“Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣàánú fún mi, mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, mi ò kìí se apànìyàn, ọrọ̀ ajé ní mo ṣe dé ‘bẹ̀.” Báyìí ni obìnrin kan ṣe ń sọ pẹ̀lú omijé lójú nínú fọ́nrán tí wọ́n ti nfi obìnrin náà han pé ó ń ta orí ènìyàn.
Obìnrin náà ṣe àlàyé pé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tańt’Ọlọ́run, òṣìṣẹ́ nì itẹ́ òkú ni ó fi ọ̀rọ̀ náà lọ òun láti wá máa ra orí òkú, nítorí àwọn máa ń ju òkú sọnù sí’nú igbó tí ó wá ní àyíká itẹ́ naa ni, obinrin náà ní ewé ọmọ ni òun ń tà, òun sì máa ń gé orí náà sí wẹ́wẹ́ láti máa fi sínú ọtí fún àwọn ènìyàn tó wà máa ń ràá ní igba náírà owó wọn ní ìlú ayédèrú Nàìjíríà.
Ìròyìn yí ba ni nínú jẹ́ púpọ̀, ọmọ Aládé ń ta ẹ̀yà ara ènìyàn láti rí owó nítorí àtijẹ, nígbà tí àwọn kan sì ń kó owó bí ẹni pé wọn ò ní fi ayé yìí sílẹ̀ lọ́jọ́ kan. Ẹ̀yà ara ènìyàn ti wá di ohun tí wọ́n ntà lọ́jà bí ẹní ń t’ẹja, ó mà ṣe ò.
Bì kò bá ṣe Olódùmarè tó dá sí ọ̀rọ̀ àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, níbo ní àwa ọmọ aládé ìbá bá yàrá já? A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla tí wọ́n gbà láti ṣiṣẹ́ fún ìran ọmọ aládé fún ìtúsílẹ̀ wá kúrò nínú oko ẹrú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.
Láì pẹ́, gégébí ọ̀rọ̀ ìyá wa, nígbàtí a bá lé àwọn àjẹgaba ìjọba agbésùnmọ̀mí Naijiria kúrò lórí ilẹ̀ wa, àtúnṣe yóò bá ayé awa Indigenous Yorùbá People (I.Y.P), àjíǹde yíò sì dé bá àṣà, ìṣe àti ìwà ọmọlúàbí wá tí àgbáyé tí mọ̀ wá sí ní ìgbà ìwáṣẹ̀.
Ẹ̀yin ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, kò tún sí ọ̀nà míràn mọ́ bíkòṣe pé kí a fi ọwọ́s’owọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì ríi dájú pé a ń sa ipá wa láti ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn kí iṣẹ́ náà lè rọrùn nítorí wípé àgbájọ ọwọ́ ni a fi ń sọ̀’yà.