, tí ó pera rẹ̀ ní “Chairman, Sharia Committee of Ọ̀yọ́ Land”, tí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ 081-455-3981-0.
- Ìkéje, Sulaimon Abdul-Ganiy Abuquudi, ẹni tí ó pera rẹ̀ ní ‘Secretary, Sharia Committee of Ọ̀yọ́ Land,’ tí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ 081-613-6343-1.
- Ẹ̀kẹ́jọ, Dr. Abdul Mumeen Hamzat, ẹni tí wọ́n pè ní, ‘Chairman, Muslim Community of Ọ̀yọ́ Land’.
- Ẹ̀kẹ́san, Sheikh Abdul Rasheed Adiyatullahi, ẹni tí ó pe ara rẹ̀ ní “National Chairman, Shari’a Committee.”
- Ẹni ‘kẹ́wa ni Mallam Nafiu Baba-Hammed, tí ó pe ara rẹ̀ ní ‘Secretary General, Supreme Council Sharia in Nigeria’.
Àwọn mẹ́wa yí, ni wọ́n pàdí àpò pọ̀, láti ṣe ìkọlù sí agbára-ìṣàkóso-ara-ẹni Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ní fífi ọ̀rọ̀ léde ní orí ẹ̀rọ-ayélujára X, ní ogúnjọ́, oṣù ọ̀pẹ, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, [tí a tún gbọ́ náà lórí YouTube], tí wọ́n sì sọ báyi pé, “Níwọ̀n-ìgbàtí àwọn ìpínlẹ̀ ‘Southwest’ kò ti fún àwọn mùsùlùmí ní àyè láti ní ilé-ìgbẹ́jọ́ ti ara wọn, lẹ́yìn ìgbàtí Ìwé-Òfin Nàìjíríà, Ipele Ọ̀rìnlélúgba-ó-dín-márun, abala ìkíní ti fi àyè gba gbogbo ìpínlẹ̀ láti ní ilé-ìgbẹ́jọ́ bẹ́ẹ̀, àwọn mùsùlùmí ti wá pinu láti lo Àwọn-Ìṣe-Ẹ̀mí-Islam [ISP].
Ìlú Ọ̀yọ́ Àláàfin yíò ní ilé-ìgbẹ́jọ́ tirẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí ní oṣù ṣẹrẹ [ẹgbàá-ọdún ó lé márun-dínlọ́gbọ̀n].
Ẹ bá wa péjọ!”
Èyí ni kókó ọ̀ràn tí àwọn ọ̀daràn mẹ́wa yí dá.
- Èkíní, wọ́n pe ilẹ̀ Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ní “Southwest” Nàìjíríà.
- Èkejì, wọ́n nsọ pé orílẹ̀-èdè aṣàkóso-ara-ẹni D.R.Y, wà lábẹ́ Constitution Nàìjíría.
- Ìkẹ́ta, wọn sọ nípa ẹgbẹ́ tí wọ́n pè ní “Muslim Community of Ọ̀yọ́ Land,” nígbàtí Olórí-Ìṣàkóso Adelé Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, tí sọ, ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, pé, a fagi lé gbogbo ẹgbẹ́ ni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).
Àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí, gbé ìpolongo síta, ní ìkànnì X tí a sọ nípa rẹ̀ yí, pé, ìfilọ́lẹ̀ ilé-ẹjọ́ sharia tí wọ́n nsọ, yíò wáyé ní ọjọ́ kọ́kànlá, oṣù ṣẹrẹ, ẹgbàá ọdún ó lé márun-dínlọ́gbọ̀n (èyíinì, oṣù tí ó nbọ̀ yí), ní aago mẹ́wa àárọ̀, ní Muslim Community Islamic Centre, Ọba Adéyẹmí High School Road, Mọbọlajẹ Area, Agbogangan, Ọ̀yọ́.
Èyí túmọ̀ sí pé, kìí ṣe pé wọ́n pinu, pẹ̀lú ìpàdí-àpò-pọ̀, níkan, pé àwọn máa ṣe àkọlù sí agbára-ìṣàkósó-ara-ẹni Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), wọ́n tilẹ̀ tún fi lédé ibi tí wọ́n ti máa ṣe àkọlù náà, ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe, àti aago tí àwọn máa ṣe àkọlù náà.
Wọ́n tún kọ-ọ́, gàdàgbà-gadagba, sorí ìkéde tí wọ́n ṣe lórí ìkànnì X ọ̀ún pé, lábẹ́ àsíá “Supreme Council for Shari’a in Nigeria, Ọyọ Chapter” ni àwọn ti nṣe nkan wọ̀nyí o! èyí tí ó fi ẹ̀rí-ìdánilójú si pé, àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí dájú Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), wọ́n sì nfi léde pé, ní ti àwọn o, D.R.Y jẹ́ ara nàìjíríà! Ẹ jọ̀wọ́, ẹlẹ́ri kíni a tún nwá? Àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí ti fúnra wọn gbé ẹ̀rí ọ̀ràn-dídá wọn síta.
Ẹ̀yin ọ̀daràn wọ̀nyí, tí wọ́n bá bí yín dáa, kí ẹ máa gbé ọ̀rọ̀ rírùn tí ẹ nsọ yẹn bọ̀ ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), á wá yée yín pé ilẹ̀ Yorùbá (D.R.Y) ti kúrò lára nàìjíríà.